يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ قُل لِّمَن فِيٓ أَيۡدِيكُم مِّنَ ٱلۡأَسۡرَىٰٓ إِن يَعۡلَمِ ٱللَّهُ فِي قُلُوبِكُمۡ خَيۡرٗا يُؤۡتِكُمۡ خَيۡرٗا مِّمَّآ أُخِذَ مِنكُمۡ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 70
Irẹ Anọbi, sọ fun awọn ẹru ọlọsẹbọ tti wọn wa lọwọ yin eyiti ẹ mu lẹru ni ọjọ badiri, ti Ọlọhun Ọba Allah ba mọ ohun ti nbẹ ninu ọkan yin ninu daradara, ati didara adisọkan yin, yoo fun yin ni oore ti o ju nkan ti wọn gba lọwọ yin lọ ni ifidi, ẹ mase se ijanba lori nkan ti wọn gba lọwọ yin, yoo si se afoprijin ẹsẹ yin, Ọlọhun Ọba jẹ olufi ori jin ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, O si jẹ onikẹ si yin, paapaa adehun Ọlọhun Ọba ti di imusẹ fun Abbas tii se ẹgbọn Anọbi ki ikọ ati ọla maa bẹ fun ati ẹniti o yatọ si ninu awọn ti o gbafa fun Ọlọhun Ọba.
وَإِن يُرِيدُواْ خِيَانَتَكَ فَقَدۡ خَانُواْ ٱللَّهَ مِن قَبۡلُ فَأَمۡكَنَ مِنۡهُمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ 71
Ti wọn ba gbero - irẹ Muhammad - lati tan ọ jẹ pẹlu ohun ti wọn nse afihan rẹ si ọ ninu ọrọ, wọn ti janba Ọlọhun Ọba siwaju, Ọlọhun Ọba si ti ran ọ se le wọn lori, wọn ti pa ninu wọn, wọn si mu lẹru ninu wọn, ki wọn o yaa maa reti iru rẹ ti wọn ba tun sẹri pada, Ọlọhun Ọba nimọ nipa ẹda Rẹ ati nkan ti o le se wọn ni anfaani, O si jẹ ọjọgbọn nibi iseto Rẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلَّذِينَ ءَاوَواْ وَّنَصَرُوٓاْ أُوْلَٰٓئِكَ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٖۚ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَلَمۡ يُهَاجِرُواْ مَا لَكُم مِّن وَلَٰيَتِهِم مِّن شَيۡءٍ حَتَّىٰ يُهَاجِرُواْۚ وَإِنِ ٱسۡتَنصَرُوكُمۡ فِي ٱلدِّينِ فَعَلَيۡكُمُ ٱلنَّصۡرُ إِلَّا عَلَىٰ قَوۡمِۢ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٞۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ 72
Dajudaju awọn ti wọn nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba, ti wọn si gba ojisẹ Rẹ lododo, ti wọn si nse awọn ofin Rẹ, ti wọn si se irin ajo kuro ni ilu keferi lọ si ilu Islam, tabi lọ si aaye ti wọn yoo ti maa sin Ọlọhun Ọba Allah ni ifọkanbalẹ, ti wọn si se igbiyanju pẹlu nina gbogbo dukia wọn ati ẹmin wọn lati gbe gbolohun Ọlọhun Ọba Allah ga, awọn ti wọn sọ wọn kalẹ si ile wọn, ti wọn si se aranse fun wọn - awọn ni oluse irin-ajo ati awọn ti wọn ran wọn ninu awọn ara ile, apakan wọn jẹ ọrẹ fun apakan nibi aranse ati iranlọwọ, ati awọn ti wọn nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn ko se irin ajo lati ilu keferi lọ si inu Islam, kii se dandan le yin lori - ẹyin olugbagbọ ododo - ki ẹ ran wọn se, ki ẹ si maa sọ wọn, titi ti wọn yoo fi se irin ajo si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ti awọn keferi ba se abosi si wọn, ti wọn wa aranse lọdọ yin, ẹ yaa ran wọn lọwọ lori ọta wọn ayaafi ti adehun ba wa laarin ẹyin ati ọta wọn, ti ẹ ko lee ja, Ọlọhun Ọba Allah jẹ oluriran ri ohun ti ẹ nse, nkankan ko pamọ fun Un ninu isẹ yin, yoo si san yin lẹsan le lori.
