أَمَّن يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ وَمَن يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۗ أَءِلَٰهٞ مَّعَ ٱللَّهِۚ قُلۡ هَاتُواْ بُرۡهَٰنَكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 64
Tabi ẹniti O bẹrẹ dida ẹda ninu apo ibi ni igbesẹ kan lẹyin igbesẹ, lẹyin naa ti O si ta a ji lẹyin igbati o ti pa a, ati ẹniti o ran yin se lati sanmọ pẹlu ojo ti o sọkalẹ nibẹ, ti O si tun ran yin se ninu ilẹ pẹlu awọn irugbin ti o nwu nibẹ! Se ẹni ẹ njọsin fun ni o nse eleyi pẹlu Allah ni?! Sọpe - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ yii: ẹ mu awijare yin lori ohun ti ẹ wa nibẹ ninu ẹbọ ti o ba jẹ olododo ni yin nibi ohun ti ẹ npe ara yin wipe ori otitọ lẹ wa.
قُل لَّا يَعۡلَمُ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ ٱلۡغَيۡبَ إِلَّا ٱللَّهُۚ وَمَا يَشۡعُرُونَ أَيَّانَ يُبۡعَثُونَ 65
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: ẹniti o nbẹ ni sanmọ ninu awọn Malaika ko mọ kọkọ ati eniyan ti o nbẹ ni ori ilẹ naa ko mọ ọ, sugbọn Allah nikan soso ni O mọ ọ, bẹẹni gbogbo ẹniti o nbẹ ni sanmọ ati ẹniti o nbẹ ni ori ile ko mọ igbati wọn yoo gbe wọn dide ayaafi Allah.
بَلِ ٱدَّٰرَكَ عِلۡمُهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِۚ بَلۡ هُمۡ فِي شَكّٖ مِّنۡهَاۖ بَلۡ هُم مِّنۡهَا عَمُونَ 66
Tabi se imọ wọn ntọpa ọrun ni ti wọn fi mọ amọdaju bẹẹ bi? Rara, bikosepe wọn wa ninu iyemeji ati idaamun nipa ọrun, koda paapaa wọn fọju nipa rẹ.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَءِذَا كُنَّا تُرَٰبٗا وَءَابَآؤُنَآ أَئِنَّا لَمُخۡرَجُونَ 67
Awọn keferi sọ ni ẹniti o korira: se ti a ba ku, ti a di yeepẹ se o rọrun ki wọn gbe wa dide ni aaye bi?
لَقَدۡ وُعِدۡنَا هَٰذَا نَحۡنُ وَءَابَآؤُنَا مِن قَبۡلُ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ 68
Paapaa wọn ti se adehun fun wa, wọn si se adehun awọn baba wa siwaju wipe dajudaju wọn yoo gbe wa dide papọ, awa ko ri ododo nibi adehun yii, adehun yii ko jẹ nkankan ti wọn se fun gbogbo wa ayaafi irọ awọn ẹni akọkọ ti wọn rọ silẹ ninu iwe wọn.
قُلۡ سِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ 69
Sọ fun - irẹ ojisẹ - awọn olutako igbende yii: ẹ rin ni eyikeyi abala oriilẹ, ki ẹ ronu si bawo ni igbẹyin awọn ẹlẹsẹ, opurọ nipa ọjọ igbende se ri, paapaa julọ a pa wọn run nitori pipe e nirọ.
وَلَا تَحۡزَنۡ عَلَيۡهِمۡ وَلَا تَكُن فِي ضَيۡقٖ مِّمَّا يَمۡكُرُونَ 70
Mase banujẹ nitori igunri awọn ẹlẹbọ kuro nibi ipepe rẹ, masi jẹ ki igbaaya rẹ fun nibi ete wọn, Ọlọhun Ọba Allah yoo jẹ alaranse fun ọ le wọn lori.
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 71
Awọn keferi ti o ntako igbende yoo sọ ninu ijọ rẹ: nigba wo ni ohun ti ẹ nse ni adehun fun wa ninu iya yoo di ododo iwọ ati awọn olugbagbọ ododo ti ẹ ba jẹ olootọ nibi ohun ti ẹ npe apemọra rẹ yii?
قُلۡ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ رَدِفَ لَكُم بَعۡضُ ٱلَّذِي تَسۡتَعۡجِلُونَ 72
Sọ fun wọn wipe - irẹ ojisẹ -: o seese ki apakan ohun ti ẹ nkanju rẹ ninu iya ti sun mọ yin.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَشۡكُرُونَ 73
Ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - jẹ ọlọla lori awọn eniyan nigbati o gbe ikanju fi iya jẹ wọn silẹ pẹlu wiwa lori keferi ati ẹsẹ wọn naa, sugbọn ọpọ awọn eniyan kii dupẹ fun Allah lori idẹkun ti O se le wọn lori.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَيَعۡلَمُ مَا تُكِنُّ صُدُورُهُمۡ وَمَا يُعۡلِنُونَ 74
Ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ mọ ohun ti ọkan awọn ẹru Rẹ di sinu ati ohun ti wọn se afihan rẹ, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
وَمَا مِنۡ غَآئِبَةٖ فِي ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٍ 75
Nkankan ko pamọ fun awọn eniyan ni sanmọ, bẹẹni ko jẹ nkan ipamọ fun wọn ni oriilẹ ayaafi fi ki nkan naa ti wa ninu iwe ti o fi oju han, ohun si ni ọpọn ti A daabobo.
إِنَّ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ يَقُصُّ عَلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ أَكۡثَرَ ٱلَّذِي هُمۡ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ 76
Dajudaju Alukuraani ti A sọkalẹ fun Muhammad ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun yii nsọ itan fun awọn ọmọ isirẹli lori ọpọ ohun ti wọn yapa le lori, o si nse afihan ọpọ yiyẹ kuro ni oju ọna wọn.
Imọ kọkọ wa ninu ohun ti o jẹ ẹsa pẹlu Allah, pipe apemọra rẹ si jẹ keferi.
Gbigba iwoye pẹlu awọn ti o ti siwaju nibi ibudarisi rẹ ati awọn isesi wọn jẹ ọna ọla.
Kikari imọ Allah si awọn isẹ ẹru Rẹ.
Sise atunse Alukuraani fun yiyẹ kuro loju ọna awọn ọmọ isirẹli ati yiyi awọn iwe wọn pada.