وَمَا عَلَى ٱلَّذِينَ يَتَّقُونَ مِنۡ حِسَابِهِم مِّن شَيۡءٖ وَلَٰكِن ذِكۡرَىٰ لَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ 69
Isiro awọn alabosi yii, ko si lọrun awọn ti wọn paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle asẹ Rẹ, ti wọn si jinna si ohun ti O kọ, ohun ti o jẹ dandan fun wọn ni ki wọn kọ fun wọn kuro nibi ohun ti ko tọ, boya wọn yoo paya Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn yoo si tẹle awọn asẹ Rẹ, ti wọn yoo si tun jinna si ohun ti o kọ.
وَذَرِ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ دِينَهُمۡ لَعِبٗا وَلَهۡوٗا وَغَرَّتۡهُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَاۚ وَذَكِّرۡ بِهِۦٓ أَن تُبۡسَلَ نَفۡسُۢ بِمَا كَسَبَتۡ لَيۡسَ لَهَا مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٞ وَلَا شَفِيعٞ وَإِن تَعۡدِلۡ كُلَّ عَدۡلٖ لَّا يُؤۡخَذۡ مِنۡهَآۗ أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ أُبۡسِلُواْ بِمَا كَسَبُواْۖ لَهُمۡ شَرَابٞ مِّنۡ حَمِيمٖ وَعَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ 70
Gbe - irẹ ojisẹ - awọn ọsẹbọ ti wọn nyi ẹsin wọn si ere ọmọde ati ere agba, ti wọn si fi nse yẹyẹ ati awada ju silẹ, ti isẹmi aye ti tan wọn jẹ pẹlu adun bẹ ti yoo yẹ, se waasi - irẹ Anọbi - fun awọn eniyan pẹlu Alukuraani, titi ẹmin kankan ko fi nii le dari sibi iparun nitori asise ti o ti se, ko si alaanu kankan yatọ si Allah ti o le ran an se, ko si si alẹgun kan ti o le kọ iya Ọlọhun Ọba Allah kuro fun wọn ni ọjọ igbende, ti o ba wa isọ kuro nibi iya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu eyikeyi isura, wọn ko nii gba lọwọ rẹ, awọn wọnyi ni wọn nju ara wọn si inu iparun fun ara wọn nitori ẹsẹ ti wọn da, nkan gbigbona tan yan-an yan nbẹ fun wọn ni ọjọ igbende, ati iya onitara nitori keferi wọn.
قُلۡ أَنَدۡعُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُنَا وَلَا يَضُرُّنَا وَنُرَدُّ عَلَىٰٓ أَعۡقَابِنَا بَعۡدَ إِذۡ هَدَىٰنَا ٱللَّهُ كَٱلَّذِي ٱسۡتَهۡوَتۡهُ ٱلشَّيَٰطِينُ فِي ٱلۡأَرۡضِ حَيۡرَانَ لَهُۥٓ أَصۡحَٰبٞ يَدۡعُونَهُۥٓ إِلَى ٱلۡهُدَى ٱئۡتِنَاۗ قُلۡ إِنَّ هُدَى ٱللَّهِ هُوَ ٱلۡهُدَىٰۖ وَأُمِرۡنَا لِنُسۡلِمَ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 71
Sọ - ire ojise - fun awọn ọlọsẹbọ wọnyi: se awa yoo maa sin oosa yatọ si Ọlọhun Ọba Allah, ti ko lee se anfaani tabi ko inira ba wa, ti a o waa gunri kuro nibi igbagbọ lẹyin ti Ọlọhun Ọba Allah ti fi wa se kongẹ, ti awa yoo wa da gẹgẹ bi ẹniti eesu ti sọnu, ti o wa gbe ju silẹ ninu idaamu, ti ko le mọna rara, bẹẹni o si ni awọn eniyan ni oju ọna ti o tọ, ti wọn npe lọ si ibi ododo, ti o si nkọ lati jẹ ipe wọn lọ si ibi ti wọn npe si? Sọ fun wọn - ire ojise -: ọna ti Ọlọhun Ọba Allah ni ọna ti ododo, Ọlọhun Ọba Allah si ti pa wa lasẹ wipe ki a tẹriba fun Un pẹlu ki a dunnimọ mimu lọkan soso ati ijọsin fun Oun nikan soso, Oun ni olutọju gbogbo agbanla aye.
وَأَنۡ أَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَٱتَّقُوهُۚ وَهُوَ ٱلَّذِيٓ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ 72
O ti pawa lasẹ wipe ki a maa gberun duro ni oju ọna ti o pe, O si pawa lasẹ ki a paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mima tẹle asẹ Rẹ ati jijinna si ohun ti O kọ, Oun nikan ni Yoo ko gbogbo ẹru ni ọdọ Rẹ ni ọjọ igbende, ki O le san wọn lẹsan lori awọn isẹ wọn.
وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۖ وَيَوۡمَ يَقُولُ كُن فَيَكُونُۚ قَوۡلُهُ ٱلۡحَقُّۚ وَلَهُ ٱلۡمُلۡكُ يَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِۚ عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡخَبِيرُ 73
Oun ti mimọ nbẹ fun ni O da sanmọ ati ilẹ pẹlu ododo, ni ọjọ ti Ọlọhun Ọba Allah yoo sọ fun gbogbo nkan wipe: jẹ bẹẹ, ki o si maa ri bẹẹ, nigbati O ba nsọ ni ọjọ igbende wipe: ẹ dide, wọn yoo si maa dide, ọrọ Rẹ ni ododo eyiti yoo sẹlẹ, ko si iyemeji nibẹ, oun nikan ni O ni ọla ni ọjọ igbende, nigbati Isirọfiilu ba fatẹgun si inu iwo ni ifatẹgun ẹlẹẹkeji, O nimọ nipa ohun ti o ti re kọja, O si nimọ nipa nkan ti wọn nri bayi, Oun ni ọjọgbọn nibi dida Rẹ ati idari Rẹ, Oun ni oloye eyiti nkankan ko pamọ fun, inu gbogbo alamọri ọrọ dabi ode rẹ naa ni.
Olupepe si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga kii se ẹniti a o bi leere nipa isiro isẹ ẹnikẹni, sugbọn wọn yoo bi leere nipa imọrọ de ogongo ati sise iranti.
Isiti sise jẹ ọkan ninu awọn ọna ti o tobi ju lati ta awọn afọnu-fọra onigberaga ji.
Ninu awọn ẹri mimọ Ọlọhun Ọba lọkan: ni wipe ẹniti ko ni ikapa anfaani tabi inira tabi se bi o se wu u, ko lẹtọ ni eyikeyi ọna lati Ọlọhun Ọba ti a o maa sin.