فَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمۡ جَعَلَ ٱلسِّقَايَةَ فِي رَحۡلِ أَخِيهِ ثُمَّ أَذَّنَ مُؤَذِّنٌ أَيَّتُهَا ٱلۡعِيرُ إِنَّكُمۡ لَسَٰرِقُونَ 70
Nigbati Yuusuf pasẹ fun awọn ọmọ ọdọ rẹ wipe ki wọn gbe rakunmi awọn ọmọ baba rẹ yii pẹlu ounjẹ, o wa awọn osunwọn ọba ti wọn fi nwọn ounjẹ fun awọn osisẹ rẹ si inu apo ọmọ iya ọmọ baba rẹ laisi imọ wọn nibẹ, ki o le fi se itẹgun lati mu duro pẹlu rẹ, nigbati wọn nlọ ni ẹniti nsẹri lọ si ọdọ awọn ara ile wọn, olupepe kan pepe ni ẹyin wọn: ẹyin onirakunmi ti o gbe ounjẹ irin ajo, o le ni yin o.
قَالُواْ وَأَقۡبَلُواْ عَلَيۡهِم مَّاذَا تَفۡقِدُونَ 71
Awọn ọmọ baba Yuusuf sọ wipe: wọn si da oju kọ ẹniti o npepe lẹyin wọn ati awọn ti o wa pẹlu rẹ: kinni ohun ti o sọnu lọdọ yin ti ẹ fi nfura ole si wa?
قَالُواْ نَفۡقِدُ صُوَاعَ ٱلۡمَلِكِ وَلِمَن جَآءَ بِهِۦ حِمۡلُ بَعِيرٖ وَأَنَا۠ بِهِۦ زَعِيمٞ 72
Olupepe sọrọ ati awọn ti o wa pẹlu rẹ fun awọn ọmọ baba yusuf, osunwọn ọba ni o sọnu lọdọ wa ti a fi nwọn nkan, ẹnikẹni ti o ba si mu osunwọn ọba yii wa siwaju ki a to maa se iwadi rẹ ni ohun ti awa yoo fun un, ohun naa ni ẹru odidi rakunmi kan, emi si fi ẹni naa lọkan balẹ.
قَالُواْ تَٱللَّهِ لَقَدۡ عَلِمۡتُم مَّا جِئۡنَا لِنُفۡسِدَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا كُنَّا سَٰرِقِينَ 73
Awọn ọmọ baba Yuusuf sọ fun wipe: a fi Ọlọhun Ọba Allah bura, ẹyin gan ti mọ mimọ kanga nibi bibọpa bọsẹ wa gẹgẹ bi ẹ se ri nibi awọn isesi wa, awa ko wa si ilẹ misira lati ba ibẹ jẹ, awa kii se ole ninu igbesi aye wa.
قَالُواْ فَمَا جَزَٰٓؤُهُۥٓ إِن كُنتُمۡ كَٰذِبِينَ 74
Olupepe yii ati awọn eniyan rẹ sọ wipe: kinni ko jẹ ẹsan ẹniti o ba ji ninu yin, ti o ba lọ ja si wipe irọ ni mimọ kanga yin kuro nibi ole ti ẹ sọ?
قَالُواْ جَزَٰٓؤُهُۥ مَن وُجِدَ فِي رَحۡلِهِۦ فَهُوَ جَزَٰٓؤُهُۥۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلظَّٰلِمِينَ 75
Awọn ọmọ baba Yuusuf sọ fun wipe: ẹsan ole lọdọ wa ni wipe ẹniti a ba ri ohun ti wọn ji ninu apo rẹ yoo ju ọrun rẹ silẹ fun ẹniti o ji nkan ti yoo ma se ẹru rẹ, iru ẹsan yii nibi jiju ọrun ẹni silẹ ni a ma nsan fun gbogbo ole.
