وَلَوۡ أَنَّا كَتَبۡنَا عَلَيۡهِمۡ أَنِ ٱقۡتُلُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ أَوِ ٱخۡرُجُواْ مِن دِيَٰرِكُم مَّا فَعَلُوهُ إِلَّا قَلِيلٞ مِّنۡهُمۡۖ وَلَوۡ أَنَّهُمۡ فَعَلُواْ مَا يُوعَظُونَ بِهِۦ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۡ وَأَشَدَّ تَثۡبِيتٗا 66
Ti o ba ja si wipe a se ni ọranyan le wọn lori ki apakan pa apakan run, tabi ki wọn jade ninu ile wọn; ẹnikankan ki ba ti tẹle asẹ wa ninu wọn ayaafi onka diẹ, ki wọn ya maa dupẹ fun Ọlọhun Ọba Allah pe ko jẹ wọn nipa pẹlu nkan ti yoo ju agbara wọn lọ, ti wọn ba ja si wipe wọn se nkan ti wọn nsọ ni, ninu titẹle asẹ Ọlọhun Ọba Allah, ki ba jẹ oore fun wọn ju iyapa lọ, ki ba si fi igbagbọ wọn rinlẹ, a ba si fun wọn ni ẹsan ti o tobi ni ọdọ wa, bẹẹ ni a ba si fi wọn se kongẹ ọna ti yoo mu wọn de ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ati Alujannah Rẹ.
وَإِذٗا لَّأٓتَيۡنَٰهُم مِّن لَّدُنَّآ أَجۡرًا عَظِيمٗا 67
Ti o ba ja si wipe a se ni ọranyan le wọn lori ki apakan pa apakan run, tabi ki wọn jade ninu ile wọn; ẹnikankan ki ba ti tẹle asẹ wa ninu wọn ayaafi onka diẹ, ki wọn ya maa dupẹ fun Ọlọhun Ọba Allah pe ko jẹ wọn nipa pẹlu nkan ti yoo ju agbara wọn lọ, ti wọn ba ja si wipe wọn se nkan ti wọn nsọ ni, ninu titẹle asẹ Ọlọhun Ọba Allah, ki ba jẹ oore fun wọn ju iyapa lọ, ki ba si fi igbagbọ wọn rinlẹ, a ba si fun wọn ni ẹsan ti o tobi ni ọdọ wa, bẹẹ ni a ba si fi wọn se kongẹ ọna ti yoo mu wọn de ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ati Alujannah Rẹ.
وَلَهَدَيۡنَٰهُمۡ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا 68

وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ فَأُوْلَٰٓئِكَ مَعَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلنَّبِيِّۧنَ وَٱلصِّدِّيقِينَ وَٱلشُّهَدَآءِ وَٱلصَّٰلِحِينَۚ وَحَسُنَ أُوْلَٰٓئِكَ رَفِيقٗا 69
Ẹniti o ba tẹle Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, ẹni naa yii wa pẹlu awọn ti Ọlọhun Ọba se idẹkun fun pẹlu wiwọ Alujannah ninu awọn Anọbi ati awọn sootọ-sootọ, awọn ti igbalododo wọn pe si ohun awọn ojisẹ mu wa, ti wọn si sisẹ pẹlu rẹ, ati ti wọn ku si oju ogun, ati awọn ẹniire, awọn ti ode ati inu wọn dara, ti awọn isẹ wọn naa si dara, ki ni o fi ndara ki awọn naa jẹ alasunmọ ẹni ni inu Alujannah.
ذَٰلِكَ ٱلۡفَضۡلُ مِنَ ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ عَلِيمٗا 70
Eyi ni ẹsan ti a darukọ ni ti ọla lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah si awọn ẹru Rẹ, Ọlọhun Ọba Allah si ti onimimọ nipa isesi wọn, yoo si san gbogbo wọn ni ẹsan pẹlu isẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ خُذُواْ حِذۡرَكُمۡ فَٱنفِرُواْ ثُبَاتٍ أَوِ ٱنفِرُواْ جَمِيعٗا 71
Ẹyin olugbagbọ ododo ninu Ọlọhun Ọba Ati wọn si tu ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ wa isẹra kuro nibi awọn ọta yin pẹlu mimu awọn okunfa ti yoo ran yin lọwọ lori ibawọn ja, ẹ jade si wọn nijọ-nijọ, tabi ki ẹ jade si wọn ni apapọ, gbogbo eyi wa ni ibamu si bi yoo se se anfaani fun yin, ati bi ijiya yoo se maa bẹ fun awọn ọta yin.
