قَالُواْ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا هِيَ إِنَّ ٱلۡبَقَرَ تَشَٰبَهَ عَلَيۡنَا وَإِنَّآ إِن شَآءَ ٱللَّهُ لَمُهۡتَدُونَ 70
Lẹyin igba naa, wọn tẹsiwaju nibi isori kunkun wọn ni ẹni ti o nsọ bayi pe: pe Ọlọhun Ọba rẹ fun wa titi ti alekun iroyin rẹ yoo fi han si wa nitori pe maalu ti wọn darukọ pẹlu awọn iroyin naa pọ, ti a ko si ni ikapa lati se adayanri rẹ laarin wọn, ni ẹni ti nkanpa mọ pe dajudaju awọn - ti Ọlọhun Allah ba fẹ - yoo jẹ ẹni imọna lọ si ibi maalu ti wọn fẹ ki a pa.
قَالَ إِنَّهُۥ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٞ لَّا ذَلُولٞ تُثِيرُ ٱلۡأَرۡضَ وَلَا تَسۡقِي ٱلۡحَرۡثَ مُسَلَّمَةٞ لَّا شِيَةَ فِيهَاۚ قَالُواْ ٱلۡـَٰٔنَ جِئۡتَ بِٱلۡحَقِّۚ فَذَبَحُوهَا وَمَا كَادُواْ يَفۡعَلُونَ 71
Muusa sọ fun wọn pe: dajudaju Ọlọhun Ọba sọ pe: dajudaju kii se eyi ti o ti yẹpẹrẹ pẹlu isẹ ninu oko bẹẹ ni kii se eyi ti o nfun ilẹ ni omi mu, o jẹ eyi ti o la kuro nibi awọn aleebu, ko si abawọn nibi awọ pupa fẹsifẹsi ara rẹ. Nigbanaa ni wọn wa sọ pe: ni igba yii ni o mu iroyin gan-an-gan eyi ti yoo se adayanri maalu naa ni pipe wa. Wọn wa pa maalu naa lẹyin igba ti wọn fẹẹ le ma pa a mọ nitori iyan jija ati orikunkun.
وَإِذۡ قَتَلۡتُمۡ نَفۡسٗا فَٱدَّٰرَٰٔتُمۡ فِيهَاۖ وَٱللَّهُ مُخۡرِجٞ مَّا كُنتُمۡ تَكۡتُمُونَ 72
Ẹ ranti nigba ti ẹ pa ẹnikan lara yin, ti ẹ ntii si ara yin, gbogbo yin ni ẹ ngbe ifura ipaniyan kuro ni ọdọ ara yin, tiẹ si nfi ti si ọdọ ẹlomiran titi ti ẹ fi se ifanfa, Ọlọhun ni Olumujade nipa ohun ti ẹ nfi pamọ lori iku alailẹsẹ naa.
فَقُلۡنَا ٱضۡرِبُوهُ بِبَعۡضِهَاۚ كَذَٰلِكَ يُحۡيِ ٱللَّهُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ 73
A wa sọ fun yin pe: ẹ fi abala kan lara Maalu naa na oku ki o le sọ ẹni ti o paa, wọn se bẹẹ, ti oku naa si fun wọn ni iro nipa ẹni ti o pa a. Iru ijidide oku yii ni Ọlọhun Ọba yoo ji awọn oku dide ni Ọjọ Agbende, ti Yoo si fi han yin awọn ẹri ti o fi oju han lori agbara Rẹ ki ẹ le ba a jẹ ẹni ti yoo se laakaye nipa rẹ, ki ẹ si ni igbagbọ ninu Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) .
