وَهُوَ ٱلَّذِي يَتَوَفَّىٰكُم بِٱلَّيۡلِ وَيَعۡلَمُ مَا جَرَحۡتُم بِٱلنَّهَارِ ثُمَّ يَبۡعَثُكُمۡ فِيهِ لِيُقۡضَىٰٓ أَجَلٞ مُّسَمّٗىۖ ثُمَّ إِلَيۡهِ مَرۡجِعُكُمۡ ثُمَّ يُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 60
Ọlọhun Ọba ni O ma ngba ẹmin yin nigbati ẹ ba sun ni igbẹmi fun asiko kan pato, Oun ni o si mọ nkan ti ẹ kojọ ni isẹ ni ọsan nigbati ẹ da pe, yoo tun wa gbe yin dide ni ọsan lẹyin ti O ti gba ẹmin yin ni oju oorun ki ẹ le ba dide si awọn isẹ yin titi ti asiko titan yin yoo fi to eyiti Ọlọhun Ọba Allah pebubu ni ọdọ Rẹ, lẹyin igbanaa ọdọ Rẹ nikan ni ibusẹri si yin lati gbeyin dide ni ọjọ igbende, lẹyin igba naa yoo fun yin ni iro nkan ti ẹ nse ninu isẹmi aye, yoo si san yin lẹsan le lori.
وَهُوَ ٱلۡقَاهِرُ فَوۡقَ عِبَادِهِۦۖ وَيُرۡسِلُ عَلَيۡكُمۡ حَفَظَةً حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَ أَحَدَكُمُ ٱلۡمَوۡتُ تَوَفَّتۡهُ رُسُلُنَا وَهُمۡ لَا يُفَرِّطُونَ 61
Ọlọhun Ọba Allah ni olubori awọn ẹru Rẹ; Oun ni ẹniti wọn yẹpẹrẹ ara wọn fun, O ga gu wọn lọ ni gbogbo ọna, Oun ni gbogbo nkan ntẹriba fun, O wa loke gbogbo ẹru Rẹ ni iwaloke ti o tọsi gbigbọngbọn Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun, O nfi ransẹ si yin - ẹyin eniyan - awọn Malaika ti o lapọnle, ti wọn ka isẹ ti ẹ nse titi ti asiko yin yoo fi tan pẹlu ki Malaika iku gba ẹmin yin, ati awọn olukunni lọwọ, wọn kii si gewọ ni kukuru ni ohun ti wọn ba pa wọn lasẹ.
ثُمَّ رُدُّوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ مَوۡلَىٰهُمُ ٱلۡحَقِّۚ أَلَا لَهُ ٱلۡحُكۡمُ وَهُوَ أَسۡرَعُ ٱلۡحَٰسِبِينَ 62
Lẹyin igba naa, wọn yoo da gbogbo ẹmin ti wọn ba gba pada si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti o ni wọn, Ọba ododo ki O le san wọn lẹsan lori isẹ wọn, ẹniti o ni idajọ ti o mu ati deedee laarin wọn, Oun ni O si yara ju ni ẹniti o le ka gbogbo onka isẹ yin.
قُلۡ مَن يُنَجِّيكُم مِّن ظُلُمَٰتِ ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِ تَدۡعُونَهُۥ تَضَرُّعٗا وَخُفۡيَةٗ لَّئِنۡ أَنجَىٰنَا مِنۡ هَٰذِهِۦ لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلشَّٰكِرِينَ 63
Sọ - ire ojise - fun awọn ọlọsẹbọ yii: taani o le yọ yin tabi la yin kuro nibi iparun eyiti ẹ ba nkan nibi okunkun ilẹ tabi omi? Ti ẹ npe E ni Oun nikan soso, ti ẹ yoo maa yẹpẹrẹ ara yin fun Un, ti ẹ yoo si maa fi ọkan balẹ siI lọdọ ni kọrọ ati ni gbangba: ti Ọlọhun Ọba wa ba la wa nibi awọn iparun yii, a o jẹ fun oludupẹ fun idẹra Rẹ le wa lori laini sin ẹlomiran ti O tayọ siI.
قُلِ ٱللَّهُ يُنَجِّيكُم مِّنۡهَا وَمِن كُلِّ كَرۡبٖ ثُمَّ أَنتُمۡ تُشۡرِكُونَ 64
Sọ fun wọn - ire ojise -: Ọlọhun Ọba Allah ni O le yọ yin nibẹ, Oun ni O si le la yin nibi ibanujẹ, sugbọn lẹyin igba naa ẹ tun nkan miran mọ Ọ ni, ni asiko idẹrun, abosi wo ni o to eyiti ẹ nse yii? !
