ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّهُۥ يُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَأَنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 6
Eyiti a sọ fun yin yii - ninu bibẹrẹ isẹda yin ati awọn ipele rẹ ati awọn isesi ẹniti wọn bi ninu yin - nitori ki ẹ le nigbagbọ wipe dajudaju Allah ẹniti O da yin, Oun ni ododo eyiti ko si iyemeji nibẹ yatọ si ohun ti ẹ nsin ninu awọn oosa yin, ki ẹ si tun le gbagbọ wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah oluji awọn oku ati wipe dajudaju O lagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko si le ko agbara ba A.
وَأَنَّ ٱلسَّاعَةَ ءَاتِيَةٞ لَّا رَيۡبَ فِيهَا وَأَنَّ ٱللَّهَ يَبۡعَثُ مَن فِي ٱلۡقُبُورِ 7
Ati ki ẹ le nigbagbọ wipe dajudaju igbende nbẹ ko si iyemeji nipa wiwa rẹ ati wipe dajudaju Allah yoo gbe awọn oku dide ninu saare ki O le san wọn lẹsan lori awọn isẹ wọn.
Nigbati Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun sọ nipa isesi anu lati ibi ikọse ninu aayah eleeketa, O tun sọ isesi anu awọn olori keferi ninu aayah yii, O si sọ wipe:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَٰدِلُ فِي ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَلَا هُدٗى وَلَا كِتَٰبٖ مُّنِيرٖ 8
O nbẹ ninu awọn keferi ti o nja mimọ Ọlọhun Ọba lọkan niyan laisi imọ ni ọdọ wọn ti o le mu wọn lọ si ibi ododo, ti ko si si itẹle imọna ti yoo tọka wọn le lori, bẹẹni ko si iwe ti o tan imọlẹ, ti o sọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti yoo fi wọn mọ ọna Rẹ.
ثَانِيَ عِطۡفِهِۦ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۖ لَهُۥ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞۖ وَنُذِيقُهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ عَذَابَ ٱلۡحَرِيقِ 9
Yoo maa tẹ ọrun rẹ kọkọ niti isegberaga ki o le mu awọn eniyan kuro nibi igbagbọ ati wiwọ inu ẹsin Allah, iyẹpẹrẹ nbẹ fun ẹniti iroyin rẹ ba jẹ eleyi ni ile aye pẹlu ohun ti yoo ba pade ninu iya, a o tun iya ina jẹ lọrun eyiti yoo jo.
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتۡ يَدَاكَ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَيۡسَ بِظَلَّٰمٖ لِّلۡعَبِيدِ 10
Wọn yoo si sọ fun: iya eyiti o tọ wo yii jẹ okunfa ohun ti ko jọ ni keferi ati awọn ẹsẹ, Ọlọhun Allah kii fi iya jẹ ẹnikẹni ninu ẹda Rẹ ayaafi lori ẹsẹ.
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَعۡبُدُ ٱللَّهَ عَلَىٰ حَرۡفٖۖ فَإِنۡ أَصَابَهُۥ خَيۡرٌ ٱطۡمَأَنَّ بِهِۦۖ وَإِنۡ أَصَابَتۡهُ فِتۡنَةٌ ٱنقَلَبَ عَلَىٰ وَجۡهِهِۦ خَسِرَ ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةَۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡخُسۡرَانُ ٱلۡمُبِينُ 11
O nbẹ ninu awọn eniyan ti ndaamun, ti yoo maa sin Allah lori iyemeji, ti rere kan ninu alaafia ati ọrọ ba sẹlẹ si i, yoo tẹsiwaju lori igbagbọ rẹ ati ijọsin rẹ fun Allah, ti adanwo ba kan an gẹgẹ bi aarẹ tabi osi, yoo gbero aburu pẹlu ẹsin rẹ, yoo si sẹri kuro nibẹ, o ti sosfo aye, keferi ko si le se alekun ipin kankan fun un ni ile aye, ti wọn ko kọ silẹ fun, o si tun sofo ọrun nitori iya Ọlọhun Ọba ti yoo ba pade, eleyi ni ofo ti o fi oju han.
يَدۡعُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُۥ وَمَا لَا يَنفَعُهُۥۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلضَّلَٰلُ ٱلۡبَعِيدُ 12
O nsin ohun ti o yatọ si Allah ti ko le ko inira ba a ti o ba sẹ ẹ, ko si le se ni anfaani ti o ba tẹle tirẹ, pipe awọn oosa rẹ ko le mu inira wa, bẹẹni ko le se anfaani, o jẹ anu ti o jinna si ododo.
يَدۡعُواْ لَمَن ضَرُّهُۥٓ أَقۡرَبُ مِن نَّفۡعِهِۦۚ لَبِئۡسَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَلَبِئۡسَ ٱلۡعَشِيرُ 13
Keferi eyiti o nsin oosa yoo maa pepe nitori inira ti o nse e, ti o si jasi wipe anfaani ti yoo padanu sunmọ ju u lọ, nitori aburu ohun ti o nsin ti o jasi wipe inira rẹ o sun mọ ju anfaani rẹ lọ, o buru ni olurannise fun awọn ti nwa a ni alaranse tabi wa ni abanikẹgbẹ fun ẹniti nwa ni ibakẹgbẹ.
إِنَّ ٱللَّهَ يُدۡخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يُرِيدُ 14
Dajudaju Allah yoo fi awọn ti o nigbagbọ si I, ti wọn si nsisẹ re wọ inu ọgba idẹra eyiti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ, dajudaju Allah ma nse ohun ti O wu U ninu ikẹ fun ẹniti O ba fẹ kẹ ati ijiya fun ẹniti O ba fẹ jẹ niya, ẹnikankan ko ke jẹ nipa, mimọ Rẹ.
مَن كَانَ يَظُنُّ أَن لَّن يَنصُرَهُ ٱللَّهُ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ فَلۡيَمۡدُدۡ بِسَبَبٍ إِلَى ٱلسَّمَآءِ ثُمَّ لۡيَقۡطَعۡ فَلۡيَنظُرۡ هَلۡ يُذۡهِبَنَّ كَيۡدُهُۥ مَا يَغِيظُ 15
Ẹniti o ba nlero wipe dajudaju Allah ko le se aranse fun Anọbi Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ni ile aye ati ni ọrun, ki o ya fa okun kan lọsi aja ile rẹ, lẹyin naa ki o fi pokun so, ki o nfi pa ara rẹ, lẹyin naa ki o wa woye boya eleyi yoo mu ohun ti o nri ninu ẹmin rẹ ninu ibinu kuro, Ọlọhun Ọba Allah ni oluse aranse fun Anọbi Rẹ, boya olugunri fẹni tabi o kọ.
Awọn okunfa imọna le jẹ imọ ti nyoo mu de ibi ododo tabi olutọni sọna ti yoo tọka rẹ fun un tabi iwe kan ti yoo gbara le lati tọ ọ sọna lọ si ibẹ.
Igberaga jẹ iwa ti o ma nkọ fun ni lati se kongẹ ododo.
Ninu deede Allah nipe kii fi iya jẹ yan ayaafi lori ẹsẹ.
Allah jẹ alaranse fun Anọbi Rẹ ati fun ẹsin Rẹ koda bi awọn keferi kọ.