قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن جَعَلَ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمُ ٱلَّيۡلَ سَرۡمَدًا إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَنۡ إِلَٰهٌ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَأۡتِيكُم بِضِيَآءٍۚ أَفَلَا تَسۡمَعُونَ 71
Sọ fun - irẹ ojisẹ - awọn ẹlẹbọ wọnyi: ti Allah ba sọ oru di ohun ti yoo maa bẹ lọ, ti ko nii ja titi di ọjọ igbende, taani ẹni ijọsin fun yatọ si Allah ti o le mu imọlẹ wa gẹgẹ bi imọlẹ ọsan?! Se ẹ ko gbọ awọn awijare yii, ki ẹ si mọ wipe ko si ọba kan ayaafi Allah ti o le mu eleyi wa?!
قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن جَعَلَ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمُ ٱلنَّهَارَ سَرۡمَدًا إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَنۡ إِلَٰهٌ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَأۡتِيكُم بِلَيۡلٖ تَسۡكُنُونَ فِيهِۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ 72
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: fun mi niro ti Allah ba sọ ọsan di ohun ti yoo maa lọ titi di ọjọ igbende, taani ẹni ijọsin fun yatọ si Allah ti yoo mu oru wa, tiẹ o maa gbe ninu rẹ ki ẹ le sinmi kuro nibi wahala isẹ ọsan?! Se ẹ ko ri awọn amin yi ni ki ẹ le mọ wipe ko si ọba kan ayaafi Allah eyiti o le mu gbogbo eleyi wa?!
وَمِن رَّحۡمَتِهِۦ جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ لِتَسۡكُنُواْ فِيهِ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 73
Ninu ikẹ Rẹ ti mimọ nbẹ fun ni ki O se fun yin -ẹyin eniyan- oru ti sookun; ki ẹ le gbe ninu rẹ lẹyin igbati ẹ ba ti daamu nibi isẹ ọsan, o si tun se ọsan onimọlẹ fun yin; ki ẹ le maa rin lati wa arisiki nibẹ, ati ki ẹ le ba dupẹ idẹkun Allah le yin lori, ki ẹ mase se keferi si i.
وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ فَيَقُولُ أَيۡنَ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تَزۡعُمُونَ 74
Ni ọjọ ti Ọlọhun wọn ti mimọ nbẹ fun yoo pe wọn ni ẹniti O nsọ bayi: nibo ni awọn akẹgbẹ Mi eyiti ẹ nsin wọn yatọ si Mi wa, ti ẹ si nlero pe wọn jẹ akẹgbẹ pẹlu Mi?
وَنَزَعۡنَا مِن كُلِّ أُمَّةٖ شَهِيدٗا فَقُلۡنَا هَاتُواْ بُرۡهَٰنَكُمۡ فَعَلِمُوٓاْ أَنَّ ٱلۡحَقَّ لِلَّهِ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ 75
A mu wa ninu ijọ kọọkan anọbi rẹ, ti yoo maa jẹri le lori nipa keferi ati irọ pipa ti o wa nibẹ, a si sọ fun awọn ti nparọ ninu ijọ naa ẹ mu awọn awijare yin wa ati awọn ẹri yin lori ohun ti ẹ wa nibẹ ni keferi ati irọ pipa, bẹẹni awọn ẹri wọn ja, wọn si mọ amọdaju wipe dajudaju ododo ti ko si iyemeji nibẹ jẹ ti Allah, ohun ti wọn nhun ninu akẹgbẹ fun Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun si kuro lọdọ wọn.
Nigbati Allah sọ nipa fir'aona ti o ga lori ilẹ nitori ọla, O tun sọ ikọja ẹnu aala Qọruna nitori owo, O wa sọpe:
۞إِنَّ قَٰرُونَ كَانَ مِن قَوۡمِ مُوسَىٰ فَبَغَىٰ عَلَيۡهِمۡۖ وَءَاتَيۡنَٰهُ مِنَ ٱلۡكُنُوزِ مَآ إِنَّ مَفَاتِحَهُۥ لَتَنُوٓأُ بِٱلۡعُصۡبَةِ أُوْلِي ٱلۡقُوَّةِ إِذۡ قَالَ لَهُۥ قَوۡمُهُۥ لَا تَفۡرَحۡۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡفَرِحِينَ 76
Dajudaju Qọruna wa ninu ijọ Musa ẹniti ọla nbẹ fun, o si se igberaga si wọn, a si fun ni awọn pẹpẹ ọrọ dukia eyiti awọn kọkọrọ pẹpẹ ọrọ naa wuwo ni gbigbe fun awọn ijọ ti o lagbara, nigbati awọn ijọ rẹ sọ fun pe, mase yọ ni ayọ alayọpọrọ, dajudaju Allah ko nifẹ si awọn alayọ ni ayọ pọrọ bikosepe O korira wọn, Yoo si fi iya jẹ wọn lori rẹ.
وَٱبۡتَغِ فِيمَآ ءَاتَىٰكَ ٱللَّهُ ٱلدَّارَ ٱلۡأٓخِرَةَۖ وَلَا تَنسَ نَصِيبَكَ مِنَ ٱلدُّنۡيَاۖ وَأَحۡسِن كَمَآ أَحۡسَنَ ٱللَّهُ إِلَيۡكَۖ وَلَا تَبۡغِ ٱلۡفَسَادَ فِي ٱلۡأَرۡضِۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُفۡسِدِينَ 77
Maa wa ẹsan ni ile ọrun nibi ohun ti Allah fun ọ ni dukia; pẹlu ki o maa na si ojupọnna rere, masi se gbagbe ipin rẹ nibi jijẹ ati mimu ati wiwọ ati ohun ti o yatọ si eleyi ninu awọn idẹkun, laina ina apa tabi se akọ, ki o si jẹ ibasepọ rẹ dara pẹlu Ọlọhun Ọba rẹ ati pẹlu awọn ẹru Rẹ gẹgẹ bi Ọba ti mimọ nbẹ fun se se daadaa fun ọ, masi se wa ibajẹ lorilẹ pẹlu dida ẹsẹ ati gbigbe awọn itẹlasẹ ju silẹ, dajudaju Allah ko nifẹ si olubilẹjẹ pẹlu eleyi bikosepe O korira wọn.
Pipaarọ oru ati ọsan si ara wọn jẹ idẹkun kan ninu awọn idẹkun Allah ti didupẹ rẹ jẹ dandan fun un.
Ikọja ẹnu aala bi o se ma nwa nibi idari ati ọla, bẹẹni o ma nwa nibi dukia.
Yiyọ pọrọ jẹ ẹsẹ ti Ọlọhun Ọba binu si.
Jijẹ dandan sise isiti fun ẹniti a nbẹru idaamun le lori.
Ikorira Ọlọhun Ọba nbẹ fun olubilẹjẹ lorilẹ.