وَإِنَّهُۥ لَعِلۡمٞ لِّلسَّاعَةِ فَلَا تَمۡتَرُنَّ بِهَا وَٱتَّبِعُونِۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ 61
Ati wipe dajudaju Isa jẹ amin kan ninu awọn amin asiko ikẹyin ti o tobi ni igbati igbẹyin asiko ba sọkalẹ, ẹ mase se iyemeji si sisẹlẹ asiko igbẹyin igbẹyin, ẹ tẹle mi nibi ohun ti mo mu wa ba yin ni ọdọ Allah, eyiti mo mu wa ba yin ni ọna ti o duro tọ, ti ko si iwọgun nibẹ.
وَلَا يَصُدَّنَّكُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُۖ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ 62
Esu ko le yi yin kuro ni oju ọna ti o duro tọ pẹlu ifẹ inu rẹ ati itanjẹ rẹ, dajudaju o jẹ ọta eyiti o fi oju han fun yin.
وَلَمَّا جَآءَ عِيسَىٰ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ قَالَ قَدۡ جِئۡتُكُم بِٱلۡحِكۡمَةِ وَلِأُبَيِّنَ لَكُم بَعۡضَ ٱلَّذِي تَخۡتَلِفُونَ فِيهِۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 63
Nigbati Isa ẹniti ọla nbẹ fun mu ẹri ti o fi oju han wa awọn ijọ rẹ lori wipe oun jẹ ojisẹ, o sọ fun wọn: paapaa mo ti mu ọgbọn wa lati ọdọ Allah fun yin, ki nle salaye apakan ohun ti ẹ nse ifanfa si ninu ọrọ ẹsin yin fun yin, ki ẹ ya paya Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn ohun ti o kọ, ki ẹ si tẹle mi nibi ohun ti mo ba pa yin lasẹ rẹ, ti mo si nkọ fun yin kuro nibẹ.
إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ رَبِّي وَرَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ 64
Dajudaju Allah ni Ọlọhun mi ati yin, ko si lọhun kankan fun wa ju U lọ, ki ẹ ya se afọmọ ijọsin fun Un lohun nikan, imulọkan yii ni oju ọna ti o duro tọ ti ko si iwọgun nibẹ.
فَٱخۡتَلَفَ ٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَيۡنِهِمۡۖ فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡ عَذَابِ يَوۡمٍ أَلِيمٍ 65
Apakan ijọ Nasaarọ si yapa nibi ọrọ Isa; o wa ninu ẹniti o sọpe: Ọlọhun ni o jẹ ati ẹniti o sọpe: oun ni ọmọ Ọlọhun ati ẹniti o sọpe: oun ati iyọ rẹ ni ọlọhun meji, egbe ki o maa bẹ fun awọn alabosi fun ẹmin ara wọn - pẹlu iroyin ti wọn fi royin Isa nipa ijẹ ọmọ tabi oun jẹ ikẹta ẹta - kuro nibi iya inira ti nreti wọn ni ọjọ igbende.
هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا ٱلسَّاعَةَ أَن تَأۡتِيَهُم بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ 66
Se nkankan nreti awọn ti wọn jẹ oluyapa nibi ọrọ Isa wọnyi ju asiko ikẹyin ti yoo wa ba wọn lojiji ti wọn ko si nii fura mọ wiwa rẹ lọ bi?! Ti o ba de waa ba wọn, ti wọn si wa lori keferi wọn, dajudaju ibusẹrisi wọn jẹ iya inira.
ٱلۡأَخِلَّآءُ يَوۡمَئِذِۢ بَعۡضُهُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوٌّ إِلَّا ٱلۡمُتَّقِينَ 67
Awọn ọrẹ aayo ati awọn sootọ sootọ fun ra wọn lori keferi ati anu, apakan wọn jẹ ọta fun apakan ni ọjọ igbende ayaafi awọn olubẹru Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti O kọ, ibasepọ wọn yoo maa wa gbere ko nii ja.
يَٰعِبَادِ لَا خَوۡفٌ عَلَيۡكُمُ ٱلۡيَوۡمَ وَلَآ أَنتُمۡ تَحۡزَنُونَ 68
Allah yoo maa sọ fun wọn: ẹyin ẹru Mi, ko si ipaya fun yin loni nibi ohun ti ẹ ba ba pade, a ko si ni banujẹ ninu ohun ti o ba bọ mọ yin lọwọ ninu awọn ipin aye.
ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بَِٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ مُسۡلِمِينَ 69
Awọn ti o nigbagbọ ninu Alukuraani ti a sọkalẹ fun ojisẹ wọn, ti wọn si jẹ ẹniti o tẹriba fun Alukuraani naa; ti wọn nronu nipa awọn asẹ Rẹ, ti wọn si njawọ kuro nibi ohun ti O kọ.
ٱدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ أَنتُمۡ وَأَزۡوَٰجُكُمۡ تُحۡبَرُونَ 70
Ẹ maa wọ ọgba idẹra ẹyin ati apejuwe yin nibi igbagbọ, ki ẹ maa dunnu pẹlu ohun ti ẹ ba pade ninu idẹkun gbere eyiti ko nii tan, ti ko si nii ja.
يُطَافُ عَلَيۡهِم بِصِحَافٖ مِّن ذَهَبٖ وَأَكۡوَابٖۖ وَفِيهَا مَا تَشۡتَهِيهِ ٱلۡأَنفُسُ وَتَلَذُّ ٱلۡأَعۡيُنُۖ وَأَنتُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 71
Awọn oluse isẹsin wọn yoo maa gbe ife wura yi wọn ka ati awọn ife ti ko ni ideri, ohun ti ẹmin nfẹ si wa ninu ọgba idẹra naa ati ohun ti yoo maa dun mọ oju nibi riri rẹ, ẹyin naa yoo si maa wa nibẹ lailai, ti ẹ ko nii jade nibẹ rara.
وَتِلۡكَ ٱلۡجَنَّةُ ٱلَّتِيٓ أُورِثۡتُمُوهَا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 72
Ọgba idẹra eyiti wọn royin fun yin yii, ohun ni Allah yoo jogun fun yin lati ibi isẹ yin ni ọla lati ọdọ Rẹ.
لَكُمۡ فِيهَا فَٰكِهَةٞ كَثِيرَةٞ مِّنۡهَا تَأۡكُلُونَ 73
Ipapanu ti o pọ ti ko nii ja nbẹ fun yin nibẹ, ninu rẹ ni ẹ o si maa jẹ.
Sisọkalẹ Isa wa ninu awọn amin asiko ikẹyin ti o tobi.
Jija aayo poki ni ọjọ igbende ati lilo gbere aayo awọn olubẹru.
Iro idunnu Allah fun awọn olugbagbọ ododo ati fifi wọn lọkan balẹ lori ohun ti wọn fi role sẹyin ni ile aye ati nkan ti wọn yoo ba pade lọrun.