وَإِنَّ مِنكُمۡ لَمَن لَّيُبَطِّئَنَّ فَإِنۡ أَصَٰبَتۡكُم مُّصِيبَةٞ قَالَ قَدۡ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيَّ إِذۡ لَمۡ أَكُن مَّعَهُمۡ شَهِيدٗا 72
Ti o ba wa ninu yin - ẹyin Musulumi - awọn ijọ kan ti wọn ba nfa sẹyin lati jade lọ ba awọn ọta yin ja nitori ojo wọn, ti wọn si tun fa awọn miran sẹyin, awọn wọnyi ni sọbẹselo, ti wọn si lẹ ni igbagbọ, ti iku ba pa yin tabi igunri sẹlẹ si yin, ọkan ninu yoo maa sọ ni ti idunnu ati lila rẹ: Ọlọhun Ọba Allah ti se annu mi, ti emi ko si nibi ogun, ti nkan ti o sẹlẹ si wọn ko fi sẹlẹ si mi.
وَلَئِنۡ أَصَٰبَكُمۡ فَضۡلٞ مِّنَ ٱللَّهِ لَيَقُولَنَّ كَأَن لَّمۡ تَكُنۢ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُۥ مَوَدَّةٞ يَٰلَيۡتَنِي كُنتُ مَعَهُمۡ فَأَفُوزَ فَوۡزًا عَظِيمٗا 73
Ti o ba tẹyin lọwọ - ẹyin Musulumi - ọla lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, pẹlu aranse ati iko ọrọ, oluyapa si igbiyanju yoo maa sọ wipe, se kii wa se wipe mo wa ni aarin yin ni, se kii waa se wipe ifẹ ati isunmọ ko si laarin oun si yin ni: o ma se fun mi ti emi ko si pẹlu wọn nibi ogun ti wọn ja ki ẹmi naa jẹ ere ti o tobi ti wọn jẹ yii.
۞فَلۡيُقَٰتِلۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ٱلَّذِينَ يَشۡرُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا بِٱلۡأٓخِرَةِۚ وَمَن يُقَٰتِلۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَيُقۡتَلۡ أَوۡ يَغۡلِبۡ فَسَوۡفَ نُؤۡتِيهِ أَجۡرًا عَظِيمٗا 74
Ki o ya jagun si oju ọna ọna Ọlọhun Ọba Allah ki gbolohun Ọlọhun Ọba Allah le jẹ ohun ti yoo ga julọ, awọn olugbagbọ ododo ti wọn jẹ sootọ-sootọ, awọn ti wọn ta isẹmi aye wọn ni ise oju kokoro kuro nibẹ, lati fi ra ọrun ni ise oju kokoro sii, ẹniti o ba njagun si oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah nitori ki gbolohun rẹ le ga, ti wọn si pa si oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah, tabi o bori ọta rẹ, ti o si jere pẹlu rẹ, Ọlọhun Ọba Allah yoo fun ni ẹsan ti o tobi, ohun naa ni Alaujannah ati iyọnu Ọlọhun.
Sise awọn itẹle asẹ wa ninu awọn okunfa ti o tobi ju lati le duro sinsin lori ẹsin.
Mimu idaabobo ati isọ pẹlu wiwa gbogbo ọna ti o le ran ni lọwọ lati ba ọta ja, kii se jijoko lẹ tabi idagunla si.
Sisọra kuro nibi ifasẹyin kuro nibi igbiyanju, ati mima se awọn eniyan ni oju kokoro kuro nibẹ; nitori wipe dajudaju igbiyanju jẹ okunfa ti o tobi ju ni iyi fun awọn olugbagbọ ododo, o si tun jẹ ikọdi ijẹgaba ọta le wọn lori.