وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَصَعِقَ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا مَن شَآءَ ٱللَّهُۖ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخۡرَىٰ فَإِذَا هُمۡ قِيَامٞ يَنظُرُونَ 68
Ọjọ ti Malaaika ti a la fifan fere bọ lọrun yoo fan fere si inu iwo, gbogbo ẹniti ti o wa ni gbogbo sanmọ ati ẹniti o wa ni ilẹ yoo ku, ayaafi ẹniti Allah ko ba fẹ ki o ku, lẹyin naa Malaaika naa yoo tun fan fere fun ajinde, lojiji ni gbogbo alaaye yoo naro ti wọn yoo maa wo kini Allah yoo se fun wọn.
وَأَشۡرَقَتِ ٱلۡأَرۡضُ بِنُورِ رَبِّهَا وَوُضِعَ ٱلۡكِتَٰبُ وَجِاْيٓءَ بِٱلنَّبِيِّۧنَ وَٱلشُّهَدَآءِ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡحَقِّ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ 69
Nigbati Ọlọhun Abiyi ba jade lati dajọ larin awọn ẹru, imọlẹ yoo tan ka ori ilẹ, wọn yoo si fan iwe isẹ awọn eniyan ka, wọn yoo wa mu awọn anọbi wa, wọn yoo si tun mu ijọ Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun wa, ki o le jẹri fun awọn anọbi lori awọn ijọ wọn, Allah yoo si wa se idajọ laarin gbogbo wọn pẹlu deedee, wọn ko si ni se abosi ni ọjọ yii, wọn ko nii se alekun ọmọniyan, bẹẹni wọn ko nii din daadaa ku.
وَوُفِّيَتۡ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِمَا يَفۡعَلُونَ 70
Allah yoo si pe ẹsan gbogbo ẹmin, daadaa ni isẹ naa jẹ tabi aburu, Allah si nimọ nipa ohun ti wọn nse ju, rere ninu isẹ wọn tabi aburu rẹ kankan ko pamọ fun Un, yoo si san wọn lẹsan ni ọjọ yii lori awọn isẹ wọn.
وَسِيقَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِلَىٰ جَهَنَّمَ زُمَرًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا فُتِحَتۡ أَبۡوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمۡ خَزَنَتُهَآ أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ رُسُلٞ مِّنكُمۡ يَتۡلُونَ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتِ رَبِّكُمۡ وَيُنذِرُونَكُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَاۚ قَالُواْ بَلَىٰ وَلَٰكِنۡ حَقَّتۡ كَلِمَةُ ٱلۡعَذَابِ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ 71
Awọn Malaaika yoo dari awọn ti o se aimoore si Allah nijọ ni ẹni yẹpẹrẹ titi ti wọn yoo fi de inu ina jahannamọ, awọn Malaaika ti wọn la isẹ ibẹ bọ lọrun yoo si awọn ilẹkun rẹ fun wọn, wọn yoo si pade wọn pẹlu eebu ni ẹniti wọn yoo maa sọ fun wọn: kii wa sepe awọn ojisẹ ninu iran yin wa ba yin, ti wọn nka awọn aayah Ọlọhun Ọba yin fun yin ti o sọkalẹ fun wọn lori, ti wọn si nfi pipade ọjọ igbende dẹru ba yin; nitori iya ti o le koko ti o wa nibẹ?! Awọn ti wọn se keferi, ti wọn si nfi rinlẹ fun ẹmin ara wọn yoo sọpe: bẹẹni gbogbo eleyi ti sẹlẹ sugbọn gbolohun iya ti di dandan lori awọn keferi, awa si jẹ alaimoore.
قِيلَ ٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ 72
Wọn yoo sọ fun niti yiyẹrẹ wọn ati jijakan wọn kuro nibi ikẹ Allah ati kikuro kuro ninu ina: ẹ maa wọ awọn inu ọna jahannamọ ni ẹniti yoo maa gbe ibẹ lọ gbere, o buru, ko si dara, ibudesi awọm olusegberaga onimotomoto si ododo.
وَسِيقَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ رَبَّهُمۡ إِلَى ٱلۡجَنَّةِ زُمَرًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا وَفُتِحَتۡ أَبۡوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمۡ خَزَنَتُهَا سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡ طِبۡتُمۡ فَٱدۡخُلُوهَا خَٰلِدِينَ 73
Bẹẹni awọn Malaaika yoo maa dari awọn olugbagbọ ododo ti wọn paya Ọlọhun wọn pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si ohun ti o kọ lọ si inu ọgba idẹra pẹlu pẹlẹpẹlẹ nijọnijọ niti apọnle titi wọn yoo fi de inu ọgba idẹra naa, wọn yoo si awọn ilẹkun rẹ fun wọn, awọn Malaaika ti a la isẹ naa bọ lọrun yoo sọ fun wọn pe: alaafia ki o maa bẹ fun yin kuro nibi inira ati kuro nibi gbogbo ohun ti ẹ ko nifẹ si, ọkan yin ki o maa dun ati awọn isẹ yin, ẹ maa wọ inu ọgba idẹra ni ẹniti yoo ma gbebẹ gbere.
وَقَالُواْ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي صَدَقَنَا وَعۡدَهُۥ وَأَوۡرَثَنَا ٱلۡأَرۡضَ نَتَبَوَّأُ مِنَ ٱلۡجَنَّةِ حَيۡثُ نَشَآءُۖ فَنِعۡمَ أَجۡرُ ٱلۡعَٰمِلِينَ 74
Awọn olugbagbọ ododo yoo sọrọ nigbati wọn ba wọnu ọgba idẹra naa: ẹpẹ ni fun Allah eyiti O sọ adehun Rẹ di ododo fun wa, eyiti o se ni adehun lati ori awọn ojisẹ Rẹ fun wa, paapaa O se adehun fun wa lati fi wa wọ inu ọgba idẹra, O si jogun ilẹ ọgba idẹra fun wa, a nsọkalẹ si aaye ti a fẹ lati sọkalẹ si nibẹ, ẹsan olusisẹ awọn ti o se awọn isẹ rere lati wa oju rere Ọlọhun Ọba wọn ma dara gan an.
Ririnlẹ fifọn feere meji.
Sise alaye iyẹpẹrẹ eyiti awọn keferi yoo ba pade ati apọnle ti wọn yoo fi koju awọn olugbagbọ ododo.
Ririnlẹ gbere awọn keferi ninu ina jahiimu ati gbere awọn olugbagbọ ododo ninu idẹkun.
Isẹ didara ma njogun ẹsan to dara fun ni.