أُبَلِّغُكُمۡ رِسَٰلَٰتِ رَبِّي وَأَنَا۠ لَكُمۡ نَاصِحٌ أَمِينٌ 68
Maa fi de etigbọ yin ninu ohun ti Ọlọhun Ọba mi pa mi lasẹ ninu ijọkan soso Rẹ ati ofin Rẹ, mo si jẹ oluse isiti nibi ohun ti Ọlọhun Ọba pa mi lasẹ ati ẹni ifọkan tan, emi ko nii se alekun nibẹ, nko si nii se adinku.
أَوَعَجِبۡتُمۡ أَن جَآءَكُمۡ ذِكۡرٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَلَىٰ رَجُلٖ مِّنكُمۡ لِيُنذِرَكُمۡۚ وَٱذۡكُرُوٓاْ إِذۡ جَعَلَكُمۡ خُلَفَآءَ مِنۢ بَعۡدِ قَوۡمِ نُوحٖ وَزَادَكُمۡ فِي ٱلۡخَلۡقِ بَصۜۡطَةٗۖ فَٱذۡكُرُوٓاْ ءَالَآءَ ٱللَّهِ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ 69
Se eemọ yin ati sise ajoji yin lapa lori wipe iranti wa ba yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba yin lori ahọn okunrin kan ninu iran yin, ti kii se ninu iran awọn Malaika tabi Alujannu lati se ikilọ fun yin? ! ẹ yin Ọlọhun Ọba yin, ki ẹ si dupẹ fun Un, lori wipe o gba yin laaye lori ilẹ, o si se yin ni arole fun ijọ Nuha eyiti Ọlọhun Ọba Allah ti parun nitori keferi wọn, ki ẹ tun dupẹ fun Ọlọhun Ọba Allah lori wipe o se yin ni alara titobi ati alagbara ati igbamun ti o le, ẹ ranti ikẹ Ọlọhun Ọba Allah ti o gbaaye leyin lori ki ẹ le ba jere pẹlu oun ti ẹ nbeere fun, ki ẹ si le la kuro nibi oun ti ndẹru ba yin.
قَالُوٓاْ أَجِئۡتَنَا لِنَعۡبُدَ ٱللَّهَ وَحۡدَهُۥ وَنَذَرَ مَا كَانَ يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَا فَأۡتِنَا بِمَا تَعِدُنَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 70
Awọn ijọ rẹ sọ fun wipe: se o waa ba wa ni - irẹ Huud - lati pawa lasẹ ki a sin Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, ki a si tun gbe ohun ti awọn baba wa nsin ju silẹ? ! Ki o yaa mu wa iya ti o se adehun rẹ fun wa ti o ba se wipe olootọ ni ọ lori nkan ti o npe ara rẹ.
قَالَ قَدۡ وَقَعَ عَلَيۡكُم مِّن رَّبِّكُمۡ رِجۡسٞ وَغَضَبٌۖ أَتُجَٰدِلُونَنِي فِيٓ أَسۡمَآءٖ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّا نَزَّلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٖۚ فَٱنتَظِرُوٓاْ إِنِّي مَعَكُم مِّنَ ٱلۡمُنتَظِرِينَ 71
Huud fesi fun wọn ni ẹniti nsọ bayi wipe: ẹ ti se iya Ọlọhun Ọba ni dandan le ra yin lori ati ibinu Rẹ, yoo sọkalẹ fun yin ko si iyemeji nibẹ, se ẹyin yoo maa ba mi jiyin ni nibi awọn oosa ti ẹ fun ni orukọ ẹyin ati awọn baba yin gẹgẹ bi ọlọhun, kii se ododo? ! Ọlọhun Ọba Allah ko sọ awijare kankan fun yin kalẹ ti ẹ le fi ẹri lori ohun ti ẹ nsin, ki ẹ yaa maa reti nkan ti ẹ beere fun ninu iya, emi naa wa ninu ẹniti o nba yin reti, yoo si sẹlẹ.
فَأَنجَيۡنَٰهُ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَقَطَعۡنَا دَابِرَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَاۖ وَمَا كَانُواْ مُؤۡمِنِينَ 72
A la Huud ati awọn olugbagbọ ododo ti wọn wa pẹlu rẹ lati ara ikẹ wa, a si se iparun fun awọn ti wọn pe awọn amin wa nirọ, wọn kii se olugbagbọ ododo, ohun ti wọn jẹ ni opurọ, wọn si lẹtọ si iya.
وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمۡ صَٰلِحٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ قَدۡ جَآءَتۡكُم بَيِّنَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡۖ هَٰذِهِۦ نَاقَةُ ٱللَّهِ لَكُمۡ ءَايَةٗۖ فَذَرُوهَا تَأۡكُلۡ فِيٓ أَرۡضِ ٱللَّهِۖ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوٓءٖ فَيَأۡخُذَكُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 73
Paapaa a ti ransẹ ọmọ iya wọn Sọọlihu si idile samudawa, ti o pe wọn sibi ọkan soso Ọlọhun Ọba Allah ati jijọsin fun Un, Sọlihu sọ fun wọn: ẹyin ijọ mi, ẹ maa sin Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, ko si ẹniti ẹ lẹtọ lati jọsin fun yatọ si I, amin ti o fi oju han ti waa ba yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba lori ododo nkan ti mo muwa ba yin eyiti o sẹlẹ lori rakunmi ti o jade ninu apata, o ni asiko ti o fi ma nmumi, ẹyin naa si ni asiko imumi yin ni ọjọ ti ẹ mọ, ki ẹ fi silẹ ki o maa jẹhun lori ilẹ Ọlọhun Ọba Allah, ẹ ko ni iranlọwọ kankan ti ẹ o se fun un, ẹ ko si gbọ dọ fi suta se e, ki iya onitara maa ba kan yin latara suta ti ẹ ba fi se e.
O lẹtọ ki eniyan ni iroyin suuru nibi ipepe si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah lati fi kọse awọn Anọbi Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
Ninu ọla ti nbẹ fun ipepe si oju ọna Ọlọhun, ohun ni ki eniyan maa pepe si oju ọna Ọlọhun Ọba nikan soso, ti ko si orogun fun Un, ki eeyan si tako ẹbọ sise pẹlu rẹ.
Mima gba itanjẹ pẹlu agbara owo ati agbara ti ara ma ngbe ẹniti o ni kuro nibi jijẹ ipe asẹ Ọlọhun Ọba Allah ati kikuro nibi ohun ti O kọ.
Anọbi ma nwa lati inu iran ijọ rẹ sugbọn ẹniti o ba niyi ju ninu mọlẹbi wọn ni o ma njẹ, ti idile wọn si lọla ju, ti ipasepọ rẹ si lapọnle ju, ti iwa rẹ tun dara ju.
Awọn Anọbi Ọlọhun Ọba ati awọn ti wọn jogun wọn ma nfi suuru pade awọn omugọ, wọn sii ki sọrọ aida, wọn ma nmọkan kuro, wọn si ma nse aforijin.