وَنُمَكِّنَ لَهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَنُرِيَ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَجُنُودَهُمَا مِنۡهُم مَّا كَانُواْ يَحۡذَرُونَ 6
A si ngbero lati gba wọn laye lori ilẹ pẹlu sisọ wọn di alagbara nibẹ, ki a si fi han firiaon ati awọn olukunlọwọ rẹ agba nibi ọla tii se haamana ati awọn ọmọ ogun wọn ti o nku wọn lọwọ nibi ọla awọn mejeeji, nkan ti wọn npaya rẹ nipa lilọ ọla wọn, ati titan rẹ la ti ọwọ ọmọkunrin ti wọn yoo bi ninu awọn ọrọmọdọmọ isirẹli.
Nigbati Allah sọ nipa ibi ti ọla fir'aona yoo sẹri si ati apọnle ti yoo ba Musa ati awọn ijọ rẹ, o wa sọ ipilẹ Musa ẹniti ọla nbẹ fun titi di igbati Allah gbe dide ni ojisẹ, o wa sọpe:
وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰٓ أُمِّ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَرۡضِعِيهِۖ فَإِذَا خِفۡتِ عَلَيۡهِ فَأَلۡقِيهِ فِي ٱلۡيَمِّ وَلَا تَخَافِي وَلَا تَحۡزَنِيٓۖ إِنَّا رَآدُّوهُ إِلَيۡكِ وَجَاعِلُوهُ مِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 7
A fi mọ iya Musa ẹniti ọla nbẹ fun wipe ki o fun lọyan titi di igbati o npaya le lori nitori fir'aona ati ijọ rẹ, ti wọn le pa a, ki o ya gbe si inu apoti, ki o si ju u si inu odo nayli, ki o ma bẹru le lori nipa titẹri tabi nipa fir'aona, masi se banijẹ nitori pipinya rẹ dajudaju awa yoo sẹri rẹ pada si ọ laaye, a o si sọ ọ di ojisẹ kan ninu awọn ojisẹ Allah eyiti a gbe wọn dide si ẹda Rẹ.
فَٱلۡتَقَطَهُۥٓ ءَالُ فِرۡعَوۡنَ لِيَكُونَ لَهُمۡ عَدُوّٗا وَحَزَنًاۗ إِنَّ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَجُنُودَهُمَا كَانُواْ خَٰطِِٔينَ 8
O si se amusẹ ohun ti a fi mọ ọ nipa gbigbe si inu apoti, bayi ni o ju u sinu odo, ara ile fir'aona si kọsẹ ba a, wọn si mu u, ki ohun ti Ọlọhun Ọba Allah gbero le di amusẹ nipa ki Musa le di ọta fun fir'aona ti Ọlọhun Ọba yoo fi yẹ ọla rẹ lati ọwọ rẹ, ti yoo si le se akunfa ibanujẹ wọn, dajudaju fir'aona ati asoju rẹ hamana ati awọn olukunlọwọ awọn mejeeji jẹ ẹlẹsẹ nitori keferi wọn ati ikọja ẹnu aala wọn ati sise ibajẹ wọn si ori ilẹ.
وَقَالَتِ ٱمۡرَأَتُ فِرۡعَوۡنَ قُرَّتُ عَيۡنٖ لِّي وَلَكَۖ لَا تَقۡتُلُوهُ عَسَىٰٓ أَن يَنفَعَنَآ أَوۡ نَتَّخِذَهُۥ وَلَدٗا وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ 9
Nigbati fir'aona gbero lati pa a, iyawo rẹ sọ fun wipe: ọmọkunrin yii jẹ ipilẹ idunnu mi ati fun iwọ naa, mase pa a, o seese ki o se wa ni anfaani isisẹsin tabi ki a mu ni ọmọ afipeni, bẹẹni wọn ko mọ ohun ti ọla wọn yoo sẹri si lati ọwọ rẹ.
وَأَصۡبَحَ فُؤَادُ أُمِّ مُوسَىٰ فَٰرِغًاۖ إِن كَادَتۡ لَتُبۡدِي بِهِۦ لَوۡلَآ أَن رَّبَطۡنَا عَلَىٰ قَلۡبِهَا لِتَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 10
Ọkan iya Musa ẹniti ọla nbẹ fun di ohun ti o pa lofo kuro nibi alamọri gbogbo ọrọ aye ayaafi ọrọ Musa, ko fẹ le se suuru titi o fi sun mọ lati se afihan wipe ọmọ rẹ ni nibi lile koko lilẹ pẹlu rẹ, ti kii ba se pe a so ọkan rẹ pẹlu fifi rinlẹ ati fifun un ni suuru, ki o le wa ninu awọn olugbagbọ ododo ti o gbe ara le Ọlọhun Ọba wọn ati awọn onisuuru lori ohun ti o ba sẹlẹ.
وَقَالَتۡ لِأُخۡتِهِۦ قُصِّيهِۖ فَبَصُرَتۡ بِهِۦ عَن جُنُبٖ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ 11
Iya Musa - ti ọla nbẹ fun - sọ fun ọmọ iya rẹ birin lẹyin igbati o ti ju u si inu odo: maa tọ ipa rẹ lọ ki o le mọ ounti wọn yoo fi se, ki o maa si wo lati ọọkan, ki ọrọ rẹ ma ba han, bẹẹni fir'aona ati awọn ijọ rẹ wọn ko nii fura mọ wipe ọmọ iya rẹ birin ni ati wipe dajudaju o ntọpa iro rẹ ni.
۞وَحَرَّمۡنَا عَلَيۡهِ ٱلۡمَرَاضِعَ مِن قَبۡلُ فَقَالَتۡ هَلۡ أَدُلُّكُمۡ عَلَىٰٓ أَهۡلِ بَيۡتٖ يَكۡفُلُونَهُۥ لَكُمۡ وَهُمۡ لَهُۥ نَٰصِحُونَ 12
Musa kọ lati gba ọyan ni ọdọ awọn obirin nitori eto Ọlọhun Ọba Allah lati da pada si odo iya rẹ, nigbati ọmọ iya rẹ birin ri i, o se wọn loju kokoro lori ki o fun un lọyan, o si sọ fun wọn wipe: njẹ ki ntọka yin si awọn ara ile kan, ti wọn yoo fun lọyan ati itọju rẹ, ti wọn yoo si maa se daadaa si i?
فَرَدَدۡنَٰهُ إِلَىٰٓ أُمِّهِۦ كَيۡ تَقَرَّ عَيۡنُهَا وَلَا تَحۡزَنَ وَلِتَعۡلَمَ أَنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 13
Bẹẹni a da Musa pada si ọdọ iya rẹ ni ireti ki o le tutu oju rẹ nibi riri i ni arọwọto, ki o ma banujẹ nitori yiya lọtọọtọ rẹ, ki o si le, ki o si le mọ wipe dajudaju adehun Allah lori sisẹri rẹ pada jẹ ododo ti ko si iyemeji nibẹ, sugbọn ọpọlọpọ wọn ko mọ adehun yii, bẹẹni ẹnikankan wọn ko mọ wipe ohun ni iya rẹ.
Eto Allah fun awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ ẹniire pẹlu ohun ti yoo la wọn kuro nibi ete awọn ọta wọn.
Eto alabosi yoo sẹri si ibi iparun rẹ.
Agbara ti nbẹ fun aanu awọn iya si awọn ọmọ wọn.
Titọ lilo ete ti a se lofun lati bọ kuro nibi abosi alabosi.
Jijẹ tootọ adehun Allah lori sisẹlẹ rẹ ti ko si iyemeji.