أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ مَا يَكُونُ مِن نَّجۡوَىٰ ثَلَٰثَةٍ إِلَّا هُوَ رَابِعُهُمۡ وَلَا خَمۡسَةٍ إِلَّا هُوَ سَادِسُهُمۡ وَلَآ أَدۡنَىٰ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكۡثَرَ إِلَّا هُوَ مَعَهُمۡ أَيۡنَ مَا كَانُواْۖ ثُمَّ يُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُواْ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ 7
Se o ko ri ni - irẹ ojisẹ - wipe dajudaju Allah mọ ohun ti o wa ni gbogbo sanmọ, O si mọ ohun ti o wa ninu ilẹ, nkankan ko pamọ fun ninu ohun ti o wa ninu mejeeji, ọrọ kọkọ mẹta kan ko nii waye ayaafi ki Oun ti mimọ nbẹ fun se ẹlẹẹkẹrin wọn ninu imọ Rẹ, bẹẹni ọrọ marun kan ko nii waye ni kọkọ ayaafi ki Oun ti mimọ nbẹ fun se ẹlẹẹkẹfa wọn ninu imọ Rẹ, ko si nii dinku ni onka yii tabi ki o pọ ju u lọ ayaki O wa pẹlu wọn ninu imọ Rẹ nibi ki bi ti wọn ba wa, nkankan ninu ọrọ wọn ko pamọ fun Un, lẹyin naa Allah yoo fun wọn niro ohun ti wọn se ni ọjọ igbende, dajudaju Allah jẹ onimmimọ si gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un.
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ نُهُواْ عَنِ ٱلنَّجۡوَىٰ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا نُهُواْ عَنۡهُ وَيَتَنَٰجَوۡنَ بِٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِ وَمَعۡصِيَتِ ٱلرَّسُولِۖ وَإِذَا جَآءُوكَ حَيَّوۡكَ بِمَا لَمۡ يُحَيِّكَ بِهِ ٱللَّهُ وَيَقُولُونَ فِيٓ أَنفُسِهِمۡ لَوۡلَا يُعَذِّبُنَا ٱللَّهُ بِمَا نَقُولُۚ حَسۡبُهُمۡ جَهَنَّمُ يَصۡلَوۡنَهَاۖ فَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ 8
Se o ko ri - irẹ ojisẹ - awọn yahuudi ti wọn nsọrọ kẹlẹkẹlẹ nigbati wọn ba ri olugbagbọ ododo kan, Allah si kọ fun wọn kuro nibi ọrọ kẹlẹkẹlẹ, lẹyin naa wọn si sẹri si ibi ohun ti Allah kọ fun wọn kuro nibẹ, wọn si nsọ ọrọ kẹlẹkẹlẹ laarin wọn eyiti ẹsẹ nbẹ nibẹ gẹgẹ bi sisọrọ awọn olugbagbọ ododo lẹyin ati biba wọn se ọta ati yiyapa ojisẹ naa ti o wa nibẹ, ti wọn ba si wa ba ọ - irẹ ojisẹ - wọn yoo ki ọ ni kiki ti Allah ko fi ki ọ; ohun si ni gbolohun wọn pe: ‘As Saamu’ ki o maa ba ọ ohun ti wọn si gbero ni iku, wọn yoo si waa ma sọ ni ẹniti o nparọ fun anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun: se Allah ko nii fi iya jẹ wa pẹlu ohun ti a nsọ nigbati o ba ja sipe o jẹ olododo nibi ohun ti o npe apemọra rẹ wipe anọbi ni oun, Allah ki ba fi iya jẹ wa nipa ohun ti a nsọ nipa rẹ! Ina jahannamọ to fun wọn ni ijiya lori ohun ti wọn nsọ, wọn yoo fi ara kin igbona rẹ, ibusẹrisi wọn yii si jẹ ibusẹrisi buruku.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا تَنَٰجَيۡتُمۡ فَلَا تَتَنَٰجَوۡاْ بِٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِ وَمَعۡصِيَتِ ٱلرَّسُولِ وَتَنَٰجَوۡاْ بِٱلۡبِرِّ وَٱلتَّقۡوَىٰۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِيٓ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ 9
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se ohun ti wọn se lofin fun wọn, ẹ mase sọrọ kẹlẹkẹlẹ ti o ni ẹsẹ ninu tabi ọta tabi iyapa ojisẹ naa, ki ẹ maa ba da gẹgẹ bi yahuudi, ẹ maa sọ kẹlẹ ti itẹle ti Allah wa nibẹ ati ikoraro kuro nibi yiyapa rẹ, ki ẹ si paya Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, ọdọ Rẹ nikan ni wọn yoo ko yin jọ si fun isiro ati ẹsan.
إِنَّمَا ٱلنَّجۡوَىٰ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ لِيَحۡزُنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَلَيۡسَ بِضَآرِّهِمۡ شَيًۡٔا إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ 10
Dajudaju ọrọ kẹlẹkẹlẹ - eyiti o kojọ lori ẹsẹ ati ọta ati iyapa ojisẹ - wa ninu ohun ti esu se lọsọ ati royiroyi rẹ fun awọn ẹni tirẹ; ki o le mu ibanujẹ ba awọn olugbagbọ ododo wipe wọn nda ete si wọn, bẹẹn esu tabi sise e lọsọ ko le mu inira ba awọn olugbagbọ ododo kankan ayaafi pẹlu fifẹ Allah ati erongba Rẹ, Allah ni ki awọn olugbagbọ ododo si gbarale nibi gbogbo awọn ọrọ wọn.
Nigbati Allah sọ ẹkọ ti o wa nibi awọn gbolohun, O tun sọ ẹkọ ti o wa nibi awọn aaye ijoko, O si sọpe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا قِيلَ لَكُمۡ تَفَسَّحُواْ فِي ٱلۡمَجَٰلِسِ فَٱفۡسَحُواْ يَفۡسَحِ ٱللَّهُ لَكُمۡۖ وَإِذَا قِيلَ ٱنشُزُواْ فَٱنشُزُواْ يَرۡفَعِ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنكُمۡ وَٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ دَرَجَٰتٖۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ 11
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se ohun ti wọn se lofin fun wọn, ti wọn ba sọ fun yin wipe: ẹ fi igbalaaye silẹ nibi awọn ijoko, ki ẹ ya fi igbalaaye silẹ, Allah yoo gba yin laaye ninu isẹmin aye yin ati ni ọrun, nigbati wọn ba si sọ fun yin: ki ẹ kuro nibi awọn aaya ijoko ki awọn ọlọla le joko nibẹ, ki ẹ ya kuro nibẹ, Allah ti mimọ nbẹ fun yoo maa se agbega fun awọn ti o nigbagbọ ninu yin ati awọn ti wọn fun ni imọ ni awọn agbega ti o tobi, Allah si jẹ olufunniro ohun ti ẹ nse nisẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu awọn isẹ yin, yoo si san yin lẹsan le lori.
Gẹgẹ bi o se ja si wipe Allah ga niti bibẹ Rẹ lori ẹda Rẹ; bikosepe o jẹ oluri wọn pẹlu imọ ti nkankan ko pamọ fun Un.
Nigbati ọpọ awọn ẹda nda ẹsẹ ni sisọrọ kẹlẹkẹlẹ, Allah waa pasẹ fun awọn olugbagbọ ododo wipe ki ọrọ kẹlẹkẹlẹ wọn jẹ rere ati ipaya.
Ninu awọn ẹkọ aaye ijoko ohun ni igbani laaye nibẹ fun awọn ẹlomiran.