وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلۡحُبُكِ 7
Allah si tun bura pẹlu sanmọ ti o dara ni isẹda, ti o si tun ni awọn oju ọna.
إِنَّكُمۡ لَفِي قَوۡلٖ مُّخۡتَلِفٖ 8
Dajudaju ẹyin - ẹyin ara Mẹkkah - wa ninu gbolohun ti o tako ara wọn, ti o si fi ori gbara, nigba kan ẹ nsọpe: Alukuraani jẹ idan, nigba miran orin, ẹ wa nsọpe: Muhammad jẹ onidan ni igba kan, ni igba miran o jẹ olorin.
يُؤۡفَكُ عَنۡهُ مَنۡ أُفِكَ 9
Isikiro nibi igbagbọ ma nsẹlẹ lati ara Alukuraani ati anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ẹniti wọn ba fẹ mu kuro nibẹ ninu imọ Allah; nitori imọ Rẹ wipe ko nii ni igbagbọ, ko si nii se kongẹ imọna.
قُتِلَ ٱلۡخَرَّٰصُونَ 10
Wọn sẹbile awọn opurọ yii ti wọn nsọ nipa Alukuraani ati anọbi wọn ohun ti wọn nsọ.
ٱلَّذِينَ هُمۡ فِي غَمۡرَةٖ سَاهُونَ 11
Awọn ti o wa ninu aimọkan, ti wọn si jẹ olufọnu nipa ile ọrun, ti wọn ko ni akakun rẹ.
يَسَۡٔلُونَ أَيَّانَ يَوۡمُ ٱلدِّينِ 12
Wọn nbeere: igba wo ni ọjọ ẹsan? Wọn ko si siẹ fun un.
يَوۡمَ هُمۡ عَلَى ٱلنَّارِ يُفۡتَنُونَ 13
Allah fesi fun wọn nipa ibeere wọn: ọjọ ti wọn yoo jiya ninu ina.
ذُوقُواْ فِتۡنَتَكُمۡ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تَسۡتَعۡجِلُونَ 14
Wọn yoo sọ fun wọn: ẹ maa jiya yin, eleyi ni ohun ti ẹ nbeere kikanju nigbati wọn fi nse ikilọ fun yin; niti ise yẹyẹ.
إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي جَنَّٰتٖ وَعُيُونٍ 15
Dajudaju awọn olubẹru Ọlọhun Ọba wọn pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn ohun ti o kọ, wọn yoo wa ninu ọgba ati awọn isẹlẹru ti nsan ni ọjọ igbende.
ءَاخِذِينَ مَآ ءَاتَىٰهُمۡ رَبُّهُمۡۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَبۡلَ ذَٰلِكَ مُحۡسِنِينَ 16
Ni ẹniti yoo maa gba ohun ti Ọlọhun wọn fun wọn ni ẹsan apọnle, wọn ti jẹ oluse daadaa ni ile aye siwaju ẹsan apọnle yii.
كَانُواْ قَلِيلٗا مِّنَ ٱلَّيۡلِ مَا يَهۡجَعُونَ 17
Wọn jẹ ẹniti o ma nkirun loru, wọn kii sun ayaafi asiko diẹ.
وَبِٱلۡأَسۡحَارِ هُمۡ يَسۡتَغۡفِرُونَ 18
Wọn yoo maa wa aforijin ni ọdọ Allah fun ẹsẹ wọn ni asiko idaarun mọju.
وَفِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقّٞ لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ 19
Wọn - si ma nse ọrẹ atinuwa - ninu dukia wọn fun olubeere ninu awọn eniyan ati fun ẹniti ko bi wọn leere, ninu awọn ti wọn se arisiki leewọ fun nitori eyikeyi idi.
وَفِي ٱلۡأَرۡضِ ءَايَٰتٞ لِّلۡمُوقِنِينَ 20
Awọn ẹri lori agbara Allah fun awọn olumọ amọdaju wipe dajudaju Allah jẹ asẹda ayaworan wa ni ilẹ ati nibi oke ti Allah fi si ibẹ ati awọn odo ati awọn isẹlẹru ati awọn igi ati awọn irugbi ati awọn ẹranko.
وَفِيٓ أَنفُسِكُمۡۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ 21
Awọn amin lori agbara Allah wa ni ara yin -ẹyin eniyan- se ẹ ko ri i ni, ki ẹ le woye?!
