خُشَّعًا أَبۡصَٰرُهُمۡ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ كَأَنَّهُمۡ جَرَادٞ مُّنتَشِرٞ 7
Ni ẹniti iriran wọn kọlẹ, wọn njade ninu saare wọn gẹgẹ bi ẹni pe ibudu isiro ni wọn nlọ nibi irin wọn gẹgẹ bi ata ti o fan ka.
مُّهۡطِعِينَ إِلَى ٱلدَّاعِۖ يَقُولُ ٱلۡكَٰفِرُونَ هَٰذَا يَوۡمٌ عَسِرٞ 8
Ni ẹniti o nyara lọ si ọdọ olupepe lọsi ibi ibudo naa, awọn keferi yoo maa sọpe: ọjọ yii jẹ ọjọ inira; fun ilekoko ati awọn ipaya ti o wa nibẹ.
Nigbati Allah sọ igunri awọn keferi kuro nibi ipepe ojisẹ wa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, O fun un niro wipe dajudaju awọn ijọ ti o siwaju pe awọn ojisẹ wọn nirọ; ki o le jẹ itutu ẹmin fun un, O wa sọpe:
۞كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ فَكَذَّبُواْ عَبۡدَنَا وَقَالُواْ مَجۡنُونٞ وَٱزۡدُجِرَ 9
Wọn ti pe ijọ Nuha nirọ siwaju awọn olupe ipepe rẹ ni irọ - irẹ ojisẹ - wọn pe ẹru Wa Nuha ti ọla nbẹ fun nirọ nigbati a gbe dide si wọn, wọn si sọ nipa rẹ wipe: o jẹ were, wọn si yẹpẹrẹ rẹ pẹlu oniranran eebu, epe, idẹruba ti ko ba gbe gbigbe wọn ju silẹ.
فَدَعَا رَبَّهُۥٓ أَنِّي مَغۡلُوبٞ فَٱنتَصِرۡ 10
Nuha si pe Ọlọhun Ọba rẹ ni ẹniti o sọpe: dajudaju awọn ijọ mi bori mi, wọn ko si jẹpe mi, o si ri aranse nipa sisọkalẹ iya le wọn lori.
فَفَتَحۡنَآ أَبۡوَٰبَ ٱلسَّمَآءِ بِمَآءٖ مُّنۡهَمِرٖ 11
A si si awọn ilẹkun sanmọ fun omin ti o nda lọpọnpọn ni titẹle ara wọn.
وَفَجَّرۡنَا ٱلۡأَرۡضَ عُيُونٗا فَٱلۡتَقَى ٱلۡمَآءُ عَلَىٰٓ أَمۡرٖ قَدۡ قُدِرَ 12
A si la oju fun ilẹ ti o di ibusun omin, omin ti o nsọkalẹ lati sanmọ si pade pẹlu omin ti o nsun ni ilẹ niti asẹ lati ọdọ Allah ti o ti pebubu rẹ tipẹtipẹ, o si mu itẹri ba gbogbo wọn ayaafi ẹniti Allah la.
وَحَمَلۡنَٰهُ عَلَىٰ ذَاتِ أَلۡوَٰحٖ وَدُسُرٖ 13
A si gbe Nuha si inu ọkọ oju omin ti o ni awọn ọpọn ati awọn eso, bẹẹni a si la a ati awọn ti o wa pẹlu rẹ kuro nibi itẹri.
تَجۡرِي بِأَعۡيُنِنَا جَزَآءٗ لِّمَن كَانَ كُفِرَ 14
Ọkọ oju omin yii si nlọ nibi agbara omin eyiti o kun pẹlu iriran wa ati aabo niti sise aranse fun Nuha eyiti awọn ijọ rẹ pe e nirọ, wọn si se keferi si ohun ti o mu wa fun ba wọn lati ọdọ Allah.
وَلَقَد تَّرَكۡنَٰهَآ ءَايَةٗ فَهَلۡ مِن مُّدَّكِرٖ 15
Paapaa a si se iya ti a fi jẹ wọn yii ni ariwoye ati isiti, njẹ oluwoye ti o woye pẹlu rẹ wa bii?!
فَكَيۡفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ 16
Bawo ni iya mi yoo se ri fun awọn opurọ?! Bawo si ni ikilọ mi ati imu iparun mi ba wọn yoo se ri?!
