لِّلرِّجَالِ نَصِيبٞ مِّمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٞ مِّمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَ مِمَّا قَلَّ مِنۡهُ أَوۡ كَثُرَۚ نَصِيبٗا مَّفۡرُوضٗا 7
Nbẹ fun awọn ọkunrin ipin ninu ohun nti awọn obi mejeeji ba fi silẹ, ati awọn alasunmọ gẹgẹ bi awọn iya, ati awọn aburo tabi ẹgbọn baba l’ọkunrin lẹyin iku wọn, o kere ni tabi o pọ, ati wipe o nbẹ fun awọn obirin ipin kan ninu ohun ti awọn wọnyi fi silẹ, ni iyatọ si ohun ti o wa lori rẹ nibi alamọri igba aimọkan, nibi kikọ fun awọn obirin ati awọn ọmọde ninu ogun, ipin yii, ẹtọ kan ni, ti wọn ti salaye odiwọn rẹ, ti o si jẹ ohun ti a se ni ọranyan lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) .
وَإِذَا حَضَرَ ٱلۡقِسۡمَةَ أُوْلُواْ ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينُ فَٱرۡزُقُوهُم مِّنۡهُ وَقُولُواْ لَهُمۡ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗا 8
Ati wipe ti awọn ti ko nii jẹ ogun ninu awọn alasunmọ ati awọn ọmọ orukan ati awọn olosi ba wa si ibi pipin ogun, ki ẹ ya fun wọn - ni ojupọnna fifẹ - ninu dukia yii siwaju pipin rẹ, eyiti o ba dun ma ẹmin yin ninu, toripe awọn jẹ ẹniti o njẹran rẹ, ati wipe paapaa o ti wa ba yin laise yahala, ati wipe ki ẹ sọ gbolohun ti o dara, ti ko si eebu nibẹ fun wọn.
وَلۡيَخۡشَ ٱلَّذِينَ لَوۡ تَرَكُواْ مِنۡ خَلۡفِهِمۡ ذُرِّيَّةٗ ضِعَٰفًا خَافُواْ عَلَيۡهِمۡ فَلۡيَتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلۡيَقُولُواْ قَوۡلٗا سَدِيدًا 9
Ati wipe ki wọn yaa bẹru awọn ti wọn ba ku, ti wọn si fi awọn ọmọ kekere ti o lẹ si ẹyin wọn, ti wọn npaya ki wọn ma rare, ki wọn yaa paya Ọlọhun Ọba Allah nibi awọn ti wọn nbẹ ni abẹ amojuto wọn ninu awọn ọmọ orukan, pẹlu gbigbe sise abosi si wọn ju silẹ, titi ti Ọlọhun Ọba Allah yoo fi se ni irọrun lẹyin iku wọn ẹniti yoo maa se daadaa si awọn ọmọ wọn, gẹgẹ bi awọn naa se se daadaa, ati wipe ki wọn ya se daadaa nibi ẹtọ awọn ọmọ ẹniti wọn wa si ibi asọtẹlẹ, pẹlu wipe ki wọn sọ gbolohun ti yoo se deedee ododo fun wọn, pẹlu pe ki wọn mọ se abosi nibi asọtẹlẹ rẹ ẹtọ ẹniti yoo jẹ ogun rẹ lẹyin rẹ, ati ki o ma se oore ni eewọ fun ẹmin ara rẹ pẹlu gbigbe asọtẹlẹ ju silẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَأۡكُلُونَ أَمۡوَٰلَ ٱلۡيَتَٰمَىٰ ظُلۡمًا إِنَّمَا يَأۡكُلُونَ فِي بُطُونِهِمۡ نَارٗاۖ وَسَيَصۡلَوۡنَ سَعِيرٗا 10
Dajudaju awọn ti wọn nmu awọn dukia awọn ọmọ orukan, ti wọn si ndari rẹ bi o se wu wọn nibi abosi ati ọta, dajudaju ohun ti wọn njẹ si inu awọn agbẹdun wọn ni ina kan, ti yoo maa jo laolao le wọn lori, ati wipe ina yoo pada jo wọn ni Ọjọ Igbende.
