كَيۡفَ يَكُونُ لِلۡمُشۡرِكِينَ عَهۡدٌ عِندَ ٱللَّهِ وَعِندَ رَسُولِهِۦٓ إِلَّا ٱلَّذِينَ عَٰهَدتُّمۡ عِندَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۖ فَمَا ٱسۡتَقَٰمُواْ لَكُمۡ فَٱسۡتَقِيمُواْ لَهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُتَّقِينَ 7
Ko tọ ki adehun tabi ifọkanbalẹ lati ọdọ Ọlọhun tabi lati ọdọ ojisẹ ki o maa bẹ pẹlu awọn ọlọsẹbọ pẹlu Ọlọhun Ọba ayaafi adehun awọn ọlọsẹbọ eyiti ẹ jọ ni adehun - ẹyin olugbafa - ni mọsalaasi ọwọ nibi atunse ‘Hudaybiyah’, ti wọn ba duro lori adehun ti o wa laarin yin ati wọn, ti wọn ko si ja adehun naa, ki ẹyin duro le lori, ki ẹ si ma ja adehun naa, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nifẹ awọn olupaya Rẹ ninu awọn ẹru Rẹ ti ntẹle asẹ Rẹ, ti wọn si njinna si ohun ti o kọ.
كَيۡفَ وَإِن يَظۡهَرُواْ عَلَيۡكُمۡ لَا يَرۡقُبُواْ فِيكُمۡ إِلّٗا وَلَا ذِمَّةٗۚ يُرۡضُونَكُم بِأَفۡوَٰهِهِمۡ وَتَأۡبَىٰ قُلُوبُهُمۡ وَأَكۡثَرُهُمۡ فَٰسِقُونَ 8
Bawo ni yoo se maa bẹ fun adehun ati ifọkanbalẹ ti wọn si jẹ ọta yin, ti wọn ba le gun ori yin, wọn ko nii wo ti Ọlọhun tabi asunmọ mọ yin lara tabi adehun, bikose wipe wọn yoo fi ija buruku jẹ yin ni?! Wọn yoo maa wa iyọnu yin pẹlu ọrọ ti o dara eyiti wọn nfi ahọn wọn sọ sugbọn ọkan wọn ko se deedee ahọn wọn, wọn kii sọ nkan ti wọn nsọ, ọpọ wọn ma nkuro nibi itẹle ti Ọlọhun Ọba Allah nitori adehun wọn ti wọn nja.
ٱشۡتَرَوۡاْ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ ثَمَنٗا قَلِيلٗا فَصَدُّواْ عَن سَبِيلِهِۦٓۚ إِنَّهُمۡ سَآءَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 9
Wọn gunri, wọn si se pasi paarọ awọn itẹle awọn amin Ọlọhun Ọba Allah eyiti pipe adehun wa nibẹ ni iye yẹpẹrẹ ninu awọn ọrọ aye eyiti wọn ntọ lati de ibi adun wọn ati ifẹ inu wọn, wọn kọ di ẹmin ara wọn lati kọ di ododo, dajudaju isẹ ti wọn se jẹ aburu.
لَا يَرۡقُبُونَ فِي مُؤۡمِنٍ إِلّٗا وَلَا ذِمَّةٗۚ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُعۡتَدُونَ 10
Wọn ko wo ti Ọlọhun Ọba tabi ti asunmọ tabi adehun nibi olugbagbọ ododo kan; lori ijọta ti wọn wa, wọn jẹ ẹniti o kọja ẹnu aala ti Ọlọhun Ọba Allah; latara iroyin abosi ati ijọta ti o wa pẹlu wọn.