وَلَقَدۡ يَسَّرۡنَا ٱلۡقُرۡءَانَ لِلذِّكۡرِ فَهَلۡ مِن مُّدَّكِرٖ 17
Paapaa a si ti rọ Alukuraani fun ise iranti ati isiti, njẹ oluse ariwoye pẹlu ohun ti o wa ninu rẹ ninu oye ati awọn isiti wa bi?!
كَذَّبَتۡ عَادٞ فَكَيۡفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ 18
Haadi pe anọbi rẹ huudu ti ọla nbẹ fun nirọ ki ẹ ronu - ẹyin ara Mẹkkah - bi iya mi se ri fun wọn?! Ati bi ikilọ mi fun ẹniti o yatọ si wọn nipa fifi iya jẹ wọn yoo se ri?!
إِنَّآ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا صَرۡصَرٗا فِي يَوۡمِ نَحۡسٖ مُّسۡتَمِرّٖ 19
A gbe atẹgun lile ti o tutu dide si wọn ni ọjọ buruku ati aburu ti o ntẹsiwaju pẹlu wọn, ti yoo fi pe wọn lọ si inu ina jahannamọ.
تَنزِعُ ٱلنَّاسَ كَأَنَّهُمۡ أَعۡجَازُ نَخۡلٖ مُّنقَعِرٖ 20
Wọn yoo maa hun awọn eniyan kuro ni inu ilẹ, yoo si maa ju wọn si ori wọn gẹgẹ bu ẹni pe wọn jẹ ipilẹ igi ọpẹ ti a hun ni ibugbin rẹ.
فَكَيۡفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ 21
Ki ẹ ronu - ẹyin ara Mẹkkah - bawo ni iya se ri fun wọn?! Atipe bawo ni ikilọ mi nipa fifi iya jẹ wọn yoo se ri?!
وَلَقَدۡ يَسَّرۡنَا ٱلۡقُرۡءَانَ لِلذِّكۡرِ فَهَلۡ مِن مُّدَّكِرٖ 22
Paapaa a si rọ Alukuraani fun iranti ati isiti, njẹ oluwoye pẹlu ohun ti o wa ninu rẹ nipa oye ati awọn isiti wa bi?!
كَذَّبَتۡ ثَمُودُ بِٱلنُّذُرِ 23
Samuudu pe ohun ti ojisẹ wọn Sọlihun ẹniti ọla nbẹ fun fi se ikilọ fun wọn nirọ.
فَقَالُوٓاْ أَبَشَرٗا مِّنَّا وَٰحِدٗا نَّتَّبِعُهُۥٓ إِنَّآ إِذٗا لَّفِي ضَلَٰلٖ وَسُعُرٍ 24
Wọn sọ ni ẹniti o nse atako: se a o tẹle abara kan ninu iran wa ni ?! dajudaju ti a ba tẹle ni asiko yii paapaa a wa ni ibi ti o jinna si deedee ati itakete si i ati inu inira.
أَءُلۡقِيَ ٱلذِّكۡرُ عَلَيۡهِ مِنۢ بَيۡنِنَا بَلۡ هُوَ كَذَّابٌ أَشِرٞ 25
Se wọn yoo sọ imisi kalẹ fun un ti o si jẹ oun nikan, wọn yoo wa fi sa a lẹsa yatọ si awa lapapọ?! Rara bikosepe o jẹ opurọ onigberaga.
سَيَعۡلَمُونَ غَدٗا مَّنِ ٱلۡكَذَّابُ ٱلۡأَشِرُ 26
Wọn yoo pada mọ ẹniti o jẹ opurọ onigberaga, se Sọlihun ni tabi awọn ni ọjọ igbende?
إِنَّا مُرۡسِلُواْ ٱلنَّاقَةِ فِتۡنَةٗ لَّهُمۡ فَٱرۡتَقِبۡهُمۡ وَٱصۡطَبِرۡ 27
Dajudaju awa ni a o mu rakunmi jade ninu apata, a o si gbe e dide ki o le jẹ idanwo fun wọn, ki o ma reti - irẹ Sọlihu - ki o si maa sọ ohun ti wọn yoo se pẹlu rẹ ati ohun ti wọn yoo se pẹlu wọn, ki o si se suuru lori suta wọn.
Sise lofin sisepe le keferi ti o ba taku lori keferi rẹ.
Mimu iparun ba awọn opurọ ati lila awọn olugbagbọ ododo jẹ isesi Ọlọhun.
Rirọ Alukuraani fun hiha sori ati iranti ati isiti.