قُلۡ هُوَ ٱلۡقَادِرُ عَلَىٰٓ أَن يَبۡعَثَ عَلَيۡكُمۡ عَذَابٗا مِّن فَوۡقِكُمۡ أَوۡ مِن تَحۡتِ أَرۡجُلِكُمۡ أَوۡ يَلۡبِسَكُمۡ شِيَعٗا وَيُذِيقَ بَعۡضَكُم بَأۡسَ بَعۡضٍۗ ٱنظُرۡ كَيۡفَ نُصَرِّفُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّهُمۡ يَفۡقَهُونَ 65
Sọ fun wọn - ire ojise -: Ọlọhun Ọba Allah nikan ni O lagbara lati fi iya ransẹ si yin lati oke yin bii okuta, igbe ati odo, tabi ki O mu wa fun yin ni isalẹ yin bii imititi, ilẹ riri, tabi ki O da ọkan yin ru, ti ẹnikọọkan yin yoo si maa tẹle ifẹ inu rẹ, ti apakan yin yoo si maa pa apakan, ronu - ire ojise - bi a se nmu ẹri wa ni oniranran fun wọn, a si nsalaye rẹ, ki wọn le gbọ agbọye ohun ti o mu wa lododo, ati wipe ohun ti o wa ni ọdọ wọn jẹ ibajẹ.
وَكَذَّبَ بِهِۦ قَوۡمُكَ وَهُوَ ٱلۡحَقُّۚ قُل لَّسۡتُ عَلَيۡكُم بِوَكِيلٖ 66
Awọn ijọ rẹ pe Alukuraani yii ni irọ, ohun si ni ododo eyiti iyemeji ko si nibi wiwa lati ọdọ Ọlọhun rẹ, sọ fun wọn - ire ojise -: emi kii sọ olusọ le yin lori, emi ko jẹ nkankan ju olukilọ fun yin lọ nibi iya Ọlọhun Ọba Allah ti o le koko.
لِّكُلِّ نَبَإٖ مُّسۡتَقَرّٞۚ وَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ 67
Gbogbo iro ni o ni asiko ti o ma nrinlẹ ati ibi ti yoo pari si, ninu iru rẹ ni iro wiwaa yin ati igbẹyin yin, ẹ yoo mọ eleyi nigbati wọn ba gbeyin dide ni ọjọ igbende.
وَإِذَا رَأَيۡتَ ٱلَّذِينَ يَخُوضُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا فَأَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ يَخُوضُواْ فِي حَدِيثٍ غَيۡرِهِۦۚ وَإِمَّا يُنسِيَنَّكَ ٱلشَّيۡطَٰنُ فَلَا تَقۡعُدۡ بَعۡدَ ٱلذِّكۡرَىٰ مَعَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ 68
Nigbati o ba ri - ire ojise - ti wọn sọrọ nipa awọn amin Wa pẹlu yẹyẹ ati awada, jinna si wọn ti wọn yoo fi bọ sinu ọrọ miran, ti ko si yẹyẹ ati awada nibẹ, ti esu ba mu ki o gbagbe ki o joko pẹlu wọn, lẹyin igba naa ni o wa ranti, yara fi aaye wọn silẹ, mase joko pẹlu awọn olukọja ẹnu aala yii.
Ifi rinlẹ wipe oorun jẹ iku ati wipe wọn ma gba ẹmin ninu rẹ, wọn yoo si da pada ni igba itaji.
Wiwa ẹri lori lilẹtọ si ẹniti a nsin fun Ọlọhun pẹlu ẹri adayeba nitori wipe awọn keferi nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga, wọn si ma nsẹri si isẹda wọn nigbati wọn ba ri inira, tabi wọn ko si ibi iparun, wọn yoo waa maa bẹ Ọlọhun Ọba Allah nikan soso ti ọla Rẹ ga.
Diduni mọ awọn ọlusẹbọ si iwa wọn ati mimu ẹri wa lori idori kodo adamọ wọn nitori wipe wọn ma nwa iranlọwọ lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nikan soso ni ori omi ni gba ilekoko, wọn si ma nmu nkan miran mọ Ọ nigbati O ba yọ wọn, ti O si la wọn de ori ilẹ.
Ailẹtọ jijoko si aaye ijoko awọn ẹni ibajẹ, ọlọrọ ibajẹ ati mima yapa wọn, bẹẹ ni mima sẹri si ọdọ wọn ayaafi igbati wọn ba jawọ kuro nibẹ.