هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ مِنۡ عَلَقَةٖ ثُمَّ يُخۡرِجُكُمۡ طِفۡلٗا ثُمَّ لِتَبۡلُغُوٓاْ أَشُدَّكُمۡ ثُمَّ لِتَكُونُواْ شُيُوخٗاۚ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ مِن قَبۡلُۖ وَلِتَبۡلُغُوٓاْ أَجَلٗا مُّسَمّٗى وَلَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ 67
Oun ni Ẹniti O da baba yin Adamọ ninu yerupẹ, lẹyin naa O se isẹda yin ninu omin lọgbọ lẹyin rẹ, lẹyin naa O tun se ẹjẹ didi ninu omin lọgbọ, lẹyin naa yoo mu yin jade ninu awọn iya yin ni ọmọ oponlo ọmọ keekeeke lẹyin eleyi, lẹyin naa ki ẹ le de ọjọ ori lilagbara, lẹyin naa ki ẹ le dagba ti ẹ o fi di arugbo, o si wa ninu yin ẹniti yoo ku siwaju eleyi, ki ẹ si le de ogongo asiko ti a fi aala si ninu imọ Allah, ti ẹ ko nii dinku ninu rẹ tabi lekun le lori, ati wipe o seese ki ẹ se anfaani pẹlu awọn awijare ati awọn ẹri lori agbara Rẹ ati ijọkan soso Rẹ.
هُوَ ٱلَّذِي يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ فَإِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرٗا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ 68
Oun nikan ti mimọ nbẹ fun ni itaniji wa ni ọwọ Rẹ, Oun nikan si ni ipani wa ni ọwọ Rẹ, ti o ba gbero alamọri kan, ohun ti yoo sọ fun alamọri naa ni: (jẹ bẹẹ), yoo si jẹ bẹẹ.
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ أَنَّىٰ يُصۡرَفُونَ 69
Se o ko ri ni - irẹ ojisẹ - awọn ti wọn ja si awọn amin Allah, ti wọn si npe nirọ pẹlu hihan rẹ naa; iwọ yoo se eemọ nibi isesi wọn nigbati wọn ba ngunri kuro nibi ododo pẹlu hihan rẹ.
ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِٱلۡكِتَٰبِ وَبِمَآ أَرۡسَلۡنَا بِهِۦ رُسُلَنَاۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ 70
Awọn ti wọn pe Alukuraani nirọ ati ohun ti a fi gbe awọn ojisẹ Wa dide ninu ododo, awọn olupurọ yii yoo pada mọ igbẹyin irọ pipa wọn, wọn yoo si ri igbẹyin ti o buru.
إِذِ ٱلۡأَغۡلَٰلُ فِيٓ أَعۡنَٰقِهِمۡ وَٱلسَّلَٰسِلُ يُسۡحَبُونَ 71
Wọn mọ igbẹyin rẹ nigbati sẹkẹsẹkẹ wa ni awọn ọrun wọn, bẹẹni awọn onde naa wa ni awọn ẹsẹ wọn, ti awọn Malaaika iya nfi nwọ wọn.
فِي ٱلۡحَمِيمِ ثُمَّ فِي ٱلنَّارِ يُسۡجَرُونَ 72
Wọn yoo maa wọ wọn ninu omin gbigbona eyiti o ti gbona gidigidi lẹyin naa wọn yoo maa ko wọn ninu ina.
ثُمَّ قِيلَ لَهُمۡ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡ تُشۡرِكُونَ 73
Lẹyin naa wọn yoo sọ fun wọn niti ifinise yẹyẹ ati eebu fun wọn: nibo ni awọn ọlọhun ti ẹ nlero wipe ẹ mu ni akẹgbẹ nibi ijọsin Rẹ?!
مِن دُونِ ٱللَّهِۖ قَالُواْ ضَلُّواْ عَنَّا بَل لَّمۡ نَكُن نَّدۡعُواْ مِن قَبۡلُ شَيۡٔٗاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ ٱلۡكَٰفِرِينَ 74
Yatọ si Allah ninu awọn oosa yin eyiti ko le anfaani tabi mu inira ba ni?! Awọn keferi yoo sọpe: wọn ti pa mọ fun wa, awa ko ri wọn, bikosepe awa ko sin nkankan ni ile aye ti o lẹtọ si ijọsin gẹgẹ bi. Allah yoo sọ awọn keferi nu kuro nibi ododo ni gbogbo asiko ati aaye gẹgẹ bi isina awọn eniyan yii.
ذَٰلِكُم بِمَا كُنتُمۡ تَفۡرَحُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَبِمَا كُنتُمۡ تَمۡرَحُونَ 75
Wọn yoo wa sọ fun wọn: iya ti ẹ nfi ara kin yii jẹ okunfa ayọ yin lori ẹbọ ti ẹ wa nibẹ ati gbigbaaye ninu ayọ naa.
ٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ 76
Ẹ maa wọ awọn ẹnu ọna ina jahannamọ ni ẹniti yoo maa gbe ibẹ gbere, o buru ni ibusọ fun awọn olusegberaga kuro nibi ododo.
Nigbati ojisẹ Allah fi ara kin ojhun ti o fi ara kin lọdọ awọn ijọ rẹ, Allah pa a lasẹ suuru sise, O si mu itutu ẹmin ba a pẹlu ohun ti O se ni adehun fun un ni aranse, O wa sọpe:
فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۚ فَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعۡضَ ٱلَّذِي نَعِدُهُمۡ أَوۡ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيۡنَا يُرۡجَعُونَ 77
Se suuru - irẹ ojisẹ - lori suta ijọ Rẹ ati ipeni nirọ wọn, dajudaju adehun Allah lori riran ọ se jẹ ododo ti ko si iyemeji nibẹ, ti a ba fi han ọ ninu isẹmin rẹ apakan ohun ti a se ni adehun fun wọn ninu iya gẹgẹ bi o se sẹlẹ ni ọjọ badiri tabi ki a pa ọ siwaju asiko naa, dajudaju ọdọ Wa nikan ni wọn yoo sẹri si ni ọjọ igbende, a o si san wọn lẹsan lori awọn isẹ wọn, a o si fi wọn wọ inu ina ti wọn yoo maa gbe ibẹ lọ gbere.
Mima se pẹlẹpẹlẹ nibi isẹda jẹ isesi Ọlọhun ti awọn eniyan yoo kẹkọ sise pẹlẹ nibi isẹmin aye wọn.
Aburu ayọpọrọ si ibajẹ.
Pataki suuru ninu isẹmin aye ọmọniyan, paapaa julọ awọn olupepe ninu wọn.