قَالَ هَٰٓؤُلَآءِ بَنَاتِيٓ إِن كُنتُمۡ فَٰعِلِينَ 71
Luth sọ fun ẹniti ọla nbẹ fun ni ẹniti nwi awijare fun ara rẹ ni iwaju awọn alejo rẹ: awọn wọnyi ni awọn ọmọbinrin mi ninu awọn obinrin yin, ẹ yaa fẹ wọn ti ẹ ba ngbero lati biiya bukaata adun yin.
لَعَمۡرُكَ إِنَّهُمۡ لَفِي سَكۡرَتِهِمۡ يَعۡمَهُونَ 72
Mo fi isẹmin rẹ bura - irẹ ojisẹ - dajudaju awọn ijọ Luth wa ninu ikọja ẹnu aala adun wọn, ti wọn si ndaamun daabo.
فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّيۡحَةُ مُشۡرِقِينَ 73
Bayi ohun lile ti o le pani run gba wọn mu nigbati wọn wọnu asiko ti oorun yọ.
فَجَعَلۡنَا عَٰلِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهِمۡ حِجَارَةٗ مِّن سِجِّيلٍ 74
A yi inu wọn pada pẹlu sisọ oke rẹ dilẹ, A si rọ ojo oko lati inu abata okuta le wọn lori.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡمُتَوَسِّمِينَ 75
Dajudaju nibi eleyi ti a sọ yii wa ninu ohun ti o sẹlẹ si ijọ Luth ninu iparun eyiti o jẹ awọn amin fun ẹniti o ba nronu jinlẹ.
وَإِنَّهَا لَبِسَبِيلٖ مُّقِيمٍ 76
Dajudaju awọn abule ijọ Luth wa ni oju ọna ti rinlẹ, ti awọn ti o nse irin ajo ma nri wọn nigbati wọn ba kọja nibẹ.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ 77
Dajudaju nibi isẹlẹ yii jẹ amin fun awọn olugbagbọ ododo lati le woye sii.
وَإِن كَانَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡأَيۡكَةِ لَظَٰلِمِينَ 78
Paapaa awọn ijọ Shuayb tii se ara abule eyiti o ni igi ni ayika jẹ awọn alabosi; nitori keferi wọn si Allah ati pipe awọn ojisẹ Rẹ Shuayb ẹniti ọla nbẹ fun nirọ.
فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ وَإِنَّهُمَا لَبِإِمَامٖ مُّبِينٖ 79
A gba ẹsan lara wọn lati ibi fifi iya gba wọn mu, dajudaju awọn abule ijọ Luth ati awọn aaye awọn eniyan Shuayb jẹ oju ọna ti o han fun ẹniti o nre kọja nibẹ.
وَلَقَدۡ كَذَّبَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡحِجۡرِ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 80
Paapaa awọn ijọ Thamudaawa parọ mọ, awọn si ni awọn eniyan Hijiri (aaye kan laarin Hijaasi ati Shaamu), gbogbo awọn ojisẹ nigbati wọn pe Anọbi wọn Sọọlihun nirọ ẹniti ọla nbẹ fun.
وَءَاتَيۡنَٰهُمۡ ءَايَٰتِنَا فَكَانُواْ عَنۡهَا مُعۡرِضِينَ 81
A si fun wọn ni awọn awijare ati awọn itọka lori jijẹ ododo nkan ti o mu wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ, ninu rẹ naa ni rakunmi sugbọn wọn ko woye si awọn ẹri yii, bẹẹ ni wọn ko bikita pẹlu rẹ.
وَكَانُواْ يَنۡحِتُونَ مِنَ ٱلۡجِبَالِ بُيُوتًا ءَامِنِينَ 82
Wọn jẹ ẹniti o ngbẹ inu oke lati se ile si inu rẹ ti wọn yoo maa gbe, ki wọn le maa fi ọkan balẹ kuro nibi ohun ti o nda ẹru ba wọn.
فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّيۡحَةُ مُصۡبِحِينَ 83
Ariwo iya Ọlọhun Ọba si gba wọn mu nigbati ilẹ mọ.
فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ 84
Awọn dukia ati awọn ibugbe wọn ti wọn ko jọ ko ti iya Ọlọhun Ọba kuro fun wọn.
وَمَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۗ وَإِنَّ ٱلسَّاعَةَ لَأٓتِيَةٞۖ فَٱصۡفَحِ ٱلصَّفۡحَ ٱلۡجَمِيلَ 85
A ko da sanmọ ati ilẹ bẹẹ ni a ko da ohun ti nbẹ laarin mejeeji niti ibajẹ ju ọgbọn lọ, a ko da gbogbo eleyi ayaafi pẹlu ododo, bẹẹ ni dajudaju ọjọ igbende nbọ ko si ibuyẹ, ki o yaa gunri - irẹ ojisẹ - kuro ni ọdọ awọn ti wọn npe ọ nirọ, ki o si se amojukuro fun wọn ni amojukuro daadaa.
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ ٱلۡخَلَّٰقُ ٱلۡعَلِيمُ 86
Dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ -, Oun ni Ọba Adani fun gbogbo nkan ati Onimimọ rẹ.
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَٰكَ سَبۡعٗا مِّنَ ٱلۡمَثَانِي وَٱلۡقُرۡءَانَ ٱلۡعَظِيمَ 87
Paapaa a si ti fun ọ ni Faatiha eyiti o jẹ aayah meje, ohun si ni Alukuraani ti o tobi.
لَا تَمُدَّنَّ عَيۡنَيۡكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعۡنَا بِهِۦٓ أَزۡوَٰجٗا مِّنۡهُمۡ وَلَا تَحۡزَنۡ عَلَيۡهِمۡ وَٱخۡفِضۡ جَنَاحَكَ لِلۡمُؤۡمِنِينَ 88
Ma gbe oju rẹ wo ohun ti a fi se idẹkun fun awọn iran keferi ninu idẹkun ti yoo tan, ma si banujẹ lori piparọ wọn, ki o ya maa se apọnle awọn olugbagbọ ododo.
وَقُلۡ إِنِّيٓ أَنَا ٱلنَّذِيرُ ٱلۡمُبِينُ 89
Ki o sọ wipe - irẹ ojisẹ - dajudaju emi jẹ oluse ikilọ kuro nibi iya eyiti o fi oju han, ti o si nse ikilọ.
كَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَى ٱلۡمُقۡتَسِمِينَ 90
Mo nse ikilọ fun yin ki iru ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ fun awọn olupinya awọn tira Ọlọhun ni yẹlẹyẹlẹ ma baa sẹlẹ si yin, ti wọn nigbagbọ si apakan, ti wọn si se keferi si apakan.
Dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti o ga julọ ti O ba gbero lati pa abule kan run Yoo se alekun aburu wọn ati ikọja ẹnu aala wọn, ti o ba wa tan, Yoo waa mu ijiya ti wọn ni ẹtọ si sẹlẹ le wọn lori.
Kikorira wiwọ awọn aaye iya ninu rẹ ni wiwọ iboji awọn keferi, ti ọmọ ẹda eniyan ba wọn iru awọn aaye wọnyi ati awọn iboji, dandan ni ki o yara nibẹ.
Olugbagbọ ododo ko gbọdọ maa fẹju wo ọsọ aye ati yodoyindin rẹ, ki o si ma wo ounti o nbẹ lọdọ Ọlọhun Ọba ninu ọrẹnta.
Dandan ni fun olugbagbọ ododo ki o jinna si awọn ẹlẹbọ, ki o si mase banujẹ ti wọn ko ba nigbagbọ, ki o si sunmọ awọn olugbagbọ ododo ni ẹniti o ntẹriba fun wọn, ti o fẹran wọn koda wọn ko baa jẹ alaini.