يُوصِيكُمُ ٱللَّهُ فِيٓ أَوۡلَٰدِكُمۡۖ لِلذَّكَرِ مِثۡلُ حَظِّ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۚ فَإِن كُنَّ نِسَآءٗ فَوۡقَ ٱثۡنَتَيۡنِ فَلَهُنَّ ثُلُثَا مَا تَرَكَۖ وَإِن كَانَتۡ وَٰحِدَةٗ فَلَهَا ٱلنِّصۡفُۚ وَلِأَبَوَيۡهِ لِكُلِّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا ٱلسُّدُسُ مِمَّا تَرَكَ إِن كَانَ لَهُۥ وَلَدٞۚ فَإِن لَّمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلَدٞ وَوَرِثَهُۥٓ أَبَوَاهُ فَلِأُمِّهِ ٱلثُّلُثُۚ فَإِن كَانَ لَهُۥٓ إِخۡوَةٞ فَلِأُمِّهِ ٱلسُّدُسُۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصِي بِهَآ أَوۡ دَيۡنٍۗ ءَابَآؤُكُمۡ وَأَبۡنَآؤُكُمۡ لَا تَدۡرُونَ أَيُّهُمۡ أَقۡرَبُ لَكُمۡ نَفۡعٗاۚ فَرِيضَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا 11
Ọlọhun Ọba ngbe adehun si ọdọ yin, O si tun npayin lasẹ nibi alamọri ogun awọn ọmọ yin; pe dajudaju ogun naa, wọn yoo pin laarin wọn, yoo maa bẹ fun ọmọkunrin iru ipin awọn obirin meji, ti oku ba wa fi awọn ọmọbirin silẹ laini ọmọkunrin, yoo maa bẹ fun obirin meji tabi ju bẹẹ lọ idameji ninu idamẹta ogun ninu ohun ti o fi silẹ, ati wipe ti o ba waa jẹ obirin ẹyọkan, yoo maa jẹ tirẹ ilaji ohun ti o fi silẹ, ati wipe yoo maa bẹ fun ikọọkan ninu awọn obi oku mejeeji, ida kan ninu idamẹfa ohun ti o fi silẹ; ti o ba jẹ wipe ọmọ nbẹ fun un, ọkunrin ni o jẹ ni tabi obirin, ati wipe ti ko ba si ọmọ fun un, ko si ẹniti yoo jẹ ogun rẹ ju awọn obi mejeeji lọ; yoo maa jẹ ti iya, ida kan ninu idamẹta, ati wipe eyiti o ba ku ninu ogun yoo maa jẹ ti baba rẹ, ati wipe ti o ba nbẹ fun oku awọn ọmọ iya tabi ju bẹẹ lọ, awọn ọkunrin ni wọn jẹ tabi awọn obirin, ọmọ iya ọmọ baba ni wọn jẹ tabi wọn kii se ọmọ iya ọmọ baba, yoo maa bẹ fun iya rẹ ida kan ninu idamẹfa ogun ni ọranyan, ati wipe eyiti o ba ku, yoo maa bẹ fun baba ni kiku ogun nilẹ, ko si nii si nkankan fun awọn iya naa, ati wipe yii fun ogun yoo maa waye lẹyin mimu asọtẹlẹ eyiti oku sọ silẹ sẹ, pẹlu majẹmu ki asọtẹlẹ maa kọja idamẹta dukia rẹ, ati pẹlu majẹmu sisan gbese eyiti o wa lọrun rẹ, ati wipe paapaa Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ti se pipin ogun lori eleyi; toripe dajudaju ẹyin ko mọ taani ninu awọn baba ati awọn ọmọ ni o sun mọ yin ju niti anfaani ni ile aye ati ni ọrun, toripe o seese ki oku maa lero daadaa si ọkan ninu awọn ti yoo jogun rẹ, ti yoo waa lọ fun ni gbogbo dukia, tabi ki o lero aburu pẹlu rẹ, ti yoo si se leewọ fun un, ati wipe o seese ki isesi yatọ si nkan naa, ati wipe ẹniti o mọ gbogbo nkan naa, Oun ni Ọlọhun Ọba Allah eyiti nkankan kii si pamọ fun Un; ati wipe tori idi eleyi ni O fi pin ogun naa lori ohun ti O se alaye, O si se ni ọranyan ti o jẹ dandan lori awọn ẹrusin Rẹ lati ọdọ Rẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ Onimimọ, ti nkankan ko le pamọ fun Un, ninu awọn ohun ti yoo jẹ anfaani fun awọn eniyan, Ọjọgbọn si ni nibi ofin Rẹ ati idari Rẹ.
Awọn idajọ awọn ogun tọka lori pe dajudaju ofin Ṣẹria, fun awọn ọkunrin ati awọn obirin ni awọn ẹtọ wọn, ni ẹniti o nsọ deedee laarin wọn, ati sise afieinlẹ ohun ti yoo jẹ oore laarin wọn.
Ilekoko ti o le nibi jijẹ eewọ awọn dukia awọn ọmọ orukan, ati kikọ ikọja aaye lori rẹ, ati rira lare lori ojupọnna ti o ri ki o jẹ.
Nigbati o jẹ wipe owo ninu awọn okunfa ifanfa ti o pọ ni laarin nawọn eniyan, ni Ọlọhun Ọba Allah fun ara Rẹ fi pin in, nibi awọn idajọ awọn ogun.