رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا فَٱعۡبُدۡهُ وَٱصۡطَبِرۡ لِعِبَٰدَتِهِۦۚ هَلۡ تَعۡلَمُ لَهُۥ سَمِيّٗا 65
Asẹda sanmọ ati asẹda ilẹ ati olukapa mejeeji ati oludari alamọri wọn, ati asẹda ohun ti nbẹ laarin mejeeji ati olukapa rẹ ati oludari rẹ, ki o maa sin In ni Oun nikan, Oun si ni ẹniti ijọsin tọsi, ki o sin duro sinsin lori ijọsin Rẹ, ko si apejuwe tabi akẹgbẹ fun Un ti yoo kun lọwọ nibi ijọsin.
وَيَقُولُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَءِذَا مَا مِتُّ لَسَوۡفَ أُخۡرَجُ حَيًّا 66
Keferi ti o tako igbende yoo sọpe; niti sise yẹyẹ: se ti mo ba ku, se dajudaju maa pada jade ninu saare mi ni alaaye ni isẹmin ẹlẹẹkeji bi?! Dajudaju eleyi jinna.
أَوَ لَا يَذۡكُرُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَنَّا خَلَقۡنَٰهُ مِن قَبۡلُ وَلَمۡ يَكُ شَيۡٔٗا 67
Se olutako igbende yii ko ranti ni, Awa ni a da a siwaju ti k jẹ nkankan?! O nfi isẹda akọkọ se ẹri lori isẹda ẹlẹẹkeji, ti o si jẹ wipe dida ẹlẹẹkeji ni o rọrun, ti o si dẹkun.
فَوَرَبِّكَ لَنَحۡشُرَنَّهُمۡ وَٱلشَّيَٰطِينَ ثُمَّ لَنُحۡضِرَنَّهُمۡ حَوۡلَ جَهَنَّمَ جِثِيّٗا 68
Mo fi Ọlọhun Ọba rẹ bura –ire ojise- paapaa julọ a o mu u jade ninu saare wọn lọ si aaye akojọ pẹlu awọn esu wọn ti o sọ wọn nu, lẹyin igba naa a o maa da wọn gẹrẹgẹrẹ lọsi ẹnu ọna jahannamo ni iyẹpẹrẹ ni ẹniti yoo wa lori ikunlẹ wọn.
ثُمَّ لَنَنزِعَنَّ مِن كُلِّ شِيعَةٍ أَيُّهُمۡ أَشَدُّ عَلَى ٱلرَّحۡمَٰنِ عِتِيّٗا 69
Lẹyin naa a o ti wọn lọpọnpọm ni lile ati funfun ni abala kọọkan ninu awọn abala anu ni ibamun si bi ẹsin wọn ba se nipọn si, awọn ni yoo maa dari wọn.
ثُمَّ لَنَحۡنُ أَعۡلَمُ بِٱلَّذِينَ هُمۡ أَوۡلَىٰ بِهَا صِلِيّٗا 70
Lẹyin naa awa ni a mọ ẹniti o lẹtọ ju lati wọn ina, ti o si tun le fi ara kin igbonaa bẹ ati inira bẹ.
وَإِن مِّنكُمۡ إِلَّا وَارِدُهَاۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ حَتۡمٗا مَّقۡضِيّٗا 71
Ko si ẹnikankan ninu yin - ẹyin eniyan - ayaafi ki o re kọja lori afara naa eyiti a tẹ lori jahannamo, rire koja yii jẹ akosilẹ ti a ti la kalẹ, ti Ọlọhun Ọba se leto, ko si ohun ti o le da eto Ọlọhun Ọba pada.
ثُمَّ نُنَجِّي ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْ وَّنَذَرُ ٱلظَّٰلِمِينَ فِيهَا جِثِيّٗا 72
Lẹyin irekọja lori afara yii, a o maa la awọn ti wọn ba paya Ọlọhun Ọba wọn pẹlu titẹle asẹ Rẹ ati jijinna si awọn nkan ti o kọ, a o si fi awọn alabosi silẹ lori ipinya wọn, wọn ko nii nikapa lati sa kuro nibẹ.
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَيُّ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ خَيۡرٞ مَّقَامٗا وَأَحۡسَنُ نَدِيّٗا 73
Ti wọn ba nta awọn amin wa ti a sọkalẹ fun awọn ojisẹ Wa ni ohun ti o fi oju han fun awọn eniyan, awọn keferi yoo maa sọ fun awọn olugbagbọ ododo: ewo ninu ipin wa lo loore niti diduro si ati ibugbe, ti o si tun dara ju ni ibujokosi ati ibukojọsi: se ipin wa ni tabi ipin ti yin?!
وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّن قَرۡنٍ هُمۡ أَحۡسَنُ أَثَٰثٗا وَرِءۡيٗا 74
Bawo ni pipọ awọn ijọ ti a pa wọn se to na siwaju awọn keferi ti wọn nse iyanran yii pẹlu gbigbawaju wọn nibi awọn nkan yẹpẹrẹ, awọn wọnni dara ju wọn lọ ni dukia, wọn si dara ni irisi nitori niniye lori asọ wọn ati gbigbadun ara wọn.
قُلۡ مَن كَانَ فِي ٱلضَّلَٰلَةِ فَلۡيَمۡدُدۡ لَهُ ٱلرَّحۡمَٰنُ مَدًّاۚ حَتَّىٰٓ إِذَا رَأَوۡاْ مَا يُوعَدُونَ إِمَّا ٱلۡعَذَابَ وَإِمَّا ٱلسَّاعَةَ فَسَيَعۡلَمُونَ مَنۡ هُوَ شَرّٞ مَّكَانٗا وَأَضۡعَفُ جُندٗا 75
Sọ fun - irẹ ojisẹ -: ẹniti o nlọ ti o nbọ ninu ọna anu, Ọba Ajọkẹ Aye yoo dẹlẹkẹ titi ti yoo fi lekun ninu ọna anu, titi yoo fi di igbati wọn fi oju kan ohun ti wọn se adehun fun wọn ninu iya, iya ikọnjujẹ laye tabi eyiti wọn yoo pada jẹ ni ọjọ igbende, igba naa ni wọn yoo waa mọ ẹniti ibudesi rẹ buru ati ẹniti alaranse rẹ kere ju, se ipin ti wọn tabi ipin awọn olugbagbọ ododo?
وَيَزِيدُ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ٱهۡتَدَوۡاْ هُدٗىۗ وَٱلۡبَٰقِيَٰتُ ٱلصَّٰلِحَٰتُ خَيۡرٌ عِندَ رَبِّكَ ثَوَابٗا وَخَيۡرٞ مَّرَدًّا 76
Ni idojukọ si ilọlara fun awọn eniyan titi wọn yoo fi lekun ni anu, Ọlọhun Ọba Allah yoo se alekun igbagbọ, itẹle ati awọn isẹẹre eyiti ti yoo mu wọn de ibi oriire lailai fun awọn ti wọn mọ ọna, ohun ni ẹsan rẹ ni anfaani ju lọdọ Ọlọhun Ọbaa rẹ -irẹ ojisẹ-, ti o si loore ni igbẹyin.
Dandan ni fun awọn olugbagbọ ododo ki wọn ko airoju pẹlu ohun ti wọn pa wọn lasẹ rẹ, ki wọn si maa tẹsiwaju nibẹ ni ibamun si bi wọn se lagbara.
Didari ọpọlọpọ awọn ẹda si ina - itumọ rẹ nipe: kikọja lori afara naa, kii se wiwọ ina -, alamọri ti yoo sẹlẹ ni, ti ko si ibuyẹ.
Dajudaju osunwọn ẹsin ati awọn agbọye rẹ ti ni alaafia yapa si iwoye awọn alaimọkan ati ọpọlọpọ awọn eniyan.
Ẹniti o ba ti tẹri si inu anu, ti o si ti pilẹ ninu keferi Ọlọhu Allah yoo fi silẹ ninu ikọja ẹnu aala aimọkan ati keferi rẹ titi itanjẹ rẹ yoo fi pẹ, eyi yoo waa jẹ lilekoko fun ijiya rẹ.
Ọlọhun Ọba Allah yoo fi awọn olugbagbọ ododo rinlẹ lori imọna, Yoo si se alekun kongẹ ati aranse wọn, yoo si sọ awọn amin kalẹ ti yoo jẹ okunfa lilekun amọdaju ni iẹsan fun wọn.