قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَءَاتَىٰنِي مِنۡهُ رَحۡمَةٗ فَمَن يَنصُرُنِي مِنَ ٱللَّهِ إِنۡ عَصَيۡتُهُۥۖ فَمَا تَزِيدُونَنِي غَيۡرَ تَخۡسِيرٖ 63
Sọlihu fesi pada fun awọn ijọ rẹ: ẹyin ijọ mi, ẹ fun mi niro ti mo ba wa lori awijare ti o fi oju han lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, ti o si fun mi ni ikẹ tii se jijẹ anọbi lati ọdọ Rẹ, taani yoo kọ fun mi kuro nibi iya rẹ ti mo ba sẹ Ẹ lati ibi gbigbe imjudopin ohun ti wọn pa mi lasẹ si yin ju silẹ? ko si ohun ti yoo se alekun fun mi ju isina lọ ati jijinna si iyọnu Rẹ.
وَيَٰقَوۡمِ هَٰذِهِۦ نَاقَةُ ٱللَّهِ لَكُمۡ ءَايَةٗۖ فَذَرُوهَا تَأۡكُلۡ فِيٓ أَرۡضِ ٱللَّهِۖ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوٓءٖ فَيَأۡخُذَكُمۡ عَذَابٞ قَرِيبٞ 64
Ẹyin ijọ mi, eleyi ni rakunmi Allah fun yin ti o jẹ amin lori jijẹ ododo mi, ki ẹ ya fi silẹ ki o ma jẹ lori ilẹ Ọlọhun Allah, ẹ mase sẹri suta kankan si ki iya Ọlọhun Ọba ti o sun mọ ko maa ba jẹ yin ni asiko ti ẹ ba fi suta se e.
فَعَقَرُوهَا فَقَالَ تَمَتَّعُواْ فِي دَارِكُمۡ ثَلَٰثَةَ أَيَّامٖۖ ذَٰلِكَ وَعۡدٌ غَيۡرُ مَكۡذُوبٖ 65
Wọn gun niti imọọmọ nibi piope e nirọ, sọlihun si sọ fun wọn: ẹ maa gbadun isẹmin lori ilẹ fun ọjọ mẹta lẹyin gigun ti ẹ ti gun yii, lẹyin igba naa ki Ọlọhun Ọba Allah o wa ba yin, wiwa iya lẹyin eleyi jẹ adehun ti yoo sẹlẹ, ti ko si iyemeji nibẹ, kii si se irọ, o si jẹ adehun ododo.
فَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا نَجَّيۡنَا صَٰلِحٗا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَمِنۡ خِزۡيِ يَوۡمِئِذٍۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ ٱلۡقَوِيُّ ٱلۡعَزِيزُ 66
Nigbati asẹ wa de lati pa wọn run, a la sọlihun ati awọn ti wọn nigbagbọ pẹlu rẹ pẹlu ikẹ lati ọdọ wa, a si la wọn kuro nibi iyẹpẹrẹ ọjọ naa ati irẹlẹ rẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ -ire ojise- ni alagbara, oniyi ti ẹnikẹni ko le bori Rẹ nitori eleyi ni o fi pa awọn ijọ opurọ run.
وَأَخَذَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ ٱلصَّيۡحَةُ فَأَصۡبَحُواْ فِي دِيَٰرِهِمۡ جَٰثِمِينَ 67
Ohun lile ti o le pani run si gba ijọ samudawa mu, wọn si ku nitori lilekoko rẹ, wọn di ẹniti o da oju bolẹ, ti oju wọn ti yi mọ yerupẹ.
كَأَن لَّمۡ يَغۡنَوۡاْ فِيهَآۗ أَلَآ إِنَّ ثَمُودَاْ كَفَرُواْ رَبَّهُمۡۗ أَلَا بُعۡدٗا لِّثَمُودَ 68
Gẹgẹ bi ẹni pe ẹnikankan ko si ninu idẹkun ati irọra isẹmin ni ilu wọn, ẹ tẹti gbọ, dajudaju ijọ samudawa se keferi si ijọ wọn, wọn ko nii yẹ ni olujina si ikẹ Allah.
وَلَقَدۡ جَآءَتۡ رُسُلُنَآ إِبۡرَٰهِيمَ بِٱلۡبُشۡرَىٰ قَالُواْ سَلَٰمٗاۖ قَالَ سَلَٰمٞۖ فَمَا لَبِثَ أَن جَآءَ بِعِجۡلٍ حَنِيذٖ 69
Awọn Malaika ti wa ni aworan awọn ọkunrin lọ si ọdọ Ibrahimn ẹniti ọla nbẹ fun, ni olufun ni iro idunnu fun un ati fun iyawo rẹ lori Ishaaq lẹyin naa ni yaakub, awọn malaika waa sọ wipe: alaafia, ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun si fesi wipe: alaafia, o si lọ ni yarayara, o si mu ẹran ti a yan wa; ki wọn le jẹ nibẹ nitori wipe o ka wọn kun ọkunrin.
فَلَمَّا رَءَآ أَيۡدِيَهُمۡ لَا تَصِلُ إِلَيۡهِ نَكِرَهُمۡ وَأَوۡجَسَ مِنۡهُمۡ خِيفَةٗۚ قَالُواْ لَا تَخَفۡ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمِ لُوطٖ 70
Nigbati Ibrahim ri wipe ọwọ wọn ko le de ibi ẹran naa, ati wipe wọn ko jẹ nibẹ, o se eemọ eleyi ni ara wọn, o wa fi ipaya pamọ si inu ẹmin rẹ, sugbọn nigbati awọn Malaika ri ipaya wọn lọdọ rẹ, wọn sọ wipe: mase bẹru wa, awa jẹ ẹniti Ọlọhun Ọba Allah gbe dide si ijẹ Luth, ki a le fi iya jẹ wọn.
وَٱمۡرَأَتُهُۥ قَآئِمَةٞ فَضَحِكَتۡ فَبَشَّرۡنَٰهَا بِإِسۡحَٰقَ وَمِن وَرَآءِ إِسۡحَٰقَ يَعۡقُوبَ 71
Obinrin ibrahim tii se (Saarata) wa lori iduro, a wa fun niro nkan ti yoo dun mọ ninu, ohun naa si ni wipe yoo bi Ishaaq, ti ọmọ ti orukọ rẹ njẹ Ya'quub yoo si maa bẹ fun Ishaaq naa, o waa rẹrin, o si dunnu pẹlu ohun ti o gbọ.
Orikunkun ati sise igberaga awọn ẹlẹbọ nigbati wọn ko ba nigbagbọ si amin sọlihu ẹniti ọla nbẹ fun, o jẹ ninu awọn amin ti o tobi ju.
Ninifẹ si fifun olugbagbọ ododo niro oun ti yoo loore fun un.
Sise lofin sisalamọ fun ẹniti o ba wọle ti ẹnikeji rẹ ati jijẹ ọranyan didahun pada.
Jijẹ dandan sise apọnle alejo.