وَٱللَّهُ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَآۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَسۡمَعُونَ 65
Ọlọhun Allah sọ ojo kalẹ ni agede sanmọ, O si fi nta ilẹ ji pẹlu yiyọ awọn irugbin jade nibẹ lẹyin igbati o ti jẹ ilẹ oko ti o gbẹ, dajudaju nibi sisọ ojo kalẹ ni agede sanmọ yii ati yiyọ irugbin jade nibẹ jẹ itọka ti o fi oju han lori agbara Allah fun awọn ijọ ti wọn ngbọ ọrọ Allah, ti wọn si nronu pẹlu rẹ.
وَإِنَّ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَنۡعَٰمِ لَعِبۡرَةٗۖ نُّسۡقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهِۦ مِنۢ بَيۡنِ فَرۡثٖ وَدَمٖ لَّبَنًا خَالِصٗا سَآئِغٗا لِّلشَّٰرِبِينَ 66
Dajudaju o wa fun yin - ẹyin eniyan - lara rakun, maalu ati aguntan isiti ti ẹ le gba yẹwo nibi fifun yin ni wara ọyan rẹ mu eyiti o njade laarin agede meji ikun ati aaye igbẹ, ati ẹjẹ ti o wa lara, pẹlu eleyi wara njade ni mimọ ati didun fun mimu.
وَمِن ثَمَرَٰتِ ٱلنَّخِيلِ وَٱلۡأَعۡنَٰبِ تَتَّخِذُونَ مِنۡهُ سَكَرٗا وَرِزۡقًا حَسَنًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ 67
Isiti nbẹ fun yin nibi ohun ti A nse fun yin lara eso ọpẹ ati awọn eso inabi, ti ẹ nmu oti eyiti nmu laakaye lọ nibẹ, ti kii si se ohun ti o dara, ẹ si tun mu arisiki ti o dara nibẹ, ti ẹ nse anfaani pẹlu rẹ gẹgẹ bi tamuru ati sabiibu ati kallu ati dibisi, dajudaju nibi ohun ti a sọ yii jẹ itọka lori agbara Allah ati idẹkun Rẹ lori awọn ẹru Rẹ fun ijọ ti o se laakaye, awọn ni ẹniti yoo gba ariwoye.
وَأَوۡحَىٰ رَبُّكَ إِلَى ٱلنَّحۡلِ أَنِ ٱتَّخِذِي مِنَ ٱلۡجِبَالِ بُيُوتٗا وَمِنَ ٱلشَّجَرِ وَمِمَّا يَعۡرِشُونَ 68
Ọlọhun Ọba rẹ fi imọ mọ - irẹ ojisẹ - oyin, O si tọ ọ sọna ki o le: mu ile ninu oke, ki o si tun mu ile ninu igi ati nibi ohun ti awọn eniyan nkọ, ti wọn si se aja si.
ثُمَّ كُلِي مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ فَٱسۡلُكِي سُبُلَ رَبِّكِ ذُلُلٗاۚ يَخۡرُجُ مِنۢ بُطُونِهَا شَرَابٞ مُّخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهُۥ فِيهِ شِفَآءٞ لِّلنَّاسِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ 69
Lẹyin igba naa ki o jẹ ninu gbogbo oun ti o ba wu ọ ninu gbogbo eso, ki o si tọ awọn oju ọna eyiti Ọlọhun Ọba rẹ fi imọ rẹ mọ ọ niti irọrun, oyin lila ti awọ rẹ yatọ si ara wọn yoo jade lati oyin naa, funfun ati pupa fẹsifẹsi wa nibẹ ati eyiti o yatọ si awọn mejeeji, iwosan fun awọn eniyan naa si wa nibẹ, ti wọn yoo maa fi se iwosan fun awọn aarẹ, dajudaju itọka lori agbara Allah ati sise eto idari ẹda Rẹ wa nibi fifi imọ mọ oyin ati oyin lila eyiti o jade ni ara rẹ fun awọn ijọ ti o nronu, awọn ni ẹniti yoo wo ariwoye.
وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ ثُمَّ يَتَوَفَّىٰكُمۡۚ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰٓ أَرۡذَلِ ٱلۡعُمُرِ لِكَيۡ لَا يَعۡلَمَ بَعۡدَ عِلۡمٖ شَيًۡٔاۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٞ قَدِيرٞ 70
Ọlọhun Allah da yin lati ibi ohun ti ko si apejuwe siwaju rẹ, lẹyin igba naa Yoo pa yin nigbati asiko yin ba tan, o wa ninu yin ẹniti ọjọ ori rẹ yoo gun titi di ipo ọjọ ori ti o buru, ohun naa ni igba ogbo, ko le mọ nkankan ninu ohun ti o mọ, dajudaju Allah jẹ onimimọ ti nkankan ko pamọ fun Un ninu awọn isẹ ẹru Rẹ, Alagbara ti nkankan ko le ko agara ba A.
وَٱللَّهُ فَضَّلَ بَعۡضَكُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ فِي ٱلرِّزۡقِۚ فَمَا ٱلَّذِينَ فُضِّلُواْ بِرَآدِّي رِزۡقِهِمۡ عَلَىٰ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَهُمۡ فِيهِ سَوَآءٌۚ أَفَبِنِعۡمَةِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ 71
Allah ti O gbọngbọn gbe ọla fun apakan yin lori apakan nibi arisiki ti O ta yin lọrẹ, O se ọlọrọ ati olosi ninu yin, asiwaju ati ẹniti wọn ndari, awọn ti Allah gbe ọla fun ninu arisiki kii se oludapada ohun ti Allah fun wọn lori ẹru wọn titi ti wọn yoo fi di akẹgbẹ dọgbọndọgba nibi ọla, bawo wọn se waa le yọnu si akẹgbẹ ninu ẹru rẹ fun Allah, wọn ko si yọnu si akẹgbẹ fun ẹmin ara wọn nibi ẹru wọn, ti wọn yoo jọ jẹ dọgbandọgba? Abosi wo ni eleyi, jija idẹkun Ọlọhun niyan wo ni o to eleyi?!
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَزۡوَٰجِكُم بَنِينَ وَحَفَدَةٗ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِۚ أَفَبِٱلۡبَٰطِلِ يُؤۡمِنُونَ وَبِنِعۡمَتِ ٱللَّهِ هُمۡ يَكۡفُرُونَ 72
Ọlọhun Ọba Allah se fun yin - ẹyin eniyan - akọ ati abo ninu iran yin ti ẹ nba nnaju, o si se awọn ọkunrin ati awọn ọmọ ọmọkunrin ninu lọkọ laya yin, O si ran yin se ninu awọn nkan jijẹ - gẹgẹ bi ekiri ẹran, ati awọn nkan horo ati awọn nkan ipapanu - eyiti o dara ninu rẹ, se awọn ẹbọ ati awọn oosa ti o jẹ ibajẹ ni wọn yoo nigbagbọ si tabi idẹkun Allah ti o pọ eyiti wọn ko lee ka ni wọn yoo maa se keferi si, ti wọn ko waa ni dupẹ fun Allah pẹlu ki wọn o nigbagbọ si I ni Oun nikan soso?!
Ọba ti O ga se anfaani fun ẹru Rẹ ninu awọn eso ọpẹ ati eso inabi ati anfaani ni oniranran arisiki eyiti o dara ti awọn ẹru njẹ ni ọmunu ati gbigbo ati eyiti o wa ni ipese ati eyiti a fi pamọ ati onjẹ ati mimu.
Nibi dida kokoro oyin kekere ati ounti o njade ninu rẹ ni oyin lila ti o dun ni oniranran awọ ni ibamun si yiyapa ilẹ rẹ ati awọn nkan jijẹ rẹ jẹ itọka lori pipe akiyesi Ọlọhun Ọba Allah ti O ga, ati pipe aanu Rẹ fun awọn ẹru Rẹ ati wipe Ohun ni Ẹniti ko tọ ki a so nkan miran mọ, tabi pe nkan miran yatọ si I.
Ninu idẹkun Allah ti o tobi lori ẹru Rẹ ni ki O se takọ tabo ki wọn le maa gbe ninu rẹ, O si se awọn ọmọ lati ara tọkọ taya ki o le jẹ itutu oju fun wọn, ki wọn si maa sisẹ sin wọn, bakannaa ki wọn maa ran wọn lọwọ nibi bukaata wọn, ki wọn si maa se anfaani lara wọn ni ọpọlọpọ ojupọnna.