وَعۡدَ ٱللَّهِۖ لَا يُخۡلِفُ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ 6
Aranse yii jẹ adehun lati ọdọ Allah ti O ga, Olohun Allah kosi ni yapa adehun Rẹ, pẹlu mimusẹ Rẹ ni awọn olugbagbọ ododo yoo fi ma lekun ni amodaju nipa adehun Allah pẹlu aranse, sugbọn ọpọ awọn eniyan ko le gbọ eleyi ye nitori keferi wọn.
يَعۡلَمُونَ ظَٰهِرٗا مِّنَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَهُمۡ عَنِ ٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ غَٰفِلُونَ 7
Wọn ko mọ igbagbọ ati awọn idajọ ofin, wọn kan nimọ nipa awọn ode isẹmin aye ti o sopọ mọ kiko nkan isẹmin jọ ati mimọ awọn nkan igbalode sugbọn awọn nipa ọrun eyitii se isẹmin tootọ jẹ olugunri, wọn kii gboju wobẹ.
أَوَ لَمۡ يَتَفَكَّرُواْ فِيٓ أَنفُسِهِمۗ مَّا خَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَأَجَلٖ مُّسَمّٗىۗ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِ بِلِقَآيِٕ رَبِّهِمۡ لَكَٰفِرُونَ 8
Se awọn ẹlẹbọ olupurọ yii ko wa ronu ni nipa ara wọn, bi Allah se da wọn, ti O si se ni dọgba, Allah ko da sanmọ tabi da ilẹ ayaafi pẹlu ododo, ko si da awọn mejeeji lasan, O si se ondinwọn asiko bibẹ wọn ni ile aye fun mejeeji, atipe dajudaju ọpọ ninu awọn eniyan jẹ alaimoore si pipade Ọlọhun Ọba wọn ni ọjọ igbende, tori eleyi, wọn ko mura silẹ fun igbende pẹlu isẹ rere ti yoo mu iyọnu wa lọdọ Ọlọhun Ọba wọn.
أَوَ لَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُوٓاْ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗ وَأَثَارُواْ ٱلۡأَرۡضَ وَعَمَرُوهَآ أَكۡثَرَ مِمَّا عَمَرُوهَا وَجَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِۖ فَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظۡلِمَهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ 9
Se awọn wọnyi ko rin lorilẹ ni, ki wọn le ronu si bi igbẹyin awọn ijọ opurọ ti wọn siwaju wọn se ri, awọn ijọ wọnyi jẹ alagbara ju wọn lọ, ti wọn si yilẹ pada fun nkan ọgbin ati ibugbe, wọn lo o ju bi awọn wọnyi se lo o lọ, awọn ojisẹ wọn si waa ba wọn pẹlu awọn awijare ati awọn ẹri ti o fi oju han lori ọkan soso Allah, wọn si pe e nirọ, Allah ko se abosi wọn nigbati O pa wọn run, sugbọn awọn ni wọn se abosi fun ẹmin ara wọn pẹlu mimu u lọ si ibi iparun nitori keferi wọn.
ثُمَّ كَانَ عَٰقِبَةَ ٱلَّذِينَ أَسَٰٓـُٔواْ ٱلسُّوٓأَىٰٓ أَن كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَكَانُواْ بِهَا يَسۡتَهۡزِءُونَ 10
Lẹyin naa igbẹyin awọn ti isẹ wọn buru pẹlu sise ẹbọ si Allah ati sise aidara jẹ igbẹyin ti o ga nibiburu nitoripe wọn pe awọn amin Allah nirọ, wọn si nfi se yẹyẹ, wọn si nmu ni fifuyẹ.
ٱللَّهُ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ ثُمَّ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 11
Allah ni o bẹrẹ dida ẹda lori apejuwe ti ko siwaju, lẹyin naa O mu opin ba a, lẹyin naa O tun mu u pada, lẹyin naa ọdọ Rẹ nikan ni ẹ o sẹri si fun isiro ati ẹsan ni ọjọ igbende.
وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يُبۡلِسُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ 12
Ni ọjọ ti asiko yoo to, awọn ẹlẹsẹ yoo jakan kuro nibi ikẹ Allah, irankan wọn yoo ja kuro nibẹ; nitori jija awijare wọn lori sise keferi si Allah.
وَلَمۡ يَكُن لَّهُم مِّن شُرَكَآئِهِمۡ شُفَعَٰٓؤُاْ وَكَانُواْ بِشُرَكَآئِهِمۡ كَٰفِرِينَ 13
Ko si si fun wọn nibi awọn ti wọn mu kẹgbẹ - awọn ti wọn nsin wọn ni ile aye - ẹniti yoo sipẹ lati la kuro nibi iya naa, wọn si ti di keferi nitori mimu wọn ni akẹgbẹ, wọn ti sọ wọn di ẹni yẹpẹrẹ nitori wiwa iwulo lọsi ọdọ wọn toripe gbogbo wọn ni wọn papọ nibi iparun.
وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يَوۡمَئِذٖ يَتَفَرَّقُونَ 14
Ọjọ ti asiko yoo to, ni ọjọ yii awọn eniyan yoo ya lọtọọtọ nibi ẹsan ni ibamun si isẹ wọn ni ile aye laarin ẹni agbeg si awọn ẹni oke ati irẹẹlẹ si awọn ẹni ilẹẹlẹ.
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَهُمۡ فِي رَوۡضَةٖ يُحۡبَرُونَ 15
Sugbọn awọn ti wọn nigbagbọ si Allah, ti wọn si nse awọn rere ti o le yọ Ọ ninu, awọn wọnyii yoo wa ninu ọgba idẹra ni ẹniti yoo maa dunnu pẹlu ohun ti ọwọ wọn ba tẹ ninu idẹkun lailai ti ko nii ja nibẹ.
Nini imọ nipa ohun ti yoo seni lanfaani laye ati fifọnu nipa ohun ti yoo seni lanfaani lọrun ko le se anfaani.
Awọn amin Allah wa ni ara at ni oferefe lapapọ lati tọka si ọkan soso Rẹ.
Abosi jẹ okunfa iparun awọn ijọ ti o siwaju.
Ọjọ igbende ni Allah yoo gbe awọn olugbagbọ ododo ga, Yoo si rẹ awọn keferi nilẹ.