ثُمَّ قَسَتۡ قُلُوبُكُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ فَهِيَ كَٱلۡحِجَارَةِ أَوۡ أَشَدُّ قَسۡوَةٗۚ وَإِنَّ مِنَ ٱلۡحِجَارَةِ لَمَا يَتَفَجَّرُ مِنۡهُ ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ وَإِنَّ مِنۡهَا لَمَا يَشَّقَّقُ فَيَخۡرُجُ مِنۡهُ ٱلۡمَآءُۚ وَإِنَّ مِنۡهَا لَمَا يَهۡبِطُ مِنۡ خَشۡيَةِ ٱللَّهِۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ 74
Lẹyin naa, ọkan yin wa le koko, lẹyiin gbogbo awọn ibanisọsrọ eyiti o dogongo, ati arisami eyiti o fi oju han, titi ti o fi wa da bii okuta, koda o tun le ju okuta lọ, ti ko si lee parada kuro ni isesi ti o wa lailai, ẹẹ waa ri okuta, o ma nyipada, o si nparada, dajudaju o nbẹ ninu okuta eyiti omi ma njade ninu rẹ, bakannaa ni o si nbẹ ninu rẹ eyiti o ma nlanu pẹẹ, ti omi yoo si maa jade ninu rẹ, awọn isẹlẹru eyiti yoo maa san ni ori ilẹ, ti awọn eniyan yoo si maa se anfaani pẹlu rẹ ati awọn ẹranko, o si nbẹ ninu rẹ eyiti o ma njabọ lati ibi ti o ga nibi oke niti ipaya Ọlọhun Ọba ati ibẹru Rẹ, ti o si jẹ wipe ọkan yin ko ri bẹẹ, Ọlọhun Ọba Allah Kii se Ẹniti ko mọ ohun ti ẹ ngbese nisẹ bikise wipe O ni imọ pẹlu rẹ, Yoo si san yin lẹsan lori rẹ.
۞أَفَتَطۡمَعُونَ أَن يُؤۡمِنُواْ لَكُمۡ وَقَدۡ كَانَ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۡ يَسۡمَعُونَ كَلَٰمَ ٱللَّهِ ثُمَّ يُحَرِّفُونَهُۥ مِنۢ بَعۡدِ مَا عَقَلُوهُ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ 75
Se ẹ nrankan ni - ẹyin Muumini - lẹyin igbati ẹ ti mọ paapaa isesi awọn Yahuudi ati igbẹrugbọnri wọn pe ki wọn ni igbagbọ, ki wọn si dayin lohun?! Ati wipe paapaa, awọn ijọ kan ninu awọn onimimọ wọn, wọn ma ngbọ ọrọ Ọlọhun Ọba eyiti wọn sọkalẹ fun wọn ninu Taoreeta, lẹyin igbanaa ni wọn yoo wa maa yi awọn gbolohun rẹ pada ati awọn itumọ rẹ lẹyin igbati wọn ti gbọ agbọye rẹ, ti wọn si ti ni imọ nipa rẹ, ti o si jẹ wipe awọn naa mọ titobi ọran ti wọn da yii.
وَإِذَا لَقُواْ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا وَإِذَا خَلَا بَعۡضُهُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٖ قَالُوٓاْ أَتُحَدِّثُونَهُم بِمَا فَتَحَ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمۡ لِيُحَآجُّوكُم بِهِۦ عِندَ رَبِّكُمۡۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ 76
Ninu awọn ọrọ Yahuudi ti o tako ara wọn, ati ete wọn ni wipe dajudaju ti apakan ninu wọn ba pade awọn Muumini, wọn yoo jọwọ ara wọn fun wọn pẹlu gbigba Anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun ko ma baa) ni ododo ati nini alaafia isẹ ti wọn fi ran, ti o si jẹ wipe ohun ni Taoreeta jẹri si, sugbọn nigbati awọn Yahuudi, apakan wọn ba wa pẹlu apakan, wọn yoo maa bu ara wọn ni aarin ara wọn nitori ijọwọ ara ẹni yii; toripe awọn Musulumi, wọn yoo fi eleyi jẹri le wọn lori nibi nkan ti o sẹlẹ lati ọdọ wọn nibi gbigba Anọbi ni ododo.
Dajudaju apakan ọkan awọn ẹrusin, o le koko ju okuta ti o le lọ; ti ko si nii rọ fun gbigbọ isiti, bakannaa ni ko nii lẹ fun iranti.
Dajudaju awọn itọka ati awọn alaye - koda ki o tobi - ko nii se anfaani nigbati ọkan ko ba fi gbafa, ti ko si tẹriba fun Ọlọhun Allah.
Awọn aayah yii sisọ loju paapa awọn nkan ti nbẹ ninu ọkan awọn Yahuudi nigbati o jẹ wipe wọn jogun iseyẹyẹ, ẹtan ati ere pẹlu ẹsin.