قَالُواْ يَٰمُوسَىٰٓ إِمَّآ أَن تُلۡقِيَ وَإِمَّآ أَن نَّكُونَ أَوَّلَ مَنۡ أَلۡقَىٰ 65
Awọn pidan pidan sọ fun Musa ẹniti ọla nbẹ fun: irẹ Musa sa ikan lẹsa ninu awọn alamọri meji: ki o jẹ ẹni igbawaju lati fi ohun ti o nbẹ ni ọwọ rẹ silẹ ninu idan tabi ki o jẹ wipe awa ni a o gbawaju nibẹ.
قَالَ بَلۡ أَلۡقُواْۖ فَإِذَا حِبَالُهُمۡ وَعِصِيُّهُمۡ يُخَيَّلُ إِلَيۡهِ مِن سِحۡرِهِمۡ أَنَّهَا تَسۡعَىٰ 66
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọ wipe: bi kose wipe ẹyin ni ki ẹ ku ohun ti nbẹ ni ọdọ yin silẹ ni akọkọ, wọn si ju ohun ti nbẹ ni ọdọ wọn silẹ, ni ojiji ni okun wọn ati ọpa wọn eyiti wọn ju silẹ han si Musa lati ibi idan wọn ni ejo ti o nyira pada ni kiakia.
فَأَوۡجَسَ فِي نَفۡسِهِۦ خِيفَةٗ مُّوسَىٰ 67
Bayi ni Musa fi ipaya pamọ si inu ẹmin rẹ lati ibi ohun ti wọn se yii.
قُلۡنَا لَا تَخَفۡ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡأَعۡلَىٰ 68
Ọlọhun Allah sọ fun Musa ẹniti ọla nbẹ fun ki o fi ọkan balẹ: mase paya nibi ohun ti o yọ si ọ, dajudaju iwọ - irẹ Musa - ẹniti yoo ga le wọn lori pẹlu ibori ati aranse.
وَأَلۡقِ مَا فِي يَمِينِكَ تَلۡقَفۡ مَا صَنَعُوٓاْۖ إِنَّمَا صَنَعُواْ كَيۡدُ سَٰحِرٖۖ وَلَا يُفۡلِحُ ٱلسَّاحِرُ حَيۡثُ أَتَىٰ 69
Ki o si ju ọpa eyiti o wa ni ọwọ ọtun silẹ, yoo yira pada si ejo, ti yoo si gbe gbogbo ohun ti wọn se ni idan mi, nkan ti wọn se ko jẹ nkankan ju ete onidan lọ, bẹẹni onidan ko le jere ohun ti o nwa nibi ki bi ti o ba wa.
فَأُلۡقِيَ ٱلسَّحَرَةُ سُجَّدٗا قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِرَبِّ هَٰرُونَ وَمُوسَىٰ 70
Musa ju ọpa rẹ silẹ o si di ejo, o si mi gbogbo ohun ti awọn pidan pidan nse, bayi awọn pidan pidan si fi ori balẹ fun Allah nitori imọ wọn wipe ohun ti nbẹ ni ọdọ Musa kii se idan, daju o jẹ lati ọdọ Allah, wọn sọ wipe: a nigbagbọ si Ọlọhun Musa ati haruna ati gbogbo ẹda.
قَالَ ءَامَنتُمۡ لَهُۥ قَبۡلَ أَنۡ ءَاذَنَ لَكُمۡۖ إِنَّهُۥ لَكَبِيرُكُمُ ٱلَّذِي عَلَّمَكُمُ ٱلسِّحۡرَۖ فَلَأُقَطِّعَنَّ أَيۡدِيَكُمۡ وَأَرۡجُلَكُم مِّنۡ خِلَٰفٖ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمۡ فِي جُذُوعِ ٱلنَّخۡلِ وَلَتَعۡلَمُنَّ أَيُّنَآ أَشَدُّ عَذَابٗا وَأَبۡقَىٰ 71
Firaona sọ fun awọn pidan pidan niti atako si igbagbọ wọn ati ni sise adehun iya: se ẹyin yoo nigbagbọ si Musa siwaju ki nto yọnda eleyi fun yin ni?! Dajudaju Musa jẹ olori yin - ẹyin pidan pidan - eyiti o kọ yin ni idan, paapaa julọ emi yoo gbe ẹsẹ kọọkan ati ọwọ kọọkan ni abala ọtọọtọ lara yin, wọn yoo si kan ara yin mọ okutu igi ọpẹ titi ti ẹ o fi ku, ti ẹ o si pada jẹ ariwoye fun ẹlomiran ti o yatọ si yin, ẹyin yoo wa pada mọ ẹniti o lagbara ju ni iya ninu wa ati ẹniti yoo pẹ ju: emi tabi Ọlọhun Musa?!
قَالُواْ لَن نُّؤۡثِرَكَ عَلَىٰ مَا جَآءَنَا مِنَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلَّذِي فَطَرَنَاۖ فَٱقۡضِ مَآ أَنتَ قَاضٍۖ إِنَّمَا تَقۡضِي هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَآ 72
Awọn pidan pidan sọ fun fir'aona: a ko gbọla fun titẹle ọ - irẹ firaona - lori titẹle ohun ti o wa ba wa ninu awọn amin ti o fi oju han, a ko si le gbe ọla fun ọ lori Ọlọhun Allah ti O da wa, ki o ya se ohun ti o ba wu ọ fun wa, iwọ ko ni agbara le wa lori ju isẹmin aye ti yoo tan lọ, bẹẹ ni ọla rẹ yoo si pada yẹ.
إِنَّآ ءَامَنَّا بِرَبِّنَا لِيَغۡفِرَ لَنَا خَطَٰيَٰنَا وَمَآ أَكۡرَهۡتَنَا عَلَيۡهِ مِنَ ٱلسِّحۡرِۗ وَٱللَّهُ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓ 73
Dajudaju awa nigbagbọ si Ọlọhun wa ni ireti wipe yoo se iparẹ awọn ẹsẹ wa ninu keferi ati ohun ti o yatọ si i, yoo si pa ẹsẹ idan wa rẹ eyiti o jẹ wa nipa lati le kọ ati lilo o ati lati le bori Musa pẹlu rẹ, Ọlọhun Ọba Allah loore ni ẹsan ju ohun ti o se ni adehun fun wa lọ, iya Rẹ si le pẹ ju adehun iya ti o se fun wa lọ.
إِنَّهُۥ مَن يَأۡتِ رَبَّهُۥ مُجۡرِمٗا فَإِنَّ لَهُۥ جَهَنَّمَ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحۡيَىٰ 74
Dajudaju isesi ati ounti o sẹlẹ nipe ẹniti o ba wa ba Ọlọhun Ọba rẹ ni ọjọ igbende ni sise keferi Rẹ dajudaju ina jahannamọ nbẹ fun ti yoo wọ ọ, yoo si maa wa nibẹ gbere, ko nii ku bẹẹni ko ni sin mi nibi iya ibẹ, ko si ni sẹmin ni isẹmin ti o dara.
وَمَن يَأۡتِهِۦ مُؤۡمِنٗا قَدۡ عَمِلَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَأُوْلَٰٓئِكَ لَهُمُ ٱلدَّرَجَٰتُ ٱلۡعُلَىٰ 75
Ẹniti ti o ba si wa ba Ọlọhun Ọba rẹ ni olugbagbọ si I, ti o ti se ọpọlọpọ isẹẹre, awọn wọnyi ni ẹniti a royin pẹlu awọn iroyin ti o tobi naa, awọn ipo giga nbẹ fun wọn ati awọn ipele giga.
جَنَّٰتُ عَدۡنٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ جَزَآءُ مَن تَزَكَّىٰ 76
Awọn agbega yii ni ọgba idẹra ti wọn yoo maa wa nibẹ, ti akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ, yoo si maa wa nibẹ lailai, ẹsan ti a sọ yoo jẹ ẹsan gbogbo ẹniti o ba mọ kanga kuro nibi keferi ati awọn ẹsẹ.
Onidan ko le jere bẹẹni ko le la nibi kibi ti o ba de ni oriilẹ, tabi ibikibi ti o ba ti lo ọgbọn, bẹẹni erongba rẹ daadaa tabi aburu ko le ni amusẹ lati ibi aburu.
Igbagbọ ma nse isẹ iyanu; paapaa igbagbọ awọn pidandan rinlẹ ju oke lọ ni iya ile aye fi yẹpẹrẹ ni ọdọ wọn, wọn ko si ka idẹruba fir'aona kun.
Isesi awọn olukọja ẹnu aala ni ki wọn maa fi iya ti o le koko dẹru bani fun awọn ẹni ootọ ati ki wọn rinlẹ nibi eleyi lati le yẹpẹrẹ ati sisọ ẹni di ẹni ilẹ.