فَبَدَأَ بِأَوۡعِيَتِهِمۡ قَبۡلَ وِعَآءِ أَخِيهِ ثُمَّ ٱسۡتَخۡرَجَهَا مِن وِعَآءِ أَخِيهِۚ كَذَٰلِكَ كِدۡنَا لِيُوسُفَۖ مَا كَانَ لِيَأۡخُذَ أَخَاهُ فِي دِينِ ٱلۡمَلِكِ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ نَرۡفَعُ دَرَجَٰتٖ مَّن نَّشَآءُۗ وَفَوۡقَ كُلِّ ذِي عِلۡمٍ عَلِيمٞ 76
Wọn ba da wọn pada si ọdọ Yuusuf lati se iwadi awọn apo wọn, bayi sise iwadi awọn apo awọn ọmọ baba rẹ bẹrẹ siwaju sise iwadi apo ọmọ iya ọmọ baba gan an lati daabobo ete naa, lẹyin igba naa ni wọn wa se iwadi apo ọmọ kiya ọmọ baba, wọn si mu osunwọn ọba jade nibẹ, gẹgẹ bi a se da ete fun Yuusuf pẹlu lilo ọgbọn fifi osunwọn sinu apo ọmọ iya rẹ, bẹẹ naa ni a se da ete fun alamọri miran, ki o mu awọn ọmọ baba rẹ pẹlu fifi iya ilu wọn tii se iju ọrun ẹni silẹ ole, ọrọ yii ko le di ododo ti wọn ba lo ijiya ọba fun ole eyiti tii se lilu ati owo itanran ayaafi ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ eto miran, O si ni agbara le lori. Awa ni a ma nse agbega ipo ẹniti o ba wu wa ninu ẹru Wa gẹgẹ bi a se se agbega ipo yusuf, onimimọ julọ miran nbẹ loke gbogbo onimimọ, bẹẹ ni imọ Ọlọhun Ọba Allah ti O mọ gbogbo nkan nbẹ loke gbogbo imọ ẹda.
۞قَالُوٓاْ إِن يَسۡرِقۡ فَقَدۡ سَرَقَ أَخٞ لَّهُۥ مِن قَبۡلُۚ فَأَسَرَّهَا يُوسُفُ فِي نَفۡسِهِۦ وَلَمۡ يُبۡدِهَا لَهُمۡۚ قَالَ أَنتُمۡ شَرّٞ مَّكَانٗاۖ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا تَصِفُونَ 77
Awọn ọmọ baba Yuusuf sọ wipe: ti o ba jale kii se ijọniloju, ọmọ iya rẹ ọmọ baba rẹ ti jale saaju ole tirẹ yii, ẹniti wọn gbero ni yusuf ti ọla nbẹ fun, yusuf si fi pamọ ki kan an labuku ọrọ wọn yii, ko se afihan rẹ fun wọn, o wa sọ fun ninu ẹmin rẹ bayi wipe: keeta ti ẹ wa lori rẹ ati isẹ aburu yin ti siwaju lọdọ yin, ohun ni ojulowo aburu ni aaye yii, Ọlọhun Ọba ti o ga julọ si mọ adapa irọ ti o jade ni ọdọ yin yii.
قَالُواْ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡعَزِيزُ إِنَّ لَهُۥٓ أَبٗا شَيۡخٗا كَبِيرٗا فَخُذۡ أَحَدَنَا مَكَانَهُۥٓۖ إِنَّا نَرَىٰكَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 78
Awọn ọmọ baba Yuusuf sọ fun Yuusuf: irẹ ọba, dajudaju baba agbalagba ti o ti tẹ kọrọ lọjọ ori nbẹ fun ti nifẹ rẹ pupọ, mu ẹnikan ninu wa dipo rẹ, dajudaju a ri ọ ni oluse daadaa nibi ibasepọ wa ati ibasepọ rẹ si ẹlomiran, yaa se daadaa pẹlu eleyi si wa.
Titọ dida ete eyiti o ba le muni de ibi ododo pẹlu majẹmu ki inira ma si nibẹ fun ẹlomiran.
Titọ fun ẹniti o ni ohun ti o sọnu tabi nkan ti o sọnu gan, gbigbe nkan ẹbun kan kalẹ, ki a se adayanri odiwọn rẹ ati iroyin rẹ fun ẹniti o ba kun ni lọwọ lati daa pada.
Sise amojukuro nibi suta ati fifipamọ sinu ẹmin wa ninu awọn iwa daadaa.