وَإِن يُرِيدُوٓاْ أَن يَخۡدَعُوكَ فَإِنَّ حَسۡبَكَ ٱللَّهُۚ هُوَ ٱلَّذِيٓ أَيَّدَكَ بِنَصۡرِهِۦ وَبِٱلۡمُؤۡمِنِينَ 62
Ti o ba ja si wipe jijupa jusẹ silẹ wọn sibi atunse ati aijagun jẹ erongba lati tan ọ jẹ - ire ojise - ki wọn o le mura lati pa ọ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah yoo to ọ nibi ete wọn ati itanjẹ wọn, Oun ni O fi aranse Rẹ gbe ọ ro, o si tun fi sise aranse fun awọn olugbagbọ ododo si ọ ninu awọn onirin-ajo ati alaranse gbe ọ ro.
وَأَلَّفَ بَيۡنَ قُلُوبِهِمۡۚ لَوۡ أَنفَقۡتَ مَا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا مَّآ أَلَّفۡتَ بَيۡنَ قُلُوبِهِمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ أَلَّفَ بَيۡنَهُمۡۚ إِنَّهُۥ عَزِيزٌ حَكِيمٞ 63
O si da ọkan awọn olugbagbọ ododo pọ, awọn ti o fi se aranse fun lẹyin kigbati wọn ti pin yẹlẹ-yẹlẹ, ti o ba na gbogbo ohun ti o nbẹ ni ori ilẹ lati pa ẹmin wọn ti o ti pin yẹlẹ-yẹlẹ pọ, iwọ ko le e ko jọ sugbọn Ọlọhun Ọba Allah nikan soso ni o koo jọ, dajudaju Oun jẹ alagbara nibi ọla Rẹ, ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi ipebubu Rẹ ati iseto ati ofin Rẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ حَسۡبُكَ ٱللَّهُ وَمَنِ ٱتَّبَعَكَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 64
Irẹ Anọbi, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah yoo to ọ kuro nibi aburu awọn ọta rẹ, yoo to awọn olugbagbọ ododo ti wọn wa pẹlu rẹ, gbẹkẹ le Ọlọhun Ọba Allah, ki o si gbara le.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ حَرِّضِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ عَلَى ٱلۡقِتَالِۚ إِن يَكُن مِّنكُمۡ عِشۡرُونَ صَٰبِرُونَ يَغۡلِبُواْ مِاْئَتَيۡنِۚ وَإِن يَكُن مِّنكُم مِّاْئَةٞ يَغۡلِبُوٓاْ أَلۡفٗا مِّنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِأَنَّهُمۡ قَوۡمٞ لَّا يَفۡقَهُونَ 65
Irẹ Anọbi, gbẹ awọn olugbagbọ ododo ni ongbẹ ogun jija, se wọn loju kokoro lori ohun ti yoo mu agbara ba awọn ipinnu wọn, ti yoo si mu idasasa ba awọn erongba wọn, ti o ba wa ninu yin - ẹyin olugbagbọ ododo - ogun onisuuru lati ba keferi ja, wọn yoo maa bori ọgọrun meji ninu awọn keferi, ti ọgọrun onisuuru ba wa ninu yin, wọn yoo maa bori ẹgbẹrun ninu awọn keferi nitori wipe dajudaju awọn keferi jẹ ẹniti ko gbọ isesi Ọlọhun Ọba Allah ye lori sise aranse fun awọn ẹni tiRẹ, ati wiwọ awọn ọta Rẹ nilẹ, wọn ko si mọ erongba ogun jija, wọn jagun nitori giga ni ile aye ni.
