يَحۡلِفُونَ بِٱللَّهِ لَكُمۡ لِيُرۡضُوكُمۡ وَٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥٓ أَحَقُّ أَن يُرۡضُوهُ إِن كَانُواْ مُؤۡمِنِينَ 62
Awọn sọbẹ selu yoo maa fi Ọlọhun Ọba Allah bura fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - wipe awọn ko sọ nkankan ti o le suta ba Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, eleyi jẹ wọn le ba yọ yin ninu, Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ ni o lọla ki a maa wa iyọnu Rẹ pẹlu nini igbagbọ ati sise isẹẹre, ti awọn eniyan wọnyi ba jẹ olugbagbọ ododo tootọ.
أَلَمۡ يَعۡلَمُوٓاْ أَنَّهُۥ مَن يُحَادِدِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَأَنَّ لَهُۥ نَارَ جَهَنَّمَ خَٰلِدٗا فِيهَاۚ ذَٰلِكَ ٱلۡخِزۡيُ ٱلۡعَظِيمُ 63
Se awọn sọbẹ selu yii ko wa mọ ni wipe ohun ti awọn nse yii jẹ imu Ọlọhun Ọba Allah ni ọta ati ojisẹ Rẹ, ati wipe ẹniti o ba nba awọn mejeeji sọta yoo wọ inu ina jahanamọ ni ọjọ igbende, wọn yoo maa gbe ibẹ lọ gbere?! Eleyi ni iyẹpẹrẹ ti o tobi julọ lọ.
يَحۡذَرُ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ أَن تُنَزَّلَ عَلَيۡهِمۡ سُورَةٞ تُنَبِّئُهُم بِمَا فِي قُلُوبِهِمۡۚ قُلِ ٱسۡتَهۡزِءُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ مُخۡرِجٞ مَّا تَحۡذَرُونَ 64
Awọn sọbẹselu npaya ki Ọlọhun Ọba Allah ma sọ suura kan kalẹ fun ojisẹ Rẹ, ti yoo mu awọn olugbagbọ ododo ri keferi ti o wa ninu ọkan wọn, sọ wipe -irẹ ojisẹ - tẹ siwaju - ẹyin sọbẹselu - lori yẹyẹ yin ati fifi ẹnu egan kan ẹsin, Ọlọhun Ọba Allah yoo mu jade oun ti ẹ nfi pamọ nipa sisọ suura kalẹ tabi fifun ojisẹ Rẹ niro nipa eleyi.
وَلَئِن سَأَلۡتَهُمۡ لَيَقُولُنَّ إِنَّمَا كُنَّا نَخُوضُ وَنَلۡعَبُۚ قُلۡ أَبِٱللَّهِ وَءَايَٰتِهِۦ وَرَسُولِهِۦ كُنتُمۡ تَسۡتَهۡزِءُونَ 65
Ti o ba beere - ire ojise - lọwọ awọn sọbẹ selu nipa nkan ti wọn nsọ bii fifi ẹnu agan ati bibu awọn olugbagbọ ododo lẹyin igbati Ọlọhun Ọba Allah ti mu iro wa fun ọ lori rẹ, wọn yoo maa sọ wipe: a nse awada ni, kii se ohun ti a gbero tọkan tọkan, sọ wipe - ire ojise -: se Allah ati awọn aayah Rẹ ati ojisẹ Rẹ ni ẹ fi nse yẹyẹ?!
لَا تَعۡتَذِرُواْ قَدۡ كَفَرۡتُم بَعۡدَ إِيمَٰنِكُمۡۚ إِن نَّعۡفُ عَن طَآئِفَةٖ مِّنكُمۡ نُعَذِّبۡ طَآئِفَةَۢ بِأَنَّهُمۡ كَانُواْ مُجۡرِمِينَ 66
Ẹ mase wi awijare irọ yii, ẹ ti se afihan keferi pẹlu sise yẹyẹ yin lẹyin igbati ẹ ti ipamọ rẹ sinu ọkan, ti a ba se amojukuro fun apakan ninu yin nitori wipe o gbe sọbẹ selu ju silẹ ati ironu piwada rẹ ati isafọmọ rẹ fun Ọlọhun Ọba Allah, bẹẹ ni a o fi iya jẹ awọn miran ninu yin nitori titaku wọn lori sọbẹ selu ati aironu piwada kuro nibẹ.
ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلۡمُنَٰفِقَٰتُ بَعۡضُهُم مِّنۢ بَعۡضٖۚ يَأۡمُرُونَ بِٱلۡمُنكَرِ وَيَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمَعۡرُوفِ وَيَقۡبِضُونَ أَيۡدِيَهُمۡۚ نَسُواْ ٱللَّهَ فَنَسِيَهُمۡۚ إِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ 67
Awọn sọbẹ selu ọkunrin ni tabi obinrin ni wọn jẹ ẹniti o dọgba nibi sọbẹ selu wọn, wọn si jẹ ẹniti o ntako awọn olugbagbọ ododo, wọn ma npasẹ ohun ti ko tọ, wọn si ma nkọ ohun ti o dara, wọn se ahun pẹlu dukia wọn, wọn kii na si oju ọna ti Allah, wọn fi Ọlọhun Ọba silẹ wọn ko tẹ le E, Ọlọhun Ọba Allah na si gbe wọn ju silẹ nibi kongẹ rẹ, dajudaju awọn sọbẹ selu ni ẹniti o jade kuro nibi itẹle ti Allah ati oju ọna ododo lọ si ibi ẹsẹ rẹ ati oju ọna anu.
وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقَٰتِ وَٱلۡكُفَّارَ نَارَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ هِيَ حَسۡبُهُمۡۚ وَلَعَنَهُمُ ٱللَّهُۖ وَلَهُمۡ عَذَابٞ مُّقِيمٞ 68
Ọlọhun Ọba Allah se adehun fun awọn sọbẹ selu ati awọn keferi ti wọn ko ronu piwada wipe Oun yoo fi wọn wọ inu ina jahanamọ ni ẹniti yoo maa gbe ibẹ lọ gbere, yoo si ta wọn lọrẹ ijiya, Ọlọhun Ọba Allah yoo si le wọn kuro nibi ikẹ Rẹ, iya onitẹsiwaju yoo si maa bẹ fun wọn.
Aburu awọn sọbẹ selu pọ ninu rẹ ni gbigba waju nibi igbagbọ irọ ati biba Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ se ọta, ati fifi Alukuraani se yẹyẹ ati anọbi ati olugbagbọ ododo ati bibẹru ki suura kan ninu alukuraani ma sọkalẹ ti yoo da yẹyẹ isesi wọn silẹ, ati wiwi awijare wọn wipe awọn nse awada ati ere ni eyiti i se fifi ẹsẹ rinlẹ koda jẹ awijare ti o buru ju ẹsẹ lọ.
Wọn ko tẹwọgba fifi ẹsin sere ati awọn idajọ rẹ, wọn si ka titẹri sibi ibajẹ nibi tira Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ sise keferi.
Sise sọbẹselu: jẹ aarẹ alọmọda ti o ti gbilẹ ninu ara, awọn ti o ba si ni aarẹ yi lara ma njọ ara wọn ni gbogbo igba ati asiko nibi mima pasẹ ohun ti ko tọ ati kikọ ohun ti o dara, ati kika ọwọ wọn ro, ati didi ọwọ lati ma se na nkan si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah fun igbiyanju ati nibi ohun ti o lẹtọ.
Ẹsan yoo maa jẹ iran isẹ ti a ba se, ẹniti o ba gbe asẹ Ọlọhun Ọba ju silẹ, ti o si nse nkan ti a kọ, Ọlọhun Ọba yoo gbe ju silẹ nibi ikẹ Rẹ.