Nigbati Allah salaye idajọ ikọra ẹni silẹ ati igbara ẹni pada, o tun salaye idajọ inawo ati ibugbe, o wa sọpe:
أَسۡكِنُوهُنَّ مِنۡ حَيۡثُ سَكَنتُم مِّن وُجۡدِكُمۡ وَلَا تُضَآرُّوهُنَّ لِتُضَيِّقُواْ عَلَيۡهِنَّۚ وَإِن كُنَّ أُوْلَٰتِ حَمۡلٖ فَأَنفِقُواْ عَلَيۡهِنَّ حَتَّىٰ يَضَعۡنَ حَمۡلَهُنَّۚ فَإِنۡ أَرۡضَعۡنَ لَكُمۡ فََٔاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ وَأۡتَمِرُواْ بَيۡنَكُم بِمَعۡرُوفٖۖ وَإِن تَعَاسَرۡتُمۡ فَسَتُرۡضِعُ لَهُۥٓ أُخۡرَىٰ 6
Ẹ mu wọn gbe - ẹyin ọkọ - nibi ti ẹ ngbe ti ẹ nikapa, Allah ko nii la nkan miran bọ yin lọrun, ki ẹ si mase fi inira si inu inawo ati ibugbe, bẹẹni si bi nkan miran ti o yatọ si wọn, ni irankan ki ilẹ le fun wọn, ti awọn ẹ kọ silẹ ba jẹ oloyun, ki ẹ na owo fun wọn titi ti wọn yoo fi bi oyun inu wọn, ti wọn ba ba yin tọju awọn ọmọ yin, ki ẹ fun wọn ni owo ọya itọju ọmọ wọn, ki ẹ si sẹri si ibi ọrọ owo ọya naa pẹlu daadaa, ti ọkọ ba se ohun si ohun ti iyawo beere ni owo ọya, ti oun naa si se ahun, ti ko si yọnu ayaafi ohun ti nfẹ; ki baba yaa gba olutọju miran ti yoo ba tọju ọmọ rẹ.
لِيُنفِقۡ ذُو سَعَةٖ مِّن سَعَتِهِۦۖ وَمَن قُدِرَ عَلَيۡهِ رِزۡقُهُۥ فَلۡيُنفِقۡ مِمَّآ ءَاتَىٰهُ ٱللَّهُۚ لَا يُكَلِّفُ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِلَّا مَآ ءَاتَىٰهَاۚ سَيَجۡعَلُ ٱللَّهُ بَعۡدَ عُسۡرٖ يُسۡرٗا 7
Ẹniti igbaaye ninu yin ba nbẹ fun, ki o ya na lori ẹniti o kọ ati lori ọmọ rẹ bi o se pọ to, ẹniti wọn ba si funlẹ arisiki mọ ki o ya na ohun ti ninu ohun ti Allah fun un, Allah ko nii la bọ ẹmin kan lọrun ayaafi ohun ti O ba fun, ko le laa bọ lọrun kọja rẹ, bẹẹni ko le kọja ohun ti o nikapa, Allah yoo se igbaaye ati ọrọ lẹyin ifunpinpin isesi rẹ ati ilekoko rẹ.
Nigbati Allah sọ akojọ awọn asẹ, O se ikilọ kuro nibi igunri nibi awọn asẹ naa, O si se alaye wipe dajudaju igbẹyin rẹ jẹ aburu, O wa sọpe:
وَكَأَيِّن مِّن قَرۡيَةٍ عَتَتۡ عَنۡ أَمۡرِ رَبِّهَا وَرُسُلِهِۦ فَحَاسَبۡنَٰهَا حِسَابٗا شَدِيدٗا وَعَذَّبۡنَٰهَا عَذَابٗا نُّكۡرٗا 8
Ọpọ awọn abule ti o jasi pe ti o ba yapa asẹ Ọlọhun rẹ ti mimọ nbẹ fun ati asẹ awọn ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun gbogbo wọn; a o se isiro wọn ni isiro ti o nira lori awọn isẹ aburu wọn, a o si fi iya ti o gbona jẹ wọn ni aye ati ni ọrun.
فَذَاقَتۡ وَبَالَ أَمۡرِهَا وَكَانَ عَٰقِبَةُ أَمۡرِهَا خُسۡرًا 9
O tọ ijiya awọn isẹ aburu rẹ wo, igbẹyin rẹ si jẹ ofo ni ile aye ati ofo ni ọrun.
أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُمۡ عَذَابٗا شَدِيدٗاۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ قَدۡ أَنزَلَ ٱللَّهُ إِلَيۡكُمۡ ذِكۡرٗا 10
Allah pese iya ti o lagbara fun un, ki ẹ yaa bẹru Allah - ẹyin onilaakaye ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti ẹ si nigbagbọ si ojisẹ Rẹ - pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti wọn kọ, ki ohun ti o sẹlẹ si wọn ma ba sẹlẹ si yin, paapaa Allah ti sọ iranti kan kalẹ fun yin, ti yoo maa ran yin leti biburu igbẹyin iyapa Rẹ ati didara ibusẹrisi itẹle tiRẹ.
رَّسُولٗا يَتۡلُواْ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ مُبَيِّنَٰتٖ لِّيُخۡرِجَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ مِنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِۚ وَمَن يُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ وَيَعۡمَلۡ صَٰلِحٗا يُدۡخِلۡهُ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۖ قَدۡ أَحۡسَنَ ٱللَّهُ لَهُۥ رِزۡقًا 11
Iranti yii ni ojisẹ kan ni ọdọ Rẹ, ti o nka awọn amin Allh fun yin, ti o fi oju han, ti ko si irurju nibẹ; ni irankan lati mu awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si gba ojisẹ Rẹ lododo, ti wọn si nse awọn isẹẹre kuro ninu awọn okunkun anu lọsi imọlẹ imọna, ẹniti o ba nigbagbọ ninu Allah ti o si se isẹ rere, Allah mu wọ awọn ọgba idẹra ti akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ ti abẹ awọn igi rẹ ni ẹniti wọn yoo maa gbe ibẹ lọ lailai, paapaa Allah ti se arisiki ti o dara fun un nitoripe o mu wọ ọgba idẹra kan ti idẹkun rẹ ko nii ja.
ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ سَبۡعَ سَمَٰوَٰتٖ وَمِنَ ٱلۡأَرۡضِ مِثۡلَهُنَّۖ يَتَنَزَّلُ ٱلۡأَمۡرُ بَيۡنَهُنَّ لِتَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ وَأَنَّ ٱللَّهَ قَدۡ أَحَاطَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عِلۡمَۢا 12
Allah ni ẹniti o sẹda sanmọ mejeeji, O si sẹda ilẹ meje gẹgẹ bi isẹda Rẹ fun sanmọ mejeeje, asẹ Allah lori aye ati ofin ti o sọkalẹ laarin wọn; ni irankan ki ẹ le ma wipe dajudaju Allah lagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko le ko agara ba A ati wipe dajudaju Oun ti mimọ nbẹ jẹ ẹniti imọ Rẹ rọkirika gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un ni gbogbo sanmọ bẹẹni gbogbo ilẹ.
Aijẹ dandan ifuni lọyan lori oloyun nigbati wọn ba kọ ọ silẹ.
Lila nkan bọni lọrun ko gbọdọ jẹ ju ohun ti a lagbara lọ.
Nini igbagbọ si agbara Allah ati kikari imọ Rẹ si gbogbo nkan jẹ okunfa iyọnu ati ifọkanbalẹ ẹmin.