فَإِن تَابُواْ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُاْ ٱلزَّكَوٰةَ فَإِخۡوَٰنُكُمۡ فِي ٱلدِّينِۗ وَنُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ 11
Ti wọn ba ronu piwada lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah kuro nibi keferi wọn, ti wọn wi gbolohun ijẹri mejeeji jade, ti wọn ngberun duro, ti wọn si nya saka ninu owo wọn, wọn ti di olugbafa, wọn si di ọmọ iya yin ninu ẹsin, ẹtọ ti nbẹ fun wọn lo wa fun yin, bẹẹ ni ijiya ti o wa le wọn lori ni o wa fun ẹyin naa, kotọ fun yin ki ẹ ba wọn ja, gbigba Islam wọọn ti daabobo ẹjẹ wọn, ati awọn dukia ati ọmọluwabi wọn, a nsalaye awọn aayah wa, a si nfọ ọ si wẹwẹ fun awọn ijọ ti wọn nimọ, awọn eniti yoo se anfaani pẹlu rẹ, ti wọn yoo si se ẹlomiran naa ni anfaani.
وَإِن نَّكَثُوٓاْ أَيۡمَٰنَهُم مِّنۢ بَعۡدِ عَهۡدِهِمۡ وَطَعَنُواْ فِي دِينِكُمۡ فَقَٰتِلُوٓاْ أَئِمَّةَ ٱلۡكُفۡرِ إِنَّهُمۡ لَآ أَيۡمَٰنَ لَهُمۡ لَعَلَّهُمۡ يَنتَهُونَ 12
Ti awọn ọlọsẹbọ ti ẹ ba ni adehun lori aini ba wọn ja fun asiko kan pato ba ja adehun wọn ati ifọwọsowọpọ wọn, ti wọn wa nbu ẹsin yin, ti wọn si nsọ aleebu rẹ, ki ẹ ya ba wọn ja, awọn ni asiwaju keferi ati adari rẹ, ko si adehun kankan fun wọn, bẹẹ si ni ko si ifọwọsowọpọ kankan ti yoo daabobo ẹjẹ wọn fun wọn, ẹ ba wọn ja nireti ki wọn le ja wọ kuro nibi sise keferi wọn, ati yiyẹ adehun wọn, ati sisọ aleebu ẹsin.
أَلَا تُقَٰتِلُونَ قَوۡمٗا نَّكَثُوٓاْ أَيۡمَٰنَهُمۡ وَهَمُّواْ بِإِخۡرَاجِ ٱلرَّسُولِ وَهُم بَدَءُوكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةٍۚ أَتَخۡشَوۡنَهُمۡۚ فَٱللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخۡشَوۡهُ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ 13
Ki lode ti ẹyin ko ni ba wọn ja - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn ijọ ti wọn nja adehun yin ati ifọwọsowọpọ yin, ti wọn si se igbiyanju lati ko wọn jọ si inu ile ‘nadiwa’ lati le ojisẹ (ki ikẹ ati Ola Ọlọhun maa ba) kuro ni Mẹkkah, awọn ni wọn kọkọ bẹrẹ ija pẹlu yin ni akọkọ, ni igbati wọn kun Bakiri lọwọ gẹgẹ bi awọn alasunmọ Kurayshi lori ‘khuzaa’ah’ gẹgẹ bi awọn alasunmọ ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, se ẹ npaya wọn ni ẹ ko fi fẹ maa gbawaju lati ba wọn ja?! Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun ni ki ẹ bẹru ti ẹ ba jẹ olugbagbọ ododo tootọ.
Awọn aayah naa tọka si wipe biba awọn ọlọsẹbọ ti ja adehun ija jẹ nitori awọn idi ti o pọ, pataki julọ rẹ: ni jija adehun.
Ẹri lori ẹniti o ba kọ lati kirun tabi yọ saka, yoo di ẹni igbogunti titi ti yoo fi se wa ninu awọn aayah naa, gẹgẹ bi Abu Bakr se se.
Apakan awọn onimimọ fi gbolohun Ọlọhun se ẹri: (وَطَعَنُواْ فِي دِينِكُمۡ) (wọn so aida nipa ẹsin yin) lori jijẹ ọranyan pipa gbogbo ẹniti o ba so nkan ti ko dara nipa ẹsin niti imaamọ tabi sise yẹyẹ.
Ẹri lori wipe olugbagbọ ododo ti o npaya Allah nikan soso, o di dandan ki o jẹ ẹniti o ni akin ju, tabi ni igboya ju lati jagun wa ninu awọn aayah naa.