وَتَحۡمِلُ أَثۡقَالَكُمۡ إِلَىٰ بَلَدٖ لَّمۡ تَكُونُواْ بَٰلِغِيهِ إِلَّا بِشِقِّ ٱلۡأَنفُسِۚ إِنَّ رَبَّكُمۡ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ 7
Awọn ẹranko yii ti a da nba yin gbe awọn ẹru yin ti o wuwo nibi irin ajo yin lọsi awọn ilu eyiti ẹ ko lee de ayaafi pẹlu idaamu ti o wuwo lori ẹmin, dajudaju ỌLọhun Ọba yin - ẹyin eniyan - jẹ alaanu ati onikẹ si yin nitori rirọ awọn ẹranko fun yin.
وَٱلۡخَيۡلَ وَٱلۡبِغَالَ وَٱلۡحَمِيرَ لِتَرۡكَبُوهَا وَزِينَةٗۚ وَيَخۡلُقُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ 8
Ọlọhun Ọba Allah tun da ẹsin ati ibaaka pẹlu kẹtẹkẹtẹ ki ẹ le baa maa gun, ki ẹ si tun le maa gbe awọn ẹru yin le lori ati ki o le baa jẹ ọsọ fun yin, O si tun da nkan ti ẹ ko mọ ninu ohun ti o gbero dida rẹ.
وَعَلَى ٱللَّهِ قَصۡدُ ٱلسَّبِيلِ وَمِنۡهَا جَآئِرٞۚ وَلَوۡ شَآءَ لَهَدَىٰكُمۡ أَجۡمَعِينَ 9
O jẹ dandan fun Allah ki O se alaye oju ọna ti o tọ eyiti o le muni lọ si ibi iyọnu Rẹ, ohun naa si ni Islam, kuro nibi awọn oju ọna esu ti o le muni yẹ kuro nibi ododo, gbogbo oju ọna ti o yatọ si oju ọna Islam ni eyiti o ti yẹ kuro, ti Ọlọhunn Ọba Allah ba fẹ lati fi yin mọ ọna ni apapọ si igbagbọ, ki ba fi yin se kongẹ lapapọ.
هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗۖ لَّكُم مِّنۡهُ شَرَابٞ وَمِنۡهُ شَجَرٞ فِيهِ تُسِيمُونَ 10
Oun ti mimọ nbẹ fun ni Ẹniti O nsọ omin ninu ẹsu ojo eyiti ẹ nmu wa ninu omin ati eyiti ẹ nfun awọn ẹranko yin mu, bẹẹ ni eyiti awọn irungbin igi yin na nmu eyiti awọn ẹranko yin njẹ koriko rẹ.
يُنۢبِتُ لَكُم بِهِ ٱلزَّرۡعَ وَٱلزَّيۡتُونَ وَٱلنَّخِيلَ وَٱلۡأَعۡنَٰبَ وَمِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ 11
Ọlọhun Ọba Allah ti ibi omin naa nmu nkan ọgbin jade fun yin eyiti ẹ njẹ, O si nmu zaytun ati ọpẹ ati awọn eso inabi jade fun yin, bẹẹ ni O tun mu ọpọlọpọ awọn eso naa jade fun yin, dajudaju nibi omin yii ati ohun ti o njade lati ara rẹ jẹ itọka lori agbara Allah fun awọn ijọ ti o nronu nipa ẹda Rẹ, ti wọn yoo fi maa se ẹri lori titobi mimọ Rẹ.
وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ وَٱلنُّجُومُ مُسَخَّرَٰتُۢ بِأَمۡرِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ 12
Ọlọhun Ọba Allah tun rọ oru fun yin ki ẹ le maa gbe ninu rẹ, ki ẹ si tun maa sin min, ati ọsan ki ẹ le maa ko ohun ti ẹyin yoo maa fi sẹmin jẹ, O si tun rọ oorun fun yin, O si se ni itansan, ati osupa, O si se ni imọlẹ ati irawọ jẹ ohun ti A rọ fun yin lati ibi asọ agbara Rẹ, ohun ni ẹ fi nmọ ọna nibi awọn okunkun ori ilẹ ati ori omin, ẹ si tun fi nmọ awọn asiko ati ohun ti o yatọ si i, dajudaju nibi rirọ eleyi lapapọ fun jẹ awọn itọka ti o fi oju han lori agbara Ọlọhun Ọba Allah fun awọn ijọ ti wọn nlo laakaye wọn, awọn yii ni yoo ri ọgbọn mu ninu rẹ.
وَمَا ذَرَأَ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهُۥٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَذَّكَّرُونَ 13
Oun ti mimọ nbẹ fun tun rọ ohun ti o da fun yin ni ilẹ ninu nkan ti awọ rẹ yatọ si ara wọn, ninu awọn nkan alumọọni ati ẹranko ati awọn eso ati awọn irugbin, dajudaju nibi eleyi ti a sọ ninu awọn ẹda ati rirọ ọ jẹ itọka ti o gbọngbọn lori agbara Allah ti mimọ nbẹ fun, fun awọn ijọ ti o nwoye pẹlu Rẹ, ti wọn si nmọ wipe dajudaju Allah jẹ alagbara oluse idẹkun.
وَهُوَ ٱلَّذِي سَخَّرَ ٱلۡبَحۡرَ لِتَأۡكُلُواْ مِنۡهُ لَحۡمٗا طَرِيّٗا وَتَسۡتَخۡرِجُواْ مِنۡهُ حِلۡيَةٗ تَلۡبَسُونَهَاۖ وَتَرَى ٱلۡفُلۡكَ مَوَاخِرَ فِيهِ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 14
Oun ti mimọ nbẹ fun ni Ẹniti o rẹ odo fun yin, O se gigun rẹ ni irọrun fun yin ati mimu ohun ti o wa inu rẹ jade; ki ẹ le maa jẹ ninu ohun ti ẹ ba dẹdẹ l’ẹja, ekiri ti o ndan, ti o si lẹ, ti si tun nmu ọsọ jade eyiti ẹ nwọ, ti ẹ si tun nfun awọn obinrin wọ gẹgẹ bi aluuluu, iwọ yoo ri awọn ọkọ oju omin ti wọn nda odo lamun, ẹ si ngun awọn ọkọ oju omin yii lati wa ọla Allah eyiti ma njade lati ibi ere owo sise, ati lati le maa rankan dida ọpẹ fun Allah lori idẹkun ti o se fun yin, ki ẹ si le baa mu U lọkan nibi ijọsin.
Ninu titobi Allah ni ki O da ohun ti ọpọlọpọ abara ko mọ, ni gbogbo asiko ti mimọ Rẹ ba ti gbero.
Allah da irawọ ki o le jẹ ọsọ fun sanmọ ati imọna nibi okunkun ori ilẹ ati ori omin ati mimọ awọn asiko ati isiro awọn igba.
Ẹyin ati ọpẹ fun Allah eyiti O se idẹkun le wa lori pẹlu ohun ti yoo se anfaani fun isẹmin aye wa, ti yoo si kun wa lọwọ lori eyiti o lọla ju lori isẹmin.
Allah ti mimọ nbẹ fun se idẹkun fun wa pẹlu rirọ odo ki a le maa ri awọn ekiri (awọn ẹja) ati lati le maa mu awọn aluuluu ati marijaanu ati ki o le baa jẹ nkan igun ati okowo ati ounti o yatọ si ninu awọn daada ati awọn anfaani