فَلَمَّا تَرَٰٓءَا ٱلۡجَمۡعَانِ قَالَ أَصۡحَٰبُ مُوسَىٰٓ إِنَّا لَمُدۡرَكُونَ 61
Nigbati fir'aona ati awọn ijọ rẹ pade pẹlu Musa ati awọn ijọ rẹ, ti o de ipo wipe ijọ abala kinni nri ijọ abala keji, awọn ijọ Musa sọ wipe: dajudaju fir'aona ati ijọ rẹ yoo le wa ba, ko si igbawaju fun wa le wọn lori.
قَالَ كَلَّآۖ إِنَّ مَعِيَ رَبِّي سَيَهۡدِينِ 62
Musa sọ fun awọn ijọ rẹ: ọrọ kii se bi ẹ se ro o; dajudaju Ọlọhun mi wa pẹlu mi pẹlu ikunlọwọ ati aranse, yoo tọ mi sọna, yoo si tọka oju ọna ọla fun mi.
فَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنِ ٱضۡرِب بِّعَصَاكَ ٱلۡبَحۡرَۖ فَٱنفَلَقَ فَكَانَ كُلُّ فِرۡقٖ كَٱلطَّوۡدِ ٱلۡعَظِيمِ 63
Awa ransẹ si Musa ni ẹniti o npaa lasẹ ki o fi ọpa rẹ lu odo, o si fi lu u, odo si lanu, bẹẹni o yi pada si ona mejila ni onka awọn idile ọmọ isirẹli, egige kọọkan ninu ipin omin naa si da gẹgẹ bi oke ti o tobi, nibi titobi rẹ ati fifi rinlẹ rẹ, ti omin ko si lee san nibẹ.
وَأَزۡلَفۡنَا ثَمَّ ٱلۡأٓخَرِينَ 64
A si sun fir'aona ati ijọ mọra titi wọn fi wọ inu odo ni ẹniti o nlero wipe oju ọna naa jẹ gbigba.
وَأَنجَيۡنَا مُوسَىٰ وَمَن مَّعَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ 65
A si la Musa ati awọn ti o wa pẹlu rẹ ninu ọmọ isirẹli, ti ẹnikankan ko parun ninu wọn.
ثُمَّ أَغۡرَقۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ 66
Lẹyin naa ni a pa fir'aona ati ijọ rẹ run pẹlu titẹ wọb ri si inu odod.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ 67
Dajudaju lilanu odo fun Musa ati lila a ati mimu iparun ba firiaon ati awọn ijọ rẹ jẹ amin kan ti o ntọka si ododo Musa, sugbọn ọpọ ninu awọn ti o wa pẹlu fir'aona kii se olugbagbọ ododo.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 68
Ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - jẹ alagbara eyiti o ma ngba ẹsan lara awọn ọta Rẹ, onikẹ fun ẹniti o ba ronu piwada ninu wọn.
وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ إِبۡرَٰهِيمَ 69
Ki o si ka fun wọn - irẹ ojisẹ - itan ibrahim.
إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦ مَا تَعۡبُدُونَ 70
Nigbati o sọ fun baba rẹ asara ati awọn ijọ rẹ, kinni ohun ti ẹ nsin yatọ si Allah?
قَالُواْ نَعۡبُدُ أَصۡنَامٗا فَنَظَلُّ لَهَا عَٰكِفِينَ 71
Awọn ijọ rẹ sọ fun: a nsin awọn ẹbọ, a si wa pẹlu wọn lori sinsin in ni ẹniti o ndunni mọ ọ.
قَالَ هَلۡ يَسۡمَعُونَكُمۡ إِذۡ تَدۡعُونَ 72
Ibrahim sọ fun wọn: njẹ awọn ẹbọ naa ngbọ ipepe yin nigbati ẹ ba pe wọn?
أَوۡ يَنفَعُونَكُمۡ أَوۡ يَضُرُّونَ 73
Tabi wọn nse yin ni anfaani ni igbati ẹ ba tẹle wọn, tabi wọn nkonira ba yin ti ẹ ba sẹ wọn bi?
قَالُواْ بَلۡ وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا كَذَٰلِكَ يَفۡعَلُونَ 74
Wọn sọ wipe: wọn kii gbọ wa ti a ba pe wọn, bẹẹni wọn kii se wa ni anfaani ti a ba tẹle wọn, wọn si kii fi ara niwa ti a ba sẹ wọn, ohun ti o sẹlẹ ni wipe awa ri awọn baba wa ti wọn nse bẹẹ, ni awa naa si nkọse wọn.
قَالَ أَفَرَءَيۡتُم مَّا كُنتُمۡ تَعۡبُدُونَ 75
Ibrahim sọpe: se ẹ ronu jinlẹ ni ẹ fi ri ohun ti ẹ nsin ni ẹbọ yatọ si Allah.
أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُمُ ٱلۡأَقۡدَمُونَ 76
Ati ohun ti awọn baba yin akọkọ nsin.
فَإِنَّهُمۡ عَدُوّٞ لِّيٓ إِلَّا رَبَّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 77
Dajudaju gbogbo wọn jẹ ọta fun mi; nitoripe dajudaju ibajẹ ni wọn ayaafi Allah ti O jẹ olutọju gbogbo ẹda lapapọ.
ٱلَّذِي خَلَقَنِي فَهُوَ يَهۡدِينِ 78
Eyiti o da mi; Oun ni O si ntọmi sọna rere aye ati ọrun.
وَٱلَّذِي هُوَ يُطۡعِمُنِي وَيَسۡقِينِ 79
Eyiti Oun nikan nfun mi ni ounjẹ nigbati ebi ba pa mi, o si nrẹmi ni ongbẹ nigbati ongbẹ ba gbẹ mi.
وَإِذَا مَرِضۡتُ فَهُوَ يَشۡفِينِ 80
Ti mo ba si saarẹ Oun nikan ni O nfun mi ni alaafia kuro nibi aarẹ naa, ko si olusewosan kankan fun mi yatọ si I.
وَٱلَّذِي يُمِيتُنِي ثُمَّ يُحۡيِينِ 81
Oun nikan si ni yoo pa mi nigbati asiko mi ba tan, yoo si ta mi ji ni ẹyin iku mi.
وَٱلَّذِيٓ أَطۡمَعُ أَن يَغۡفِرَ لِي خَطِيَٓٔتِي يَوۡمَ ٱلدِّينِ 82
Oun nikan si ni mo nrankan wipe ki O fi ori jinmi nibi asise mi ni ọjọ ẹsan.
رَبِّ هَبۡ لِي حُكۡمٗا وَأَلۡحِقۡنِي بِٱلصَّٰلِحِينَ 83
Ibrahim sọ ni ẹniti o npe Ọlọhun Ọba rẹ: Ọlọhun Ọba mi, fun mi ni agbọye ninu ẹsin; ki o si pa mi pọ mọ awọn ẹniire ninu awọn anọbi siwaju mi pẹlu ki o fi mi wọ sinu Alujannah pẹlu wọn.
Ọlọhun Ọba Allah wa pẹlu awọn ẹru Rẹ olugbagbọ ododo nibi aranse ati ikunlọwọ ati lila kuro nibi awọn ilekoko.
Ririnlẹ iroyin iyi ati ikẹ fun Allah ti O ga.
Ewu ikọse afọju.
Irankan olugbagbọ ododo ninu Ọlọhun Ọba rẹ jẹ ounti o tobi.