وَفِي ٱلسَّمَآءِ رِزۡقُكُمۡ وَمَا تُوعَدُونَ 22
Arisiki yin ti aye ati ti ẹsin si wa ni sanmọ, ohun ti wọn ni adehun fun yin ni rere ati aburu naa si wa nibẹ.
فَوَرَبِّ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ إِنَّهُۥ لَحَقّٞ مِّثۡلَ مَآ أَنَّكُمۡ تَنطِقُونَ 23
Mo fi Ọlọhun sanmọ ati ilẹ bura dajudaju ajinde jẹ ododo ti ko si iyemeji nibẹ gẹgẹ bi o se jẹpe ko si iyemeji nibi isọrọ yin nigbati ẹ nsọrọ.
هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ضَيۡفِ إِبۡرَٰهِيمَ ٱلۡمُكۡرَمِينَ 24
Njẹ o wa ba ọ - irẹ ojisẹ - ọrọ nipa awọn alejo Ibrahim ninu awọn Malaika eyiti o se apọnle wọn?
إِذۡ دَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَقَالُواْ سَلَٰمٗاۖ قَالَ سَلَٰمٞ قَوۡمٞ مُّنكَرُونَ 25
Nigbati wọn wọle tii, wọn si sọ fun: alaafia, Ibrahim sọ ni ẹniti o nda ọrọ pada si wọn: alaafia, o si tun sọ ninu ẹmin rẹ: awọn wọnyi jẹ ijọ ti a ko mọ.
فَرَاغَ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ فَجَآءَ بِعِجۡلٖ سَمِينٖ 26
O si sẹri si ọdọ awọn eniyan rẹ ni kọkọ, o si mu ẹran ti wọn ti yan tan wa ni ọdọ wọn; ni ero lọdọ rẹ wipe abara ni wọn.
فَقَرَّبَهُۥٓ إِلَيۡهِمۡ قَالَ أَلَا تَأۡكُلُونَ 27
O si sun ẹran naa mọ wọn, o wa ba wọn sọrọ pẹlẹ: se ẹ ko nii jẹ ohun ti wọn ti siwaju yin lounjẹ?
فَأَوۡجَسَ مِنۡهُمۡ خِيفَةٗۖ قَالُواْ لَا تَخَفۡۖ وَبَشَّرُوهُ بِغُلَٰمٍ عَلِيمٖ 28
Nigbati wọn ko jẹun, o fi ipaya sinu lati ara wọn, wọn wa mọ, wọn si sọ ni ẹniti nfi i lọkan balẹ: mase paya, dajudaju awa jẹ awọn ojisẹ lati ọdọ Allah, wọn si fun un niro ohun ti yoo dun un ninu wipe wọn yoo bimọ kunrin fun un, ti yoo nimọ pupọ, ẹniti wọn fun niro rẹ yii si ni ishaaq ẹniti ọla nbẹ fun
فَأَقۡبَلَتِ ٱمۡرَأَتُهُۥ فِي صَرَّةٖ فَصَكَّتۡ وَجۡهَهَا وَقَالَتۡ عَجُوزٌ عَقِيمٞ 29
Nigbati iyawo rẹ gbọ iro idunnu yii, o bẹrẹ sini pariwo ayọ, o si gba ara rẹ loju, o wa sọrọ ni ẹniti o se eemọ: se arugbo le bimọ ni, ti o si ti jẹ agan nipilẹ?
قَالُواْ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡعَلِيمُ 30
Awọn malaika sọ fun pe: ohun ti a fun ọ niro rẹ yii jẹ ohun ti Ọlọhun Ọba rẹ sọ, ohun ti O ba si sọ ko si adapada fun un, dajudaju O jẹ ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ, Onimimọ nipa ẹda Rẹ ati ohun ti o le se wọn ni anfaani.
Sise daradara ati sise afọmọ rẹ fun Allah jẹ okunfa wiwọ ọgba idẹra naa.
Ọla ti o nbẹ fun didide loru ati wipe dajudaju o wa ninu eyiti o lọla ju ninu isunmọ.
Ninu awọn ẹkọ isalejo: ni dida ikini pada ni ọna ti o dara ju u lọ ati pipatẹ tabili ni kọkọ ati mimura silẹ fun alejo siwaju dide rẹ ati mima se ẹsa ohunkihun ninu tabili ati mimojuto pipese rẹ ati yiyara nibẹ ati sisunmọ awọn alejo ati biba wọn sọrọ pẹlẹ.