أَلَآ إِنَّ أَوۡلِيَآءَ ٱللَّهِ لَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ 62
Ẹ tẹti ẹ gbọ, dajudaju awọn ẹni Ọlọhun Ọba ko si ipaya fun wọn nibi ohun ti wọn yoo ba pade nibi awọn nkan ipaya ọjọ igbende, wọn ko si ni banujẹ lori ohun ti o ba bọ mọ lọwọ ninu ipin aye.
ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ 63
Awọn eniyan aayo wọnyi ni ẹniti a royin pẹlu igbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, wọn si jẹ ẹniti o paya Allah nibi titẹle asẹ Rẹ ati jijinna si ohun ti O kọ.
لَهُمُ ٱلۡبُشۡرَىٰ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِۚ لَا تَبۡدِيلَ لِكَلِمَٰتِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 64
Iru idunnu nbẹ fun wọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba wọn ni ile aye pẹlu ohun ti yoo dun mọ wọn ninu bii ala rere ati ẹyin awọn eniyan fun wọn, iro idunnu si tun nbẹ fun wọn lati ọdọ awọn malaika nigbati wọn ba gba ẹmin wọn ati lẹyin iku ati nigba akojọ, ko si ayipada fun ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni adehun fun wọn, ẹsan eleyi ni ọla ti o tobi nitori titẹni lọwọ ohun ti a nfẹ ti o wa nibẹ, ati ọla kuro nibi ohun ti a nsa fun.
وَلَا يَحۡزُنكَ قَوۡلُهُمۡۘ إِنَّ ٱلۡعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًاۚ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 65
Mase banujẹ - irẹ ojisẹ - nitori ohun ti awọn eniyan wọnyi nsọ nibi ifẹnu ẹgbọn tabi eebu kan ẹsin rẹ, dajudaju ibori ati isẹgun gbogbo rẹ jẹ Ọlọhun Ọba Allah, nkankan ko ko agara ba A, Oun ni olugbọ gbogbo ọrọ wọn, onimimọ gbogbo isẹẹ wọn, Yoo si san wọn lẹsan le lori.
أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَمَا يَتَّبِعُ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ شُرَكَآءَۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَإِنۡ هُمۡ إِلَّا يَخۡرُصُونَ 66
Ẹ tẹti ẹ gbọ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nikan ni ẹniti o ni ohun ti nbẹ ni sanmọ, ti O si tun ni ohun ti nbẹ ninu ilẹ ati eyikeyi ohun ti awọn ẹlẹbọ ti wọn nsin nkan miran yatọ si Allah ntẹle?! Wọn ko tẹle nkankan niti ododo ayaafi iyemeji, wọn ko si jẹ ẹnikankan ju wọn parọ nibi sise afiti orogun ti si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, giga Ọlọhun Ọba kuro nibi gbolohun wọn ni giga ti o tobi.
هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِتَسۡكُنُواْ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبۡصِرًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَسۡمَعُونَ 67
Oun nikan ni nse fun yin - ẹyin eniyan - oru ki ẹ le ba maa sinmi kuro nibi idaamun ati wahala nibẹ, O si se ọsan fun yin ni itanmọlẹ ki ẹ le maa lọ maa bọ lati ri anfaani ti yoo wulo fun yin ninu isẹmin yin, dajudaju nibi eleyi awọn amin ti o fi oju han nbẹ nibẹ fun awọn ijọ ti wọn ngbọ ọrọ ni gbigbọ iwoye ati gbigba.
قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗاۗ سُبۡحَٰنَهُۥۖ هُوَ ٱلۡغَنِيُّۖ لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ إِنۡ عِندَكُم مِّن سُلۡطَٰنِۢ بِهَٰذَآۚ أَتَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ 68
Apakan ninu awọn ẹlẹbọ sọpe: Allah awọn malaika ni ọmọbinrin, mimọ kanga Allah nibi gbolohun wọn, Oun ti mimọ nbẹ fun ni ọlọrọ kuro nibi gbogbo ẹda Rẹ, Oun ni O ni ọla gbogbo ohun ti nbẹ ni sanmọ ati ọla gbogbo ohun ti nbẹ ni ilẹ, ko si lọdọ yin - ẹyin ẹlẹbọ - awijare lori gbolohun yin yii, se ẹyin yoo maa sọ gblohun ti o tobi nipa Ọlọhun Ọba Allah ni –nigbati ẹ wa nse afiti ọmọ si ọdọ Rẹ- ẹ ko mọ ododo dipo awijare gan?!
قُلۡ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ لَا يُفۡلِحُونَ 69
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ - dajudaju awọn ti wọn hun irọ mọ Ọlọhun Ọba latara sise afiti ọmọ si ọdọ Rẹ, wọn ko le jere nibi nkan ti wọn nwa yii, bẹẹ ni wọn ko le la kuro nibi nkan ti wọn nsaa fun.
مَتَٰعٞ فِي ٱلدُّنۡيَا ثُمَّ إِلَيۡنَا مَرۡجِعُهُمۡ ثُمَّ نُذِيقُهُمُ ٱلۡعَذَابَ ٱلشَّدِيدَ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ 70
Ki wọn mase gba itanjẹ pẹlu adun ile aye eyiti wọn ngbadun ati idẹkun rẹ, o jẹ adun kekere ti yoo yẹ lẹyin naa isẹri si wọn ni ọjọ igbende yoo jẹ ọdọ wa, lẹyin igba naa a o fi iya ti o lagbara jẹ wọn nitori keferi wọn si Allah ati irọ pipa wọn si ojisẹ Rẹ.
Atilẹyin Allah yoo jẹ fun ẹniti o ba nigbagbọ si I, ti o si tẹle awọn asẹ Rẹ, ti o tun jinna si awọn nkan ti o kọ, ti o si tẹle ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, awọn ẹni Ọlọhun Allah ni ẹni ifọkan balẹ ni ọjọ igbende, idunnu nbẹ fun wọn ni ile aye ninu ki o jẹ ala rere tabi ni igba iku.
Iyi ti Ọlọhun Ọba nikan soso ni lapapọ, Ohun ni ẹniti o ni ọla, ohun ti awọn eniyan bawa nsin yatọ si Allah ko si ododo fun un.
Iseni loju kokoro lori rironu nipa ẹda Allah; toripe eleyi ma ntini lọ si ibi nini igbagbọ si I ati mimu lọkan soso.
Jijẹ eewọ piparọ mọ Allah ti mimọ nbẹ fun ati wipe onirọ ko nii jere, ninu eyiti o si tobi ju ninu irọ ni fifi ọmọ si ọdọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun.