كَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ كَانُوٓاْ أَشَدَّ مِنكُمۡ قُوَّةٗ وَأَكۡثَرَ أَمۡوَٰلٗا وَأَوۡلَٰدٗا فَٱسۡتَمۡتَعُواْ بِخَلَٰقِهِمۡ فَٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِخَلَٰقِكُمۡ كَمَا ٱسۡتَمۡتَعَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُم بِخَلَٰقِهِمۡ وَخُضۡتُمۡ كَٱلَّذِي خَاضُوٓاْۚ أُوْلَٰٓئِكَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 69
Ẹyin - akojọpọ sọbẹselu - wa ninu keferi ati yẹyẹ sise gẹgẹ bi awọn ijọ opurọ ti o siwaju yin, wọn jẹ ẹniti o lagbara ju yin lọ, wọn si ni dukia ati awọn ọmọ ti o pọ, ẹ maa fi ara da ẹsan ti a kọ silẹ fun wọn ninu awọn adun aye ati yodo yindin rẹ, ẹyin a maa gbadun rẹ - ẹyin sọbẹ selu - pẹlu ipin yin ti a se ni odiwọn fun yin ninu rẹ gẹgẹ bi agbadun awọn ijọ opurọ ti siwaju pẹlu ipin wọn, ẹ si ti wọ inu pipe ootọ nirọ ati fifi ẹnu agan kan awọn ojisẹ wọn gẹgẹ bi ẹ se wọ inu pipe e nirọ ati fifi ẹnu agan kan awọn ojisẹ wọn, awọn wọnyi ni a royin pẹlu iroyin yẹpẹrẹ yii, awọn ni ẹniti isẹ wọn ti bajẹ nitori aidara rẹ lati ara keferi, awọn ni olusofo ti sofo ẹmin ara wọn nitori mimu lọ sibi iparun.
أَلَمۡ يَأۡتِهِمۡ نَبَأُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ قَوۡمِ نُوحٖ وَعَادٖ وَثَمُودَ وَقَوۡمِ إِبۡرَٰهِيمَ وَأَصۡحَٰبِ مَدۡيَنَ وَٱلۡمُؤۡتَفِكَٰتِۚ أَتَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِۖ فَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظۡلِمَهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ 70
Se iro ko ba awọn sọbẹ selu wọnyi ni, ohun ti awọn ijọ opurọ naa se ati iya ti wọn fi jẹ wọn: ijọ Nuha ati ijọ Huud ati ijọ Sọọlihu ati ijọ Ibraheem ati awọn ara ile madiyana ati awọn abule ijọ Luutu; awọn ojisẹ wọn mu awọn awijare ti o han ati awọn ẹri ti o gbọngbọn wa fun ọ, Ọlọhun Ọba Allah kii se ẹniti yoo se abosi si wọn; awọn ojisẹ wọn ti se ikilọ fun wọn sugbọn wọn se abosi ara wọn nitori keferi ti wọn se si Ọlọhun Ọba Allah, ati pipe awọn ojisẹ Rẹ nirọ.
وَٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتُ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٖۚ يَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَيَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَيُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَيُطِيعُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓۚ أُوْلَٰٓئِكَ سَيَرۡحَمُهُمُ ٱللَّهُۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٞ 71
Awọn olugbagbọ ododo lọkunrin ati olugbagbọ ododo lobinrin apakan wọn jẹ alaranse fun apakan, ati awọn olukunlọwọ; lati ko igbagbọ jọ laarin wọn, wọn ma npasẹ daadaa; ohun ni gbogbo nkan ti Ọlọhun Ọba Allah ba nifẹ si ni ojupọnna titẹle asẹ Rẹ, gẹgẹ bi mimọ Ọlọhun Ọba lọkan ati irun kiki, wọn kọ kuro nibi ohun ti ko tọ; ohun ti gbogbo nkan ti o ba nbi Ọlọhun Ọba ninu, bi awọn ẹsẹ, sise keferi ati riba, wọn nkirun ni pipe ni ojupọnna ti o tọ, wọn ntẹle asẹ Allah, wọn si ntẹle ojisẹ Rẹ; awọn ni ẹniti a nfi awọn iroyin ẹyin yii royin, Ọlọhun Ọba Allah yoo fi wọn sinu ikẹ Rẹ, dajudaju Allah jẹ alagbara nkankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi dida ẹda Rẹ, idari Rẹ ati ofin Rẹ.
وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا وَمَسَٰكِنَ طَيِّبَةٗ فِي جَنَّٰتِ عَدۡنٖۚ وَرِضۡوَٰنٞ مِّنَ ٱللَّهِ أَكۡبَرُۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 72
Ọlọhun Ọba Allah se adehun fun awọn olugbagbọ ododo ninu Ọlọhun ati awọn olugbagbọ ododo obinrin naa pe Oun yoo fi wọn wọ inu ọgba onidẹra ti akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ ni ọjọ igbende, yoo maa nibẹ lọ gbere, wọn ko nii ku nibẹ, bẹẹ nii idẹkun wọn ko nii tan, o si tun se adehun fun wọn lati fi wọn wọ awọn aaye ti o dara ni inu alujannah, bi ibugbe ati iyọnu ti Ọlọhun Ọba yoo se lẹtọ fun wọn, jẹ ohun ti o tobi ju gbogbo eleyi lọ, ẹsan ti a darukọ yii ni erenjẹ ti o tobi eyiti erenjẹ kankan ko sun mọ.
Okunfa iya awọn keferi ati awọn sọbẹ selu jẹ ẹyọkan ni gbogbo asiko, ohun ni gbigbe ọla fun aye lori ọrun ati gbigbadun rẹ, ati pipoe awọn anọbi nirọ, ati ete ati itanjẹ ati idalẹ si wọn.
Pipa awọn ijọ ati awọn eniyan ti wọn ti re kọja lọ jẹ okunfa keferi wọn ati pipe awọn anọbi wọn nirọ, isiti ati ariwoye wa nibẹ fun ẹniti o ba loye ninu awọn onilaakaye.
Awọn ti wọn nigbagbọ lọkunrin ati lobinrin jẹ ijọ kan soso, ti wọn so papọ mọ ara wọn, ti wọn si nkun ara wọn lọwọ, ti wọn si nse aranse fun ara wọn, awọn ọkan wọn sọkan nibi ifẹ ati sise aanu ara wọn.
Iyọnu ẹniti o ni ilẹ ati sanmọ tobi ju idẹkun alujannah lọ; nitori wipe oriire imisi lọla ju abara lọ.