Nigbati Allah sọ nipa igbayọnda nigbati a ba fẹẹ wọle, O tun sọ nipa igbayọnda ti a ba nlọ, o wa sọpe:
إِنَّمَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَإِذَا كَانُواْ مَعَهُۥ عَلَىٰٓ أَمۡرٖ جَامِعٖ لَّمۡ يَذۡهَبُواْ حَتَّىٰ يَسۡتَٔۡذِنُوهُۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَسۡتَٔۡذِنُونَكَ أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۚ فَإِذَا ٱسۡتَٔۡذَنُوكَ لِبَعۡضِ شَأۡنِهِمۡ فَأۡذَن لِّمَن شِئۡتَ مِنۡهُمۡ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُمُ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 62
Dajudaju olugbagbọ ododo ti wọn jẹ sootọ sootọ nipa igbagbọ wọn ni awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nigbagbọ ninu ojisẹ Rẹ, ti wọn ba si wa pẹlu Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun nibi ọrọ ti o ko wọn jọ, ti yoo se awọn olugbafa ni anfaani, wọn kii lọ titi ti wọn yoo fi gba iyọnda ni ọdọ rẹ lati maa lọ, dajudaju awọn ti wọn nbeere fun iyọnda nigbati wọn ba nlọ - irẹ ojisẹ - awọn wọnyi ni wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nigbagbọ ninu ojisẹ Rẹ niti tootọ, ti wọn ba beere iyọnda ni ọdọ rẹ fun apakan alamọri ọrọ wọn ti o kan wọn, yọnda fun ẹniti o ba wu ọ lati yọnda fun ninu wọn, ki o si ba wọn wa aforijin fun ẹsẹ wọn, dajudaju Allah jẹ alaforijin ẹsẹ fun ẹniti o ba sẹri pada ninu awọn ẹru Rẹ, O si tun jẹ onikẹ si wọn.
لَّا تَجۡعَلُواْ دُعَآءَ ٱلرَّسُولِ بَيۡنَكُمۡ كَدُعَآءِ بَعۡضِكُم بَعۡضٗاۚ قَدۡ يَعۡلَمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ يَتَسَلَّلُونَ مِنكُمۡ لِوَاذٗاۚ فَلۡيَحۡذَرِ ٱلَّذِينَ يُخَالِفُونَ عَنۡ أَمۡرِهِۦٓ أَن تُصِيبَهُمۡ فِتۡنَةٌ أَوۡ يُصِيبَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ 63
Ẹ maa pọn ojisẹ Allah le - ẹyin olugbagbọ ododo -, nigbati ẹ ba npe e, ẹ mase fi orukọ rẹ pe e gẹgẹ bi: irẹ Muhammad tabi orukọ baba rẹ: irẹ ọmọ Abdullah gẹgẹ bi apakan yin se ma nse fun apakan, sugbọn ki ẹ maa sọpe: irẹ ojisẹ Allah, irẹ Anọbi Allah, ti o ba si pe yin fun alamọri kan ti o kari, ẹ mase sọ ipepe rẹ yii di ipepe apakan si apakan nibi awọn alamọri ti o fuyẹ ni ọpọ igba, bikosepe ki ẹ yara sasa lọ si ibi jijẹpe rẹ, paapa Allah mọ awọn ti nlọ ninu yin laigba iyọnda, awọn ti wọn yapa asẹ ojisẹ Allah (ti ikẹ ati ọla nbẹ fun) yaa sọra ki adanwo ma baa sẹlẹ si wọn ati idaamun tabi ki iya inira ma ba kan wọn eyiti wọn ko nii le se suuru fun.
أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ قَدۡ يَعۡلَمُ مَآ أَنتُمۡ عَلَيۡهِ وَيَوۡمَ يُرۡجَعُونَ إِلَيۡهِ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُواْۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمُۢ 64
Ẹ tẹti ẹ gbọ, ohun ti nbẹ ni sanmọ ati ohun ti nbẹ ni ilẹ jẹ ti Allah nikan soso niti isẹda ati inikapa ati iseto, O mọ ohun ti ẹ nbẹ lori rẹ ninu isesi - ẹyin eniyan - nkankan ko pamọ fun Un ninu rẹ, ti o ba si di ọjọ igbende - nigbati wọn ba sẹri si ọdọ Rẹ fun ajinde lẹyin iku - yoo fun wọn niro ohun ti wọn se ninu isẹ ni ile aye, Allah si jẹ onimimọ si gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un ni sanmọ, bẹẹni ni ilẹ.
سورة (MAKIYYAH)
Aranse jẹ ti ojisẹ (ti ikẹ ati ọla nbẹ fun) ati ti Qur'an ati idaabo bo ise bi awọn ẹlẹbọ.
تَبَارَكَ ٱلَّذِي نَزَّلَ ٱلۡفُرۡقَانَ عَلَىٰ عَبۡدِهِۦ لِيَكُونَ لِلۡعَٰلَمِينَ نَذِيرًا 1
Oore ẹniti O sọ Alukuraani kalẹ tobi, o si pọ ki o le jẹ oluse onipinya laarin ododo ati irọ fun ẹru Rẹ ati ojisẹ Rẹ Muhammad ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun; ki o le jẹ ojisẹ si gbogbo abara meji nni eeyan ati alujannu, ki o si tun le jẹ oludẹru ba wọn kuro nibi iya Allah.
ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَمۡ يَتَّخِذۡ وَلَدٗا وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٞ فِي ٱلۡمُلۡكِ وَخَلَقَ كُلَّ شَيۡءٖ فَقَدَّرَهُۥ تَقۡدِيرٗا 2
Ẹniti o jasi wipe ikapa sanmọ ati ilẹ tiRẹ nikan nii se, ko si bimọ, bẹẹni ko si orogun fun nibi ọla Rẹ, O si da gbogbo nkan, o si se ondinwọn nibi isẹda Rẹ ni ibamun si ohun ti o se deede imọ Rẹ ati ọgbọn Rẹ niti sise odiwọn, gbogbo rẹ jẹ ohun ti o ba dọgba.
Ẹsin Islam jẹ ẹsin eto ati awọn ẹkọ, bẹẹni nibi lilo awọn ẹkọ wọnyi jẹ ibukun ati oore.
Ipo ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun peni lọ si ibi sise apọnle rẹ ati bibọwọ fun ju ẹniti o yatọ si lọ.
Ewu ti nbẹ nibi yiyapa ikọse Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
Rirọkirika ọla Allah ati imọ Rẹ si gbogbo nkan.