وَٱلَّذِينَ لَا يَدۡعُونَ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ وَلَا يَقۡتُلُونَ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَلَا يَزۡنُونَۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ يَلۡقَ أَثَامٗا 68
Awọn ti kii pe olujọsun fun miran mọ Allah ti mimọ nbẹ fun, wọn si kii pa ẹmin eyiti Allah se ni eewọ pipa rẹ ayaafi pẹlu iyọnda ti Allah se ni pipa olupaniyan tabi olugunri tabi baale olusagbere, wọn ko si gbọdọ se agbere, ẹniti o ba se awọn ẹsẹ nla yii, yoo ba ijiya ohun ti o se ninu ẹsẹ yii pade ni ọjọ igbende.
يُضَٰعَفۡ لَهُ ٱلۡعَذَابُ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَيَخۡلُدۡ فِيهِۦ مُهَانًا 69
Wọn yoo se adipele iya fun un ni ọjọ igbende, yoo si maa wa gbere ni ẹni ilẹ, ẹni yẹpẹrẹ nibi iya naa.
إِلَّا مَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ عَمَلٗا صَٰلِحٗا فَأُوْلَٰٓئِكَ يُبَدِّلُ ٱللَّهُ سَئَِّاتِهِمۡ حَسَنَٰتٖۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمٗا 70
Sugbọn ẹniti o ba ronu piwada si ọdọ Allah, ti o si nigbagbọ, ti o si nsisẹẹre eyiti o tọka si ironu piwada rẹ, iru awọn wọnyi Allah yoo yi aida ti wọn se pada si daadaa, bẹẹni Allah jẹ oluforijin ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, O si jẹ onikẹ si wọn.
وَمَن تَابَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَإِنَّهُۥ يَتُوبُ إِلَى ٱللَّهِ مَتَابٗا 71
Ẹniti o ba ronu pada si ọdọ Allah, ti o si fi isẹ itẹle dogo lori jijẹ ododo ironu piwada rẹ ati gbigbe awọn ẹsẹ ju silẹ, dajudaju ironu piwada rẹ yoo jẹ ironu piwada itẹwọgba.
وَٱلَّذِينَ لَا يَشۡهَدُونَ ٱلزُّورَ وَإِذَا مَرُّواْ بِٱللَّغۡوِ مَرُّواْ كِرَامٗا 72
Awọn ti kii wa nibi ibajẹ; gẹgẹ bi awọn aaye ẹsẹ ati awọn aaye ere eewọ, nigbati wọn ba si re kọja nibi ibajẹ gẹgẹ bi awọn ọrọ ati isẹ, wọn yoo re kọja nibẹ ni irekọja wọọrọ, ni ẹniti yoo se apọnle ẹmin ara wọn pẹlu fifọọmọ kuro nibi riro papọ mọ ọ.
وَٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُواْ بَِٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ لَمۡ يَخِرُّواْ عَلَيۡهَا صُمّٗا وَعُمۡيَانٗا 73
Awọn ti o ja si wipe ti wọn ba darukọ awọn amin Allah eyiti wọn gbọ tabi ti wọn ri, wọn ko nii di eti wọn kuro nibi awọn amin gbigbọ yii, wọn si ko nii diju kuro nibi awọn amin afojuri yii.
وَٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا هَبۡ لَنَا مِنۡ أَزۡوَٰجِنَا وَذُرِّيَّٰتِنَا قُرَّةَ أَعۡيُنٖ وَٱجۡعَلۡنَا لِلۡمُتَّقِينَ إِمَامًا 74
Awọn ti o nsọ nibi adua wọn si Ọlọhun Ọba wọn: Ọlọhun wa, fun wa ẹniti yoo jẹ itutu oju fun wa, ti yoo tun lagbara ati iduro sinsin lori ododo ninu iyawo wa ati awọn ọmọ wa, ki o si sọ wa di asiwaju nibi ododo ki a le di ẹniti awọn olupaya Ọlọhun yoo maa kọse.
أُوْلَٰٓئِكَ يُجۡزَوۡنَ ٱلۡغُرۡفَةَ بِمَا صَبَرُواْ وَيُلَقَّوۡنَ فِيهَا تَحِيَّةٗ وَسَلَٰمًا 75
Awọn ti a fi awọn iroyin yii royin, wọn yoo sẹ wọn ni ẹsan awọn yara ti o ga ninu Alufiridaosi ti o ga ninu ọgba idẹra nitori suuru wọn lori itẹle asẹ Allah, awọn Malaika yoo si maa fi ikini ọla pade wọn nibẹ, wọn yoo si la kuro nibi gbogbo aleebu nibẹ.
خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ حَسُنَتۡ مُسۡتَقَرّٗا وَمُقَامٗا 76
Wọn yoo maa wa nibẹ gbere, aaye iduro si wọn yii si dara i ibusọkalẹ si ati aaye iduro ti wọn yoo maa wa nibẹ.
قُلۡ مَا يَعۡبَؤُاْ بِكُمۡ رَبِّي لَوۡلَا دُعَآؤُكُمۡۖ فَقَدۡ كَذَّبۡتُمۡ فَسَوۡفَ يَكُونُ لِزَامَۢا 77
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn keferi ti o taku lori sise keferi wọn: Ọlọhun mi ko nii bikita pẹlu yin nitori anfaani ti yoo waa sẹri lọ ba A nibi titẹle asẹ yin, ti kii ba se awọn ẹru kan ti wọn npe E ni pipe ijọsin ati pipe ibeere, ki ba ti kọbi ara si yin, paapa ẹ ti pe ojisẹ naa nirọ nibi ohun ti o mu wa ba yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba yin, wiwa pẹlu yin ni yoo si pada jẹ ẹsan irọ pipa naa.
Ninu iroyin awọn ẹru Ọba Ajọkẹ Aye ni: jijinna si ẹbọ, titakete si pipa ẹmin lailẹtọ ati jijinna si agbere, bẹẹni jijinna si ibajẹ ati wiwo ariwoye si awọn amin Ọlọhun Ọba ati sise adehun.
Ironu piwada ti o mọ kanga ma nse okunfa gbigbe ẹsẹ ju silẹ tabi sise itẹle asẹ.
Suuru jẹ okunfa nibi wiwọ Al-fir'daosi ti o ga julọ ninu ọgba idẹra.
Rirọrọ Ọlọhun Ọba kuro nibi igbagbọ awọn keferi.