Nigbati awọn ẹlẹbọ nwa awijare nipa titẹle ododo nitori ohun ti wọn ba pade nibi ilekoko ogun ati diduro owo sise Allah da wọn lohun pẹlu gbolohun Rẹ:
وَمَآ أُوتِيتُم مِّن شَيۡءٖ فَمَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتُهَاۚ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ 60
Ohun ti Ọlọhun Ọba yin ba fun yin, o wa ninu ohun ti ẹ fi ngbadun, ti ẹ si fi nse ẹsọ ninu isẹmin aye, lẹyin naa ti o wa tan, nkan ti o wa lọdọ Allah ninu ẹsan ti o tobi lọrun loore, yoo si sẹku ju ohun ti o wa ni ile aye lọ ninu igbadun ati ọsọ, se ẹ ko se laakaye eleyi ni, ti ẹ ko fi le gbe ọla fun ohun ti yoo sẹku lori ohun ti yoo tan?!
أَفَمَن وَعَدۡنَٰهُ وَعۡدًا حَسَنٗا فَهُوَ لَٰقِيهِ كَمَن مَّتَّعۡنَٰهُ مَتَٰعَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا ثُمَّ هُوَ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ مِنَ ٱلۡمُحۡضَرِينَ 61
Se ẹniti A se adehun Alujannah fun ni ọrun ati idẹkun gbere ti o wa nibẹ ti kosi ibuyẹ le da bi ẹniti a fun ni owo ati ọsọ ti o fi ngbadun ni isẹmin aye bi, lẹyin naa ti yoo tun wa wa ninu olupesẹ si inu ina jahannamọ ni ọjọ igbende?!
وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ فَيَقُولُ أَيۡنَ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تَزۡعُمُونَ 62
Ni ọjọ ti Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun yoo pe wọn ni ẹniti nsọ bayi wipe: ibo ni awọn akẹgbẹ mi wa, awọn ti ẹ nsin yatọ Mi, ti ẹ si lero wipe akẹgbẹ Mi ni wọn nse?
قَالَ ٱلَّذِينَ حَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ رَبَّنَا هَٰٓؤُلَآءِ ٱلَّذِينَ أَغۡوَيۡنَآ أَغۡوَيۡنَٰهُمۡ كَمَا غَوَيۡنَاۖ تَبَرَّأۡنَآ إِلَيۡكَۖ مَا كَانُوٓاْ إِيَّانَا يَعۡبُدُونَ 63
Awọn ti iya jẹ dandan le lori ninu awọn olupepe si keferi yoo sọpe: Ọlọhun wa o, awọn wọnyi ni awọn ti asọnu gẹgẹ bi a se sọnu, a tupa tusẹ lọsi ọdọ Rẹ kuro ni ọdọ wọn, wọn ko sin Wa, ounti wọn sin ni awọn esu.
وَقِيلَ ٱدۡعُواْ شُرَكَآءَكُمۡ فَدَعَوۡهُمۡ فَلَمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَهُمۡ وَرَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَۚ لَوۡ أَنَّهُمۡ كَانُواْ يَهۡتَدُونَ 64
Wọn sọ fun wọn: ẹ pe awọn akẹgbẹ yin ki wọn la yin ninu ohun ti ẹ ko si ninu iyẹpẹrẹ, wọn si pe awọn akẹgbẹ wọn, bẹẹni wọn ko jẹpe wọn, wọn nfi oju ri iya naa ti wọn ti pese fun wọn, wọn wa nnifẹ si ki awọn jẹ olumọna si ibi ododo nigbati wọn wa ni ile aye.
وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ فَيَقُولُ مَاذَآ أَجَبۡتُمُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 65
Ni ọjọ ti Ọlọhun wọn yoo pe wọn ni ẹniti o nsọ bayi pe: kinni ẹ fi da awọn ojisẹ mi lohun, awọn ti Mo gbe dide si yin?
فَعَمِيَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلۡأَنۢبَآءُ يَوۡمَئِذٖ فَهُمۡ لَا يَتَسَآءَلُونَ 66
Ohun ti wọn le fi se awijare pamọ fun wọn, wọn ko ranti nkankan, bẹẹni apakan wọn ko beere lọdọ apakan; nitori ipaya ojiji ti o de ba wọn, nitori amọdaju iya ti wọn mọ wipe yoo da fun wọn.
فَأَمَّا مَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَعَسَىٰٓ أَن يَكُونَ مِنَ ٱلۡمُفۡلِحِينَ 67
Sugbọn ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹlẹbọ kuro nibi keferi rẹ, ti o si nigbagbọ si Allah ati awọn ojisẹ Rẹ, ti o wa se isẹ rere, o seese ki o wa ninu ẹniti yoo jere pẹlu ohun ti wọn nfẹ, ẹniti yoo la kuro nibi ohun ti ndẹru ba wọn.
وَرَبُّكَ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُ وَيَخۡتَارُۗ مَا كَانَ لَهُمُ ٱلۡخِيَرَةُۚ سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ 68
Atipe Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - ma nda ohun ti O ba fẹ lati da, O si ma nsẹsa ẹniti o ba wu U fun titẹle asẹ Rẹ ati ijẹ anọbi Rẹ, ko si idanwo kankan fun awọn ẹlẹbọ titi wọn yoo fi gunri si Allah, Ẹniti mimọ nbẹ fun, ti O si mọ kanga kuro nibi ohun ti wọn nsin pẹlu Rẹ ninu akẹgbẹ.
وَرَبُّكَ يَعۡلَمُ مَا تُكِنُّ صُدُورُهُمۡ وَمَا يُعۡلِنُونَ 69
Atipe Ọlọhun Ọba rẹ ma ohun ti o pamọ ninu ọkan wọn ati ohun ti wọn se afihan rẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu rẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
وَهُوَ ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ لَهُ ٱلۡحَمۡدُ فِي ٱلۡأُولَىٰ وَٱلۡأٓخِرَةِۖ وَلَهُ ٱلۡحُكۡمُ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 70
Oun si ni Allah ti mimọ nbẹ fun ti ko si ẹniti ijọsin fun ododo yatọ si I, Oun nikan ni ọpẹ nbẹ fun laye, bẹẹni Oun nikan ni ọpẹ nbẹ fun lọrun, Oun ni idajọ imusẹ nbẹ fun eyiti idapada ko si fun, ọdọ Rẹ nikan si ni isẹrisi ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan.
Onilaakaye ni ẹniti o ma ngbọla fun ohun ti yoo sẹku lori ohun ti yoo tan.
Ironupiwada ma npa ohun ti o ti siwaju rẹ rẹ.
Ẹsa nbẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba, ko si fun awọn ẹru Rẹ, ko tọ fun ẹru Rẹ ki o sẹri kuro ni ọdọ Rẹ.
Kikari imọ Ọlọhun pẹlu ohun ti han ati ohun ti o pamọ ninu awọn isẹ ẹru Rẹ.