وَلَوۡ أَنَّ أَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ ءَامَنُواْ وَٱتَّقَوۡاْ لَكَفَّرۡنَا عَنۡهُمۡ سَئَِّاتِهِمۡ وَلَأَدۡخَلۡنَٰهُمۡ جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ 65
Ti o ba se wipe yahuudi ati nassara ba nigbagbọ si nkan ti Anọbi Muhammad muwa ni, ti wọn si payọ Ọlọhun Ọba Allah pẹlu jijina si awọn ẹsẹ, a ko pa awọn ẹsẹ wọn ti wọn da rẹ koda bi o pọ, a ba si fi wọn wọ si inu Alujannah onidẹra, wọn yoo maa gbadun nibẹ pẹlu idẹkun ti ko ni tan.
وَلَوۡ أَنَّهُمۡ أَقَامُواْ ٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِم مِّن رَّبِّهِمۡ لَأَكَلُواْ مِن فَوۡقِهِمۡ وَمِن تَحۡتِ أَرۡجُلِهِمۚ مِّنۡهُمۡ أُمَّةٞ مُّقۡتَصِدَةٞۖ وَكَثِيرٞ مِّنۡهُمۡ سَآءَ مَا يَعۡمَلُونَ 66
Ti o ba se wipe yahuudi nse nkan ti o ninu taoreeta ni, bakkanna ni nasaara nse nkan ti o wa ninu injiila, ti gbogbo wọn si se nkan ti o sọkalẹ fun wọn ninu Alukuraani - awọn okunfa arisiki ki ba rọrun fun wọn, gẹgẹ bi isẹkalẹ ojo ati ihu ti irugbin, bẹẹ ni o wa ninu awọn ti a fun ni tira, ẹniti o duro deede, ti o si fi ẹsẹ rinlẹ lori ododo, ọpọ ninu wọn isẹẹ rẹ buru nitori afẹku igbagbọ wọn.
۞يَٰٓأَيُّهَا ٱلرَّسُولُ بَلِّغۡ مَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَۖ وَإِن لَّمۡ تَفۡعَلۡ فَمَا بَلَّغۡتَ رِسَالَتَهُۥۚ وَٱللَّهُ يَعۡصِمُكَ مِنَ ٱلنَّاسِۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡكَٰفِرِينَ 67
ire ojise, mu iro wa nipa nkan ti wọn sọkalẹ lati Ọlọhun Ọba rẹ ni pipe, ma fi ọkankan pamọ nibẹ, ti o ba fi ohun kiohun pamọ nibẹ, iwọ kii se olumu isẹ Ọlọhun Ọba rẹ de ogongo, (bẹẹ ni ojisẹ Allah gbogbo ohun ti wọn pa lasẹ de ogongo, ẹniti o ba gbero ohun ti o yatọ si eleyi, o ti pa irọ ti o tobi mọ Allah) , Ọlọhun Ọba Allah yoo maa da aabo bo wa kuro ni ọdọ awọn eniyan lẹyin oni yii, wọn ko nii le fi aburu kankan se ọ, nkankan ko jẹ dandan fun ọ ju mimu ọrọ de ogongo lọ, Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi awọn keferi, ti wọn ko fẹ imọna se kongẹ itọsọna.
قُلۡ يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَسۡتُمۡ عَلَىٰ شَيۡءٍ حَتَّىٰ تُقِيمُواْ ٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكُم مِّن رَّبِّكُمۡۗ وَلَيَزِيدَنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُم مَّآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَ طُغۡيَٰنٗا وَكُفۡرٗاۖ فَلَا تَأۡسَ عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ 68
Sọ wipe - ire ojise -: ẹyin ko si - ẹyin yahuudi ati nasaara - lori eyikeyi ẹsin, eyiti ẹ nkaa kun, titi ẹ o fi maa se ohun ti o wa ninu taoreeta ati injiila, bakanna ti ẹ o maa se ohun ti o sọkalẹ fun yin ninu Alukuraani, eyiti igbagbọ yin ko le ni alaafia ayaafi ki ẹ ni igbagbọ sii, ki ẹ si tun maa se ohun ti o wa ninu rẹ, ohun ti a sọkalẹ fun ọ ni ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ yoo se alekun ọpọlọpọ ikọja ẹnu aala kan si ikọja ẹnu aala miran fun awọn ti a fun ni tira, ati keferi kan si omiran; nitori keeta ti wọn wa lori rẹ, mase ba ọkan jẹ lori awọn keferi yii ati awọn ti wọn tẹle ọ ninu awọn olugbagbọ ododo, niti rirọrọ ati tito.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلصَّٰبُِٔونَ وَٱلنَّصَٰرَىٰ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ 69
Dajudaju awọn olugbagbọ ati awọn yahuudi ati ọbọna, awọn ni apakan ninu awọn olutẹle awọn Anọbi ati nassara, ẹnikẹni ti o ba gbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah ninu wọn, ti o si tun gba ọjọ ikẹyin gbọ, ti o si tun nse awọn isẹẹre, ko si ipaya fun wọn nibi ohun ti wọn ba nkoju, wọn ko nii banujẹ lori ohun ti o ba bọ mọ wọn lọwọ ninu awọn ipin aye.
لَقَدۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ وَأَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهِمۡ رُسُلٗاۖ كُلَّمَا جَآءَهُمۡ رَسُولُۢ بِمَا لَا تَهۡوَىٰٓ أَنفُسُهُمۡ فَرِيقٗا كَذَّبُواْ وَفَرِيقٗا يَقۡتُلُونَ 70
Paapaa a ti gba adehun ti o kanpa lọwọ awon ọmọ Israeel lori gbigbọ ati itẹle, a si ran awon ojise si won, kiwon le so ofin Olohun Oba Allah fun, wọn si ja adehun ti wọn gba ni ọwọ wọn, wọn waa bẹrẹ sini tẹle oun ti ifẹ inu wọn nsọ fun wọn, gẹgẹ bi igunri kuro nibi oun ti awọn ojisẹ wọn mu wa fun wọn, ati piparọ mọ apakan ati pipa apakan.
Sise isẹ pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ jẹ okunfa pipa awọn asise rẹ ati wiọ Alujannah, bakanna ni gbigbaaye arisiki.
Titọ awọn olupepe sọna nibi wipe imu ọrọ de ogongo nibi ohun ti wọn ba rẹ ati fifọ awọn eniyan mọ jẹ iwọ ni ọrun wọn, ohun si ni nkan ti o pe, ti ko ni adikun, o si wa ninu ibamun si ohun ti imisi mu wa.
Ko si akakun fun eyikeyi aladisọkan kan ti ko ba duro lori wipe Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga ni adisọkan naa ti wa.