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٍۚ إِلَّا تَفۡعَلُوهُ تَكُن فِتۡنَةٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَفَسَادٞ كَبِيرٞ 73
Awọn ti wọn se keferi si Ọlọhun Ọba Allah, ise keferi yoo ko wọn jọ, apakan wọn yoo si maa se aranse fun apakan, olugbagbọ ododo kankan ko gbọdọ mu wọn ni alatilẹyin, ti awọn olugbagbọ ododo ko ba mu wọn ni alatilẹyin, ti wọn si ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn keferi, yoo jẹ adanwo fun awọn olugbagbọ ododo nitori wipe wọn ko nii ri ẹniti yoo ran wọn se ninu awọn ọmọ iya wọn ninu ẹsin, ibajẹ ti o tobi yoo si han lori ilẹ pẹlu sisẹri kuro ni oju ọna Ọlọhun Ọba Allah.
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلَّذِينَ ءَاوَواْ وَّنَصَرُوٓاْ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ حَقّٗاۚ لَّهُم مَّغۡفِرَةٞ وَرِزۡقٞ كَرِيمٞ 74
Awọn ti wọn nigbagbọ si Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si nse irin-ajo si oju ọna Rẹ, ati awọn ti wọn kun awọn olusegbiyanju lọwọ ni oju ọna Allah, ti wọn si se aranse fun wọn, awọn ni wọn gba iroyin igbagbọ ododo, Ọlọhun Ọba yoo si san wọn lẹsan aforijin fun ẹsẹ wọn ni ọdọ Rẹ, ati aranse ti lapọnle lati ọdọ Rẹ, ohun naa ni Alujannah.
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنۢ بَعۡدُ وَهَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ مَعَكُمۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ مِنكُمۡۚ وَأُوْلُواْ ٱلۡأَرۡحَامِ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلَىٰ بِبَعۡضٖ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمُۢ 75
Awọn ti wọn nigbagbọ lẹyin igbagbọ awọn ẹni isaaju si Islam ninu awọn oluse irin ajo ati alaranse, ti wọn si se irin ajo lati ilu keferi lọ si ilu Islam, ti wọn se igbiyanju si oju ọna Allah ki gbolohun Allah le jẹ ohun ti o ga julọ, ki gbolohun keferi si le jẹ ohun ti o lọ silẹ, awọn wa ninu yin - ẹyin olugbagbọ ododo - o nbẹ fun wọn iru ẹtọ ti o wa fun yin, o si jẹ dandan le wọn lori awọn nkan ti o jẹ ọranyan le yin lori, bẹẹ ni awọn ẹni asunmọ nibi idajọ Ọlọhun Ọba Allah, apakan wọn lẹtọ si apakeji nibi ogun jijẹ ati nibi jijẹ ogun igbagbọ laarin ara wọn, ati sise irin-ajo eyiti o ti wa siwaju, dajudaju Ọlọhun Ọba jẹ onimọ nipa gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un, O mọ nkan ti o le wulo fun awọn ẹru Rẹ ki o le se lofin fun wọn.
Dandan ni fun awọn olugbagbọ ododo ki wọn o maa se awọn ẹru loju kokoro lati ni igbagbọ.
Awọn aayah yii ko sinu ifuni niro idunnu fun awọn olugbagbọ ododo pẹlu itẹsiwaju aranse lori awọn ẹlẹbọ niwọnba igba ti wọn ba wa lori awọn okunfa aranse, eyiti o jẹ o see fi oju ri ati eyiti ko see fi oju ri.
Dajudaju awọn olugbagbọ ododo ti wọn ko ba si pẹlu ọwọ kan soso lori awọn keferi, agbara wọn ko nii han de, ibajẹ ti o tobi yoo si sẹlẹ lati ara eleyi.
Ọla ti nbẹ fun mima mu adehun sẹ ati ifọwọsowọpọ lori ofin ẹsin, koda ki o tako oun ti o le se anfaani fun awọn olugbagbọ ododo.