وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ أَنجَىٰكُم مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَسُومُونَكُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ وَيُذَبِّحُونَ أَبۡنَآءَكُمۡ وَيَسۡتَحۡيُونَ نِسَآءَكُمۡۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَآءٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَظِيمٞ 6
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nigbati Musa tẹle asẹ Ọlọhun Ọba rẹ, o si sọ fun awọn ijọ rẹ ninu awọn ọmọ isirẹli ni ẹniti o nran wọn leti idẹkun Allah le wọn lori: ẹyin ijọ mi, ẹ ranti idẹkun Allah le yin lori nigbati o yọ yin kuro lọdọ awọn ara ile firiaona, O si la yin kuro nibi ijiya wọn, ti wọn nfun yin ni iya buburu mu nibi ti wọn ti ndu awọn ọmọkunrin yin, ki wọn ma le bi ẹniti yoo jẹ gaba lori ọla firiaona, ti wọn si nsẹ awọn obinrin yin ku saye lati yẹpẹrẹ wọn ati sọ wọn di ẹni ilẹ, nibi awọn isẹ yin yii jẹ adanwo ti o tobi fun yin lori suuru, Ọlọhun Ọba yin si san yin lẹsan lori suuru yin nipa adanwo yii pẹlu wipe o yọ yin kuro nibi igbamun awọn ara ile firiaona.
وَإِذۡ تَأَذَّنَ رَبُّكُمۡ لَئِن شَكَرۡتُمۡ لَأَزِيدَنَّكُمۡۖ وَلَئِن كَفَرۡتُمۡ إِنَّ عَذَابِي لَشَدِيدٞ 7
Musa waa sọ fun wọn: ẹ ranti nigbati Ọlọhun Ọba yin fi imọ ti o ga ti o de ogongo mọ yin: ti ẹ ba dupẹ fun Allah lori idẹkun ti O se fun yin nibi idẹkun ti a sọ yii, yoo se alekun fun yin lori rẹ nibi irọra ati ọla Rẹ, sugbọn ti ẹ ba ja idẹkun Rẹ ti o se fun yin niyan, ti ẹ ko dupẹ rẹ, dajudaju iya Rẹ le koko fun ẹniti o ba ja idẹkuin Rẹ niyan, ti ko si dupẹ rẹ.
وَقَالَ مُوسَىٰٓ إِن تَكۡفُرُوٓاْ أَنتُمۡ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا فَإِنَّ ٱللَّهَ لَغَنِيٌّ حَمِيدٌ 8
Musa tun sọ fun awọn ijọ Rẹ: ẹyin ijọ mi, ti ẹ ba se keferi, ti gbogbo awọn ti nbẹ lori ilẹ naa si tun se keferi, inira keferi yin yoo sẹri si ọdọ yin; dajudaju Ọlọhun Ọba Allah rọrọ fun raaRẹ, O si lẹtọ fun ọpẹ fun ara Rẹ, igbagbọ awọn olugbagbọ ododo ko le se ni anfaani, bẹẹ ni keferi awọn alaimoore ko le ko inira ba A.
أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ نَبَؤُاْ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ قَوۡمِ نُوحٖ وَعَادٖ وَثَمُودَ وَٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لَا يَعۡلَمُهُمۡ إِلَّا ٱللَّهُۚ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَرَدُّوٓاْ أَيۡدِيَهُمۡ فِيٓ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَقَالُوٓاْ إِنَّا كَفَرۡنَا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ وَإِنَّا لَفِي شَكّٖ مِّمَّا تَدۡعُونَنَآ إِلَيۡهِ مُرِيبٖ 9
Se ko waa ba yin ni - ẹyin keferi - iro nipa iparun awọn ijọ siwaju yin: ijọ Nuha, Haadi ati ijọ Huud ati samudawa ijọ sọlihu, ati awọn ijọ ti o wa siwaju ti wọn, wọn jẹ onka ti o pọ ti a ko le ka wọn ayaafi Allah? Awọn ojisẹ wọn mu awọn amin ti o fi oju han wa fun wọn, wọn ki awọn ọwọ wọn bọ inu ni ẹniti o nge awọn ika wọn jẹ nibi ibinu si awọn ojisẹ, wọn si sọ fun awọn ojisẹ wọn: dajudaju, awa se keferi si ohun ti ẹ ran nisẹ, bẹẹ ni a si wa lori iyemeji ti nse iwadi roiroi lori ohun ti ẹ npe wa si.
۞قَالَتۡ رُسُلُهُمۡ أَفِي ٱللَّهِ شَكّٞ فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ يَدۡعُوكُمۡ لِيَغۡفِرَ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمۡ وَيُؤَخِّرَكُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗىۚ قَالُوٓاْ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا تُرِيدُونَ أَن تَصُدُّونَا عَمَّا كَانَ يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَا فَأۡتُونَا بِسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٖ 10
Awọn ojisẹ wọn sọ fun wọn ni ẹniti nfesi fun wọn: se iyemeji nbẹ nibi mimọ Ọlọhun Ọba lọkan ati sise E laaso pẹlu ijọsin, Oun ni oluda sanmọ ati ẹlẹda ilẹ, Oun ni O si mu mejeeji bẹ lori aisi apejuwe siwaju?! O npe yin sibi igbagbọ si I ki o le pa awọn ẹsẹ yin ti ẹ ti sẹ siwaju rẹ, ki O si lọ yin lara di asiko ti asiko iku yin ti wọn pebubu fun yin yoo fi to ni isẹmin aye yin, awọn ijọ wọn sọ fun wọn wipe: ẹ ko jẹ nkankan ju abara bi