عَيۡنٗا يَشۡرَبُ بِهَا عِبَادُ ٱللَّهِ يُفَجِّرُونَهَا تَفۡجِيرٗا 6
Nkan mimu ti wọn pese fun awọn olutẹle asẹ jẹ ninu odo ti arọwọto rẹ rọrun, ti o si pọ, ti ko le gbẹ, ti awọn ẹru Allah yoo maa rẹngbẹ nibẹ, wọn yoo maa mu san ati mui lọ si ibi ti o ba wu wọn.
يُوفُونَ بِٱلنَّذۡرِ وَيَخَافُونَ يَوۡمٗا كَانَ شَرُّهُۥ مُسۡتَطِيرٗا 7
Awọn iroyin awọn ẹru ti o mu omin naa jẹ nitori mimu sẹ ohun ti wọn la bọ ẹmin ara wọn lọrun ninu itẹle asẹ, wọn si nbẹru ọjọ kan ti aburu rẹ fan ka, ti o si buru, ohun si ni ọjọ igbende.
وَيُطۡعِمُونَ ٱلطَّعَامَ عَلَىٰ حُبِّهِۦ مِسۡكِينٗا وَيَتِيمٗا وَأَسِيرًا 8
Wọn si nfun awọn eniyan ni ounjẹ pẹlu wipe awọn naa wa ni ipo ẹniti o nifẹ rẹ fun bukaata wọn, ti wọn si njẹran rẹ, wọn nfun awọn to ni bukaata si ninu awọn olosi ni ounjẹ ati awọn ọmọ orukan ati awọn ẹru.
إِنَّمَا نُطۡعِمُكُمۡ لِوَجۡهِ ٱللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنكُمۡ جَزَآءٗ وَلَا شُكُورًا 9
Wọn si nfi pamọ ninu ẹmin wọn wipe awọn ko fun wọn ni ounjẹ ayaafi nitori ti Allah, wọn ko gbero ẹsan lọdọ wọn tabi ẹyin lofi fifun wọn ni ounjẹ ti wọn fun wọn.
إِنَّا نَخَافُ مِن رَّبِّنَا يَوۡمًا عَبُوسٗا قَمۡطَرِيرٗا 10
Dajudaju awa nbẹru lọdọ Ọlọhun wa ọjọ kan ti oju awọn oloriburuku yoo kọlẹ nitori lile koko rẹ ati biburu rẹ.
فَوَقَىٰهُمُ ٱللَّهُ شَرَّ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمِ وَلَقَّىٰهُمۡ نَضۡرَةٗ وَسُرُورٗا 11
Allah yoo wa la wọn kuro nibi aburu ọjọ ti o tobi naa pẹlu ọla Rẹ, yoo si fun wọn ni itansan ati imọlẹ ni oju wọn; niti apọnle fun wọn ati idunnu si inu ọkan wọn.
وَجَزَىٰهُم بِمَا صَبَرُواْ جَنَّةٗ وَحَرِيرٗا 12
Allah yoo si san wọn lẹsan - nitori suuru wọn lori itẹle asẹ ati suuru wọn lori ebubu Ọlọhun ati suuru wọn lori awọn ẹsẹ - ni ọgba idẹra kan ti wọn yoo maa gbadun nibẹ ati asọ ariirii ti wọn yoo maa wọ.
مُّتَّكِِٔينَ فِيهَا عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِۖ لَا يَرَوۡنَ فِيهَا شَمۡسٗا وَلَا زَمۡهَرِيرٗا 13
Wọn yoo maa rọgbọkun lori awọn ibusun ti na se lọsọ, wọn ko nii ri oorun ti itansan rẹ yoo se wọn ni suta ni ọgba idẹra naa tabi itutu lile bikosepe wọn yoo maa wa ni abẹ iboji lailai ti ko si ooru pẹlu tabi otutu.
وَدَانِيَةً عَلَيۡهِمۡ ظِلَٰلُهَا وَذُلِّلَتۡ قُطُوفُهَا تَذۡلِيلٗا 14
Ooji ibẹ yoo sun mọ wọn, wọn yoo si rọ eeso ibẹ fun ẹniti o ba fẹẹ mu, yoo maa mu pẹlu irọrun ati irọra debi wipe ẹniti o dubulẹ yoo mu ati ẹniti o joko ati ẹniti o naro.
وَيُطَافُ عَلَيۡهِم بَِٔانِيَةٖ مِّن فِضَّةٖ وَأَكۡوَابٖ كَانَتۡ قَوَارِيرَا۠ 15
Awọn ọmọ ọdọ yoo maa yipo wọn pẹlu igba fadaka ati awọn ife ti awọ rẹ mọ nigbati wọn ba gbero ohun mimu.
قَوَارِيرَاْ مِن فِضَّةٖ قَدَّرُوهَا تَقۡدِيرٗا 16
Mimọ rẹ yoo da gẹgẹ bi digi biotilẹjẹsipe lati ibi fadaka ni, wọn yoo pebubu rẹ ni odinwọn ohun ti wọn nfẹ, ko nii lekun rẹ, bẹẹni ko nii dinku.
وَيُسۡقَوۡنَ فِيهَا كَأۡسٗا كَانَ مِزَاجُهَا زَنجَبِيلًا 17
Wọn yoo maa fun awọn ẹni apọnle yii ni ife kan ti ọti ti a ro papọ mọ ‘sanjabiila’ wa nibẹ.
عَيۡنٗا فِيهَا تُسَمَّىٰ سَلۡسَبِيلٗا 18
Wọn yoo maa mu ninu isẹlẹru ti wọn npe ni ‘salisabiila’ ninu ọgba idẹra naa.
۞وَيَطُوفُ عَلَيۡهِمۡ وِلۡدَٰنٞ مُّخَلَّدُونَ إِذَا رَأَيۡتَهُمۡ حَسِبۡتَهُمۡ لُؤۡلُؤٗا مَّنثُورٗا 19
Awọn ọmọ ti wọn wa lori ijọdọ wọn yoo maa yipo wọn ninu ọgba naa, ti o ba ri wọn, iwọ yoo lero pe aluhuluhu ti a fan ka ni wọn nitori titutu gbọdọ oju wọn ati didara awọ wọn ati pipọ wọn ati fifanka wọn.
وَإِذَا رَأَيۡتَ ثَمَّ رَأَيۡتَ نَعِيمٗا وَمُلۡكٗا كَبِيرًا 20
Nigbati o ba wo ohun ti o wa ni ọkankan, iwọ yoo ri idẹkun kan ti ko rọrun sisalaye ninu ọgba naa, iwọ yoo si tun ri ọla ti o tobi, ti ọla nkankan ko sun mọ ọ.
عَٰلِيَهُمۡ ثِيَابُ سُندُسٍ خُضۡرٞ وَإِسۡتَبۡرَقٞۖ وَحُلُّوٓاْ أَسَاوِرَ مِن فِضَّةٖ وَسَقَىٰهُمۡ رَبُّهُمۡ شَرَابٗا طَهُورًا 21
Paapaa asọ alawọ eweko alafiyanran ti o wa lati ara ariirii ti o wẹ, ti o nipọn ni lilẹ, yoo wa ni ara wọn, wọn si tun wọn wọn ni ẹgba ọrun lati inu fadaka, Allah yoo si fun wọn mu ni ohun mimu ti o mọ kuro nibi riru.
إِنَّ هَٰذَا كَانَ لَكُمۡ جَزَآءٗ وَكَانَ سَعۡيُكُم مَّشۡكُورًا 22
Wọn yoo sọ fun wọn niti sise apọnle fun wọn: dajudaju idẹkun yii eyiti a fun un jẹ ẹsan fun yin lori awọn isẹ yin rere, isẹ yin si jẹ itẹwọgba lọdọ Allah.
إِنَّا نَحۡنُ نَزَّلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡقُرۡءَانَ تَنزِيلٗا 23
Dajudaju Awa ni a sọ Alukuraani kalẹ fun ọ - irẹ ojisẹ - ni ẹyọẹyọ, a ko sọ ọ kalẹ fun ọ ni akojọpọ kan soso.
فَٱصۡبِرۡ لِحُكۡمِ رَبِّكَ وَلَا تُطِعۡ مِنۡهُمۡ ءَاثِمًا أَوۡ كَفُورٗا 24
Se suuru fun idajọ ti Allah ba se i ipebubu ni tabi ofin, masi se tẹle ẹlẹsẹ nibi ohun ti o npepe si ninu ẹsẹ, bẹẹni ki o ma tẹle keferi nibi ohun ti o npepe si ninu keferi.
وَٱذۡكُرِ ٱسۡمَ رَبِّكَ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلٗا 25
Si ranti Ọlọhun rẹ pẹlu irun idaji ni akọkọ ọsan ati irun ọsan ati irọlẹ ni igbẹyin rẹ.
Mimu ileri sẹ ati fifun onibukaata lounjẹ ati sise afọmọ nibi isẹ ati pipaya Allah: jẹ awọn okunfa ọla kuro nibi ina ati wiwọ ọgba idẹra naa.
Ti isesi awọn ọmọ keekeeke ti wọn nsisẹ sin wọn ninu ọgba idẹra ba jẹ pẹlu awọn iwa yii, bawo ni awọn ẹni ọgba idẹra naa yoo se ri?!