إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلنَّصَٰرَىٰ وَٱلصَّٰبِِٔينَ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَلَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ 62
Dajudaju ẹniti o ba ni igbagbọ ninu awọn ọmọlẹyin yii, bakanna ẹniti o ba ni igbagbọ ninu awọn ọmọlẹyin ti o ti kọja siwaju gbigbe Anọbi dide, bii Yahudi, Nasọọra ati oloosa, awọn ni apakan ninu awọn ti wọn ntẹle awọn Anọbi, ẹniti o ba ni igbagbọ ododo si Ọlọhun Allah ati Ọjọ Ikẹyin, ẹsan wọn wa ni ọdọ Ọlọhun Ọba wọn, ko si ipaya nibi nkan ti wọn yoo ba pade ni Ọjọ Ikẹyin, wọn ko si nii banujẹ lori ohun ti o bọ mọ wọn lọwọ ni ile aye.
وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ وَرَفَعۡنَا فَوۡقَكُمُ ٱلطُّورَ خُذُواْ مَآ ءَاتَيۡنَٰكُم بِقُوَّةٖ وَٱذۡكُرُواْ مَا فِيهِ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ 63
Ẹ ranti adehun ti a kan pa mọ ti a bayin se, gẹgẹ bi igbagbọ ninu Ọlọhun Allah ati awọn ojisẹ Rẹ, A si gbe oke leyin lori ni ipaya fun yin, ati sise ikilọ nibi adehun ti ẹ gbe ju silẹ, ni ẹniti npayin lasẹ ki ẹ gbamu ohun ti A sọkalẹ ninu Taoreeta pẹlu igbamu gidi ati igbiyanju laise atẹẹwọ tabi oroju, ẹ sọ nkan ti nbẹ nibẹ, ki ẹ si ronu sii, o seese latari eyi naa, ki ẹ sọra fun iya Ọlọhun Allah (ti ọla Rẹ ga) .
ثُمَّ تَوَلَّيۡتُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَۖ فَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ لَكُنتُم مِّنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ 64
ko wa lati ọdọ yin ju isẹri ati iyapa lọ, lẹyin igba ti ẹ se adehun ti a kanpa mọ leyin lori, ti kii baa se ọla Ọlọhun Ọba leyin lori pẹlu sise amoju kuro fun yin, ati ikẹ Rẹ pẹlu gbigba wiwa aforijin yin, ẹ ko ba wa ninu ẹni ofo pẹlu okunfa igunri ati ẹsẹ yin.
وَلَقَدۡ عَلِمۡتُمُ ٱلَّذِينَ ٱعۡتَدَوۡاْ مِنكُمۡ فِي ٱلسَّبۡتِ فَقُلۡنَا لَهُمۡ كُونُواْ قِرَدَةً خَٰسِِٔينَ 65
Paapaa julọ ẹ ti mọ iro awọn ti wọn ti siwaju yin ni mimọ, ti ko si iruju nibẹ, nibi kikọja ẹnu aala pẹlu didẹdẹ ni ọjọ abamẹta, eyiti wọn se didẹdẹ nibẹ ni eewọ fun yin, ẹ sọ di ẹtọ pẹlu didẹ àwọ̀n yin siwaju ọjọ abamẹta ati yiyọọ jade ni ọjọ aiku, Ọlọhun Ọba wa sọ awọn elete yii di ọbọ ti nta kete ni ijiya fun ete wọn.
فَجَعَلۡنَٰهَا نَكَٰلٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهَا وَمَا خَلۡفَهَا وَمَوۡعِظَةٗ لِّلۡمُتَّقِينَ 66
A wa sọ abule olukọja ẹnu aala yii di arikọgbọn fun awọn abule ti wọn wa ni agbegbe tabi ayika rẹ, ati arikọgbọn fun awọn ti wọn nbọ lẹyin rẹ; ti ko fi nii se iru isẹẹ rẹ, ti yoo fi wa lẹtọ si iya Rẹ. A si se ariwoye fun awọn olubẹru Ọlọhun, awọn ti wọn npaya Ọlọhun Ọba ati igbẹsan Rẹ lara ẹni ti o ba kọja ẹnu aala.
وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَأۡمُرُكُمۡ أَن تَذۡبَحُواْ بَقَرَةٗۖ قَالُوٓاْ أَتَتَّخِذُنَا هُزُوٗاۖ قَالَ أَعُوذُ بِٱللَّهِ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ 67
Ẹ tun ranti ninu iro awọn ti wọn ti siwaju yin, oun ti o sele laarin wọn ati Anọbi Musa: nigbati o nfun won niro nipa ase ti Olohun Oba pa fun won wipe ki won du maalu kan ninu awon maalu. Kaka ki won yara se, n se niwon so ni eniti o mu ni yeye! Anabi Musa sope: mo fi Olohun wa iso kuro lati mo wa ninu awon ti npe Olohun niro, ti won si nfi awon eeyan se yeye.
قَالُواْ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا هِيَۚ قَالَ إِنَّهُۥ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٞ لَّا فَارِضٞ وَلَا بِكۡرٌ عَوَانُۢ بَيۡنَ ذَٰلِكَۖ فَٱفۡعَلُواْ مَا تُؤۡمَرُونَ 68
Wọn sọ fun Muusa (ki ọla Ọlọhun maa ba) pe: bawa bẹ Ọlọhun Ọba rẹ titi yoo fi salaye iroyin maalu ti o pawa lasẹ ki adu, Anọbi Muusa (ki ọla Ọlọhun maa ba) wa sọ fun wọn pe: dajudaju Ọlọhun Ọba sọpe: maalu kan ni ti ko tobi lọjọori ti kosi kere, sugbọn ti o wa ni iwọntunwọnsi, ki ẹ taratara mu asẹ Ọlọhun Ọba yin sẹ .
قَالُواْ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا لَوۡنُهَاۚ قَالَ إِنَّهُۥ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٞ صَفۡرَآءُ فَاقِعٞ لَّوۡنُهَا تَسُرُّ ٱلنَّٰظِرِينَ 69
Wọn tun tẹsiwaju nibi iyan jija wọn ati ifooro wọn ni ẹniti nsọ fun Musa ẹniti ọla nbẹ fun: bẹ Ọlọhun ọba rẹ ki o salaye awọ rẹ fun wa, Musa sọ fun wọn: dajudaju Allah sọpe: dajudaju o jẹ mọlu kan alawọ fẹsifẹsi ti fẹsifẹsi na di, ti o si njọ gbogbo ẹniti o nwo loju.
Idajọ ti wọn sọ nipa aayah akọkọ nipa ohun ti o ti siwaju nipa gbigbe Anọbi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba) dide, sugbọn lẹyin gbigbe Anọbi dide, dajudaju ẹsin ti Ọlọhun yọni si ni ẹsin Islam ti ko si nii gba ẹsin miran gẹgẹ bi Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) ti sọ wipe: (ẹni ti o ba wa ẹsin miran yatọ si Islam, wọn ko nii gba lọwọ rẹ) Suratul Al-Imran:85.(وَمَن يَبۡتَغِ غَيۡرَ ٱلۡإِسۡلَٰمِ دِينٗا فَلَن يُقۡبَلَ مِنۡهُ)
Paapaa julọ, Ọlọhun Ọba yoo kanju ijiya fun awọn ẹsẹ kan ni ile aye siwaju ọrun, ki o le baa jẹ iranti ti awọn eniyan yoo maa kiyesi, ti wọn yoo fi le sọra lati yapa asẹ Ọlọhun Allah (ti ọla Rẹ ga) .
dajudaju, ẹni ti o ba funlẹ mọ ara rẹ tabi ti o le koko mọ ẹmi ara rẹ nibi nkan ti ofin ẹsin gba laaye, iru ẹni bẹẹ le jẹ iya lori ilekoko rẹ.