خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ ثُمَّ جَعَلَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ ثَمَٰنِيَةَ أَزۡوَٰجٖۚ يَخۡلُقُكُمۡ فِي بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡ خَلۡقٗا مِّنۢ بَعۡدِ خَلۡقٖ فِي ظُلُمَٰتٖ ثَلَٰثٖۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ لَهُ ٱلۡمُلۡكُۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُصۡرَفُونَ 6
Ọlọhun yin da yin - ẹyin eniyan - lati inu ẹmin kan soso tii se Adamọ lẹyin naa O da lati ara Adamọ iyawo rẹ Hawau, O si da fun yin rakunmi ati maalu ati aguntan ati ewurẹ oniran mẹjọ, ninu iran kọọkan O da akọ ati abo, O mu yin bẹ ti mimọ nbẹ fun ninu iya yin ni ipele kan lẹyin ipele ninu awọn okunkun ikun, apo ibi ati inu, gbogbo eleyi ẹniti o da patapata ni Allah tii se Ọlọhun Ọba yin, Oun nikan ni O ni ọla, ko si ẹni ijọsin tọsi yatọ si I, bawi ni ẹ se wa nyi ijọsin Rẹ lọsi ijọsin ẹni ko le da nkankan, ti wọn si da wọn ni?!
إِن تَكۡفُرُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ عَنكُمۡۖ وَلَا يَرۡضَىٰ لِعِبَادِهِ ٱلۡكُفۡرَۖ وَإِن تَشۡكُرُواْ يَرۡضَهُ لَكُمۡۗ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُم مَّرۡجِعُكُمۡ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ 7
Ti ẹ ba se keferi - ẹyin eniyan - si Ọlọhun yin dajudaju Allah rọrọ kuro nibi igbagbọ yin, keferi yin ko le ko inira ba A bikosepe inira keferi yin yoo sẹri lọ si ọdọ yin, ko si nii yọnu si ki ẹru Rẹ se keferi pẹlu Rẹ, bẹẹni ko nii pa yin lasẹ keferi; nitoripe dajudaju Allah kii pasẹ ibajẹ ati ohun ti ko tọ, ti ẹ ba dupẹ lori awọn idẹkun Rẹ, ti ẹ si nigbagbọ si I, yoo yọnu si ọpẹ yin, yoo si san yin lẹsan le lori, ẹmin kan ko le gbe ẹsẹ ẹmin miran bikosepe gbogbo ẹmin ni a fi dogo pẹlu ohun ti o ba se, lẹyin naa ọdọ Ọlọhun yin ni ibusẹri si yin ni ọjọ igbende, yoo si fun yin niro nkan ti ẹ nse ni ile aye, yoo si san yin lẹsan lori awọn isẹ yin, dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun jẹ onimimọ nipa ohun ti o wa ni ọkan awọn ẹru Rẹ, nkankan ninu ohun ti nbẹ nibẹ ko pamọ fun Un.
۞وَإِذَا مَسَّ ٱلۡإِنسَٰنَ ضُرّٞ دَعَا رَبَّهُۥ مُنِيبًا إِلَيۡهِ ثُمَّ إِذَا خَوَّلَهُۥ نِعۡمَةٗ مِّنۡهُ نَسِيَ مَا كَانَ يَدۡعُوٓاْ إِلَيۡهِ مِن قَبۡلُ وَجَعَلَ لِلَّهِ أَندَادٗا لِّيُضِلَّ عَن سَبِيلِهِۦۚ قُلۡ تَمَتَّعۡ بِكُفۡرِكَ قَلِيلًا إِنَّكَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلنَّارِ 8
Ti inira kan ninu aarẹ tabi ipadanu dukia tabi ipaya itẹri ba sẹlẹ si keferi yoo pe Ọlọhun rẹ ti mimọ nbẹ fun ki o mu inira naa kuro niti sisẹri lọsi ọdọ Rẹ lohun nikan, lẹyin naa ti o ba fun un ni idẹkun kan pẹlu mimu inira naa eyiti o kan an kuro, yoo gbe ẹniti o nrawọ rasẹ si siwaju ju silẹ Oun si ni Allah, yoo wa mu awọn akẹgbẹ pẹlu Allah, ti yoo ma sin wọn yatọ si I, ki o le yi ẹlomiran kuro ni oju ọna Allah ti o le de ibẹ, sọ - irẹ ojisẹ - fun ẹniti eyi jẹ isesi rẹ: maa gbadun pẹlu keferi rẹ ninu eyiti o sẹku ninu ọjọ ori rẹ, o jẹ asiko ti o kere, dajudaju iwọ wa ninu ẹni ina ti yoo maa bẹ nibẹ ni ọjọ igbende ni ibarẹ ọrẹ si ọrẹ.
أَمَّنۡ هُوَ قَٰنِتٌ ءَانَآءَ ٱلَّيۡلِ سَاجِدٗا وَقَآئِمٗا يَحۡذَرُ ٱلۡأٓخِرَةَ وَيَرۡجُواْ رَحۡمَةَ رَبِّهِۦۗ قُلۡ هَلۡ يَسۡتَوِي ٱلَّذِينَ يَعۡلَمُونَ وَٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَۗ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ 9
Tabi ẹniti o ntẹle ti Allah, ti o si nlo awọn asiko oru rẹ ni iforikanlẹ fun Ọlọhun ati ni iduro fun Un ni o nbẹru iya ọrun, ti o si nrankan ikẹ Ọlọhun rẹ ni o loore tabi keferi naa ti o nsin Allah ni igba ile koko, ti o si nse aimoore si I ni igba irọrun, ti o tun awọn akẹgbẹ pẹlu Allah?! Sọ - irẹ ojisẹ -: njẹ awọn o nimọ ohun ti o jẹ ọranyan le wọn lori nitori imọ wọn nipa Allah dọgba pẹlu awọn eniyan ti ko mọ nkankan nipa eleyi?! Dajudaju ẹniti yoo maa yatọ laarin ipin mejeeji jẹ awọn onilaakaye ti o mọ.
قُلۡ يَٰعِبَادِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمۡۚ لِلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٞۗ وَأَرۡضُ ٱللَّهِ وَٰسِعَةٌۗ إِنَّمَا يُوَفَّى ٱلصَّٰبِرُونَ أَجۡرَهُم بِغَيۡرِ حِسَابٖ 10
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹru Mi ti wọn nigbagbọ nipa Mi ati awọn ojisẹ Mi: ẹ paya Ọlọhun yin pẹlu mima se awọn ofin Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, daadaa nbẹ fun awọn ti o se isẹ daadaa ninu yin ni ile aye nipa aranse ati alaafia ati dukia, ọgba idẹra si tun wa ni ọrun fun wọn, bẹẹni ilẹ Allah gbaaye, ẹ se irin ajo nibẹ ti ẹ o fi ri aaye lati sin Allah nibẹ, olukọdi kankan ko gbọdọ kọ di yin dajudaju ohun ti wọn ma nsan nisuuru lẹsan rẹ ni ọjọ igbende jẹ ohun ti ko see ka, bẹẹni ko ni odiwọn nitori pipọ rẹ ati oniranran rẹ.
Ireni Allah fun ọmọniyan ninu iya rẹ.
Rinrinlẹ iroyin ọrọ ati iyọnu fun Allah.
Mimọ Allah keferi ni igba inira ati sise aimo rẹ ni igba irọrun jẹ ẹri lori itẹsẹbọsẹ rẹ ati idaru dapọ rẹ.
Ipaya ati irankan jẹ iroyin meji ninu awọn iroyin ẹni igbagbọ.