ٱلۡـَٰٔنَ خَفَّفَ ٱللَّهُ عَنكُمۡ وَعَلِمَ أَنَّ فِيكُمۡ ضَعۡفٗاۚ فَإِن يَكُن مِّنكُم مِّاْئَةٞ صَابِرَةٞ يَغۡلِبُواْ مِاْئَتَيۡنِۚ وَإِن يَكُن مِّنكُمۡ أَلۡفٞ يَغۡلِبُوٓاْ أَلۡفَيۡنِ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ مَعَ ٱلصَّٰبِرِينَ 66
Ni sinsin yi Ọlọhun Ọba Allah se fufuyẹ fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - nitori ọlẹ yin ti o han, o se fufuyẹ fun yin niti aanu lati ọdọ Rẹ si yin, O wa se ni dandan fun ẹnikan ninu ki o duro sinsin niwaju keferi meji dipo mẹwa ninu wọn, ti ọgọrun onisuuru ba wa ninu yin lati ba keferi ja, wọn yoo maa bori ọgọrun meji, ti ẹgbẹrun onisuuru ba wa ninu yin, wọn yoo maa bori ẹgbẹrun meji keferi pẹlu iyọnda Allah, Ọlọhun Ọba Allah wa pẹlu awọn onisuuru olugbagbọ ododo pẹlu ikunlọwọ ati aranse.
مَا كَانَ لِنَبِيٍّ أَن يَكُونَ لَهُۥٓ أَسۡرَىٰ حَتَّىٰ يُثۡخِنَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ تُرِيدُونَ عَرَضَ ٱلدُّنۡيَا وَٱللَّهُ يُرِيدُ ٱلۡأٓخِرَةَۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٞ 67
Ko tọ fun Anọbi ki o ni ẹru ninu awọn keferi, awọn ti wọn nba a ja titi ti wọn yoo fi pa pupọ ninu wọn; ki o le fi ibẹru si inu ọkan wọn titi ti wọn ko fi ni le sẹri si mima ba ja, ẹ ngbero - ẹyin olugbagbọ ododo - lati mu awọn ẹru badiru ni mimu ifidi, Ọlọhun Ọba si ngbero ọrun eyiti ẹ yoo ti ibẹ ri aranse ẹsin ati iyi ibẹ, Ọlọhun Ọba Allah jẹ abiyi nibi bibẹ Rẹ ati iroyin Rẹ ati ibori Rẹ, ẹnikẹni ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi ipebubu ati ofin Rẹ.
لَّوۡلَا كِتَٰبٞ مِّنَ ٱللَّهِ سَبَقَ لَمَسَّكُمۡ فِيمَآ أَخَذۡتُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ 68
Ti kii ba se iwe lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti o ti ofin rẹ ati ipebubu rẹ ti gbawaju wipe Oun se awọn ẹran ni ẹtọ fun yin, ti O si tun se lẹtọ fun yin ki ẹ fi ẹru se ifidi, iya ti o le koko ki ba sẹlẹ si yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba nitori ọrọ ti ẹ gba ati ifi ẹru di siwaju ki imisi too sọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba ti o le eleyi lẹtọ.
فَكُلُواْ مِمَّا غَنِمۡتُمۡ حَلَٰلٗا طَيِّبٗاۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 69
Ki ẹ maa jẹ - ẹyin olugbagbọ ododo - ninu ohun ti ẹ gba lọdọ awọn keferi ninu ọrọ toripe o jẹ ẹtọ fun yin, ki ẹ si tun paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu wipe ki ẹ maa tẹle awọn asẹ Rẹ, ki ẹ si maa jinna si awọn nkan ti O kọ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ olufi ori jin awọn ẹru Rẹ ninu awọn olugbagbọ ododo, o si tun jẹ onikẹ si wọn.
Adehun lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah fun awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo wa ninu awọn aayah naa pẹlu tito ati aranse lori awọn ọta.
Diduro sinsin niwaju ọta jẹ ọranyan fun awọn olugbafa ti ko si isẹsa nibẹ, ti nkan ti yoo se ni fufuyẹ ko ba si nibẹ fun wọn.
Ọlọhun Ọba Allah fẹ awọn ipo ti o ga fun awọn ẹru Rẹ, O si korira awọn nkan yẹpẹrẹ fun wọn tori bẹẹ ni O se se wọn loju kokoro lati wa ẹsan ti ọrun, ti yoo sẹku, ti yoo si maa wa gbere.
Sise anfaani pẹlu awọn ẹru tabi sise iregun le wọn lori latara titu wọn silẹ ko le sẹlẹ ayaafi lẹyin igbati ti ibori ba pe ati ijẹgaba lori awọn ọta, ati sise afihan ibẹru isejọba loju awọn miran.