قَالَ هَلۡ ءَامَنُكُمۡ عَلَيۡهِ إِلَّا كَمَآ أَمِنتُكُمۡ عَلَىٰٓ أَخِيهِ مِن قَبۡلُ فَٱللَّهُ خَيۡرٌ حَٰفِظٗاۖ وَهُوَ أَرۡحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ 64
Baba wọn sọ fun wọn: se mo ni ifọkanbalẹ lọdọ yin lori re gẹgẹ bi mo se ni ifọkanbalẹ lọdọ yin lori ọmọ iya rẹ: tii se yusuf saaju, ẹ ti fi mi lọkan balẹ le lori, ẹ si se adehun wipe ẹyin yoo maa sọ ọ sugbọn ẹ ko pe adehun yin pẹlu rẹ, igbẹkẹle lati ọdọ mi ko si fun adehun yin lori sisọ ọ, bikose wipe igbẹkẹle mi wa pẹlu Allah, Oun ni ẹniti o loore ju ni olusọ fun ẹniti o ba fẹ sọ, O si kẹni ju gbogbo ẹniti kẹni lọ fun ẹniti O ba fẹ kẹ.
وَلَمَّا فَتَحُواْ مَتَٰعَهُمۡ وَجَدُواْ بِضَٰعَتَهُمۡ رُدَّتۡ إِلَيۡهِمۡۖ قَالُواْ يَٰٓأَبَانَا مَا نَبۡغِيۖ هَٰذِهِۦ بِضَٰعَتُنَا رُدَّتۡ إِلَيۡنَاۖ وَنَمِيرُ أَهۡلَنَا وَنَحۡفَظُ أَخَانَا وَنَزۡدَادُ كَيۡلَ بَعِيرٖۖ ذَٰلِكَ كَيۡلٞ يَسِيرٞ 65
Nigbati wọn si awọn apo ounjẹ wọn eyiti wọn gba, wọn ri iye rẹ ti o ti da pada fun wọn, wọn wa sọ fun baba wọn: kinni a tun nfẹ lọdọ ọba yii lapọnle lẹyin eleyi? Eleyi ni iye owo ounjẹ ti o dapa fun wa niti sise ọla lati ọdọ rẹ le wa lori, ti a si tun wa mu ounjẹ lọ fun awọn eniyan wa, a nsọ ọmọ iya wa lori ohun ti o npaya le lori, a nwa alekun osunwọn ọja nitori sisun mọ ọ, sise alekun osunwọn oja jẹ alamọri ti o rọrun lọdọ ọba.
قَالَ لَنۡ أُرۡسِلَهُۥ مَعَكُمۡ حَتَّىٰ تُؤۡتُونِ مَوۡثِقٗا مِّنَ ٱللَّهِ لَتَأۡتُنَّنِي بِهِۦٓ إِلَّآ أَن يُحَاطَ بِكُمۡۖ فَلَمَّآ ءَاتَوۡهُ مَوۡثِقَهُمۡ قَالَ ٱللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٞ 66
Baba wọn sọ fun wọn wipe: emi ko nii gbe dide pẹlu yin titi ti ẹ o fi fun mi ni adehun Ọlọhun Ọba ti o kanpa wipe ẹ o da pada si ọdọ mi ayaafi ti kiparun ba ba gbogbo yin lapapọ, ti ko si sẹku ẹnikankan ninu yin, ti ẹ ko ba ti lagbara lati daabobo o, ki ẹ yaa ma pada, nigbati wọn fun ni adehun Ọlọhun Ọba ti o kanpa lori eleyi, o sọ wipe: Ọlọhun Ọba jẹ ẹlẹri lori nkan ti a sọ, ijẹri Rẹ si to fun wa.
وَقَالَ يَٰبَنِيَّ لَا تَدۡخُلُواْ مِنۢ بَابٖ وَٰحِدٖ وَٱدۡخُلُواْ مِنۡ أَبۡوَٰبٖ مُّتَفَرِّقَةٖۖ وَمَآ أُغۡنِي عَنكُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٍۖ إِنِ ٱلۡحُكۡمُ إِلَّا لِلَّهِۖ عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُۖ وَعَلَيۡهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُتَوَكِّلُونَ 67
Baba wọn sọ fun wọn ni ẹniti o nsọ asọtẹlẹ fun wọn: ẹ mase wọ inu misirọ ni oju ọna kan soso lapapọ, sugbọn ki ẹ gba oju ọna ọtọọtọ wọle, eleyi ni o le la yin ju ki aburu maa ba ba yin nigbati ẹnikẹni ba gbero rẹ si yin, emi ko sọ fun yin wipe eleyi ni yoo ti aburu kuro fun yin ti Ọlọhun ba fẹ bẹ ẹ, kii si se wipe ki nle fa anfaani kan fun yin ti Ọlọhun Ọba ko ba fẹ bẹ, akọsilẹ ko le sẹlẹ ayaafi pẹlu fifẹ Ọlọhun Ọba, asẹ kankan ko si ayaafi asẹ Rẹ, Oun nikan ni mo gbara le nibi gbogbo ọrọ mi, Oun nikan ni gbogbo alugbara gbọdọ maa gbara le nibi gbogbo ọrọ wọn.
وَلَمَّا دَخَلُواْ مِنۡ حَيۡثُ أَمَرَهُمۡ أَبُوهُم مَّا كَانَ يُغۡنِي عَنۡهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٍ إِلَّا حَاجَةٗ فِي نَفۡسِ يَعۡقُوبَ قَضَىٰهَاۚ وَإِنَّهُۥ لَذُو عِلۡمٖ لِّمَا عَلَّمۡنَٰهُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ 68
Wọn bẹrẹ sini lọ, bẹẹ ni ọmọ iya ọmọ baba rẹ wa pẹlu wọn nigbati wọn wọle ni ọna ọtọọtọ gẹgẹ bi baba wọn se pa wọn lasẹ, wiwọle wọn ni ẹnu ọna ọtọọtọ ko kọdi nkan ti Ọlọhun Ọba Allah ti kadara wipe yoo sẹlẹ si wọn, o kan jẹ aanu lati ọdọ Ya'quub lori awọn ọmọ rẹ ni, o se afihan rẹ, o si sọ asọtẹlẹ rẹ fun wọn, o si mọ wipe akọsilẹ kankan ko si ayaafi akọsilẹ Allah, o jẹ onimimọ pẹlu nkan ti a fi mọ ọ ninu igbagbọ si kadara ati mimu okunfa sugbọn ọpọ awọn eniyan ko mọ eleyi.
وَلَمَّا دَخَلُواْ عَلَىٰ يُوسُفَ ءَاوَىٰٓ إِلَيۡهِ أَخَاهُۖ قَالَ إِنِّيٓ أَنَا۠ أَخُوكَ فَلَا تَبۡتَئِسۡ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 69
Nigbati awọn ọmọ baba Yuusuf wọle ti Yuusuf, ti ọmọ iya ọmọ baba rẹ si wa pẹlu wọn, o fa ọmọ iya ọmọ baba rẹ yii mọra, o si sọ fun ni kọkọ: dajudaju emi ni ọmọ iya ọmọ baba rẹ: tii se Yuusuf, mase banujẹ lori ohun ti awọn ọmọ baba rẹ se ninu isẹ idọkanru; gẹgẹ bi fifi suta ati keeta se wa ati jiju ti wọn ju mi sinu kanga.
Pipasẹ mimura silẹ ati sisọra kuro nibi ẹniti a ba ti ri amin ọdalẹ ni ọdọ rẹ, o wa ninu Hadith ti o ni alaafia: (akeke kan ko gbọdọ ta olugbagbọ ododo ninu iho kan lẹẹmeji). [Imam Bukhari ati Muslim lo mu sita]
Ninu ojupọnna imurasilẹ ni ki a kan pa mọ gbigba adehun ati ibura ti o nipọn ati sise lẹtọ wiwa ibura lọdọ ẹniti a ba nbẹru lati le sọ ohun ti a fi dogo tabi gbafipamọ si lọdọ.
O tọ fun ẹniti o nbeere ibura ki o se ayaafi awọn alamọri kan eyiti o ba ri wipe ko si ninu ikapani ẹniti o ba fẹ bura.
Ninu mimu okunfa ni ki a mura silẹ kuro nibi awọn nkan ewu.