لَقَدۡ كَانَ لَكُمۡ فِيهِمۡ أُسۡوَةٌ حَسَنَةٞ لِّمَن كَانَ يَرۡجُواْ ٱللَّهَ وَٱلۡيَوۡمَ ٱلۡأٓخِرَۚ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ 6
Awokọse ti o dara yii jẹ ohun ti ẹniti o ba nrankan oore aye ati ọrun ni ọdọ Allah yoo maa kọse, ẹniti o ba si gunri kuro nibi awokọse ti o dara yii, dajudaju Allah rọrọ kuro ni ọdọ awọn ẹru Rẹ, ko ni bukaata si itẹle asẹ wọn, Oun ni ẹniti a ma ndupẹ fun lori gbogbo isesi.
۞عَسَى ٱللَّهُ أَن يَجۡعَلَ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَ ٱلَّذِينَ عَادَيۡتُم مِّنۡهُم مَّوَدَّةٗۚ وَٱللَّهُ قَدِيرٞۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 7
O seese ki Allah fi si aarin yin ifẹ - ẹyin olugbagbọ ododo - ati aarin awọn ẹniti ẹ nba se ọta ninu awọn keferi pẹlu ki Allah fi wọn mọ ọna ẹsin alaafia, ti wọn yoo wa pada jẹ ọmọ iyọ fun yin ninu ẹsin, Allah jẹ alagbara ti o nikapa lati yi ọkan wọn si ibi igbagbọ, Allah si tun jẹ alaforijin fun ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ, Onikẹ si wọn.
لَّا يَنۡهَىٰكُمُ ٱللَّهُ عَنِ ٱلَّذِينَ لَمۡ يُقَٰتِلُوكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَلَمۡ يُخۡرِجُوكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ أَن تَبَرُّوهُمۡ وَتُقۡسِطُوٓاْ إِلَيۡهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُقۡسِطِينَ 8
Allah ko kọ fun yin lati nipa awọn ti ko ba yin ja nitori ẹsin alaafia yin, ti wọn ko si mu yin jade kuro ni inu ile yin wipe ki ẹ se daadaa si wọn, ki ẹ si se deedee laarin wọn pẹlu ki ẹ fun wọn ni ẹtọ ti wọn ni le yin lori, dajudaju Allah nifẹ awọn onideede, ti wọn nse deede nipa ara wọn ati ara ile wọn ati ohun ti wọn ndari.
إِنَّمَا يَنۡهَىٰكُمُ ٱللَّهُ عَنِ ٱلَّذِينَ قَٰتَلُوكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَأَخۡرَجُوكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ وَظَٰهَرُواْ عَلَىٰٓ إِخۡرَاجِكُمۡ أَن تَوَلَّوۡهُمۡۚ وَمَن يَتَوَلَّهُمۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ 9
Dajudaju ohun ti Allah kọ fun yin ni awọn ti wọn ba yin ja nitori igbagbọ yin, ti wọn si mu yin jade kuro ninu ile yin, ti wọn si se ikunlọwọ lori mimu yin jade, o kọ fun yin ki ẹ fi ẹmin jin fun wọn, ẹniti o ba fi ẹmin jin fun wọn ninu yin, awọn wọnyi ni awọn alabosi si ẹmin ara wọn pẹlu mimu lọ si ibi iparun nitori yiyapa si asẹ Allah.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا جَآءَكُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتُ مُهَٰجِرَٰتٖ فَٱمۡتَحِنُوهُنَّۖ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِإِيمَٰنِهِنَّۖ فَإِنۡ عَلِمۡتُمُوهُنَّ مُؤۡمِنَٰتٖ فَلَا تَرۡجِعُوهُنَّ إِلَى ٱلۡكُفَّارِۖ لَا هُنَّ حِلّٞ لَّهُمۡ وَلَا هُمۡ يَحِلُّونَ لَهُنَّۖ وَءَاتُوهُم مَّآ أَنفَقُواْۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ أَن تَنكِحُوهُنَّ إِذَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّۚ وَلَا تُمۡسِكُواْ بِعِصَمِ ٱلۡكَوَافِرِ وَسَۡٔلُواْ مَآ أَنفَقۡتُمۡ وَلۡيَسَۡٔلُواْ مَآ أَنفَقُواْۚ ذَٰلِكُمۡ حُكۡمُ ٱللَّهِ يَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡۖ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ 10
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ si Allah ti ẹ si se ohun ti wọn se lofin, nigbati awọn olugbagbọ lobinrin ba wa ba yin, ti wọn jẹ oluse irin ajo kuro ni ilẹ keferi lọsi ilẹ alaafia, ẹ dan wọn wo nibi jijẹ ododo igbagbọ wọn, Allah ni ẹniti o nimọ ju nipa igbagbọ wọn, nkankan ko pamọ fun Un nibi ohun ti o ka jọ si inu ọkan wọn, ti ẹ ba wa mọ wọn si olugbagbọ ododo lobinrin lẹyin idanwo pẹlu ohun ti o han si yin ninu ijẹ ododo wọn, ẹ mase da wọn pada lọ si ọdọ awọn ọkọ wọn ti o jẹ keferi, ko tọ fun awọn olugbagbọ lobinrin ki wọn fẹ keferi, ko si tọ fun awọn keferi ki wọn fẹ awọn olugbagbọ ododo lobinrin, ki ẹ si fun awọn obinrin wọn ni ohun ti wọn nna ninu owo ori wọn, ko si si ẹsẹ fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo lobinrin - ki ẹ fẹ wọn lẹyin igbati nkan osu wọn ti pari nigbati ẹ ba ti fun wọn ni owo ori wọn, ẹniti iyawo rẹ ba jẹ keferi tabi o kuro ninu ẹsin alaafia, ko gbọdọ gba a; nitori jija ifẹra ẹni wọn pẹlu keferi rẹ, ki ẹ si beere lọwọ awọn keferi ohun ti ẹ na ni owo ori awọn iyawo yin ti wọn gunri kuro ninu ẹsin, ki awọn naa si beere ohun ti wọn na ni owo ori awọn iyawo wọn, awọn ẹniti o jupa jusẹ silẹ, awọn wọnyi ti a sọ yii - nipa dida owo ori pada ni abala ti yin ati abala ti wọn - ohun ni idajọ Allah, ti Oun ti mimọ nbẹ fun nse idajọ laarin yin bi o se fẹ, Allah si jẹ onimimọ nipa isesi awọn ẹru Rẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu rẹ, ọjọgbọn ni nibi ohun ti O ba se lofin fun awọn ẹru Rẹ.
وَإِن فَاتَكُمۡ شَيۡءٞ مِّنۡ أَزۡوَٰجِكُمۡ إِلَى ٱلۡكُفَّارِ فَعَاقَبۡتُمۡ فََٔاتُواْ ٱلَّذِينَ ذَهَبَتۡ أَزۡوَٰجُهُم مِّثۡلَ مَآ أَنفَقُواْۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِيٓ أَنتُم بِهِۦ مُؤۡمِنُونَ 11
Ti wọn ba se jijade apakan awọn obinrin yin lọ si ọdọ awọn keferi, ni ẹniti o ti gunri kuro ninu ẹsin, ti ẹ wa nwa ori ori wọn lọdọ awọn keferi, ti wọn ko si fun un, ti ẹ wa rọrọ lọdọ awọn keferi, ki ẹ ya fun awọn ọkọ ti awọn iyawo wọn ti jade ni ẹniti o ti gunri kuro ninu ẹsin ni iru ohun ti wọn na ninu owo ori, ki ẹ si paya Allah eyiti ẹ nigbagbọ si pẹlu mimu sẹ awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti o kọ.
Nibi ki Allah yi ọkan pada kuro ni ibasọta lọsi inifẹ ati kuro nibi keferi lọsi ibi igbagbọ jẹ amin wipe gbogbo ọkan awọn ẹru wa laarin ọmọnika meji ninu awọn ọmọnika Rẹ ti mimọ nbẹ fun, ki ẹru yaa beere irinlẹ lori igbagbọ lọdọ Rẹ.
Sise onpinya nibi idajọ laarin awọn keferi ẹni ọta ati awọn ti o jupa jusẹ silẹ.
Sise fifẹ awọn keferi binrin leewọ, ti kii se awọn onitira lati ipilẹ ati titi lọ lailai, ati sise leewọ ki awọn obinrin musulumi fẹ keferi lati ipilẹ ati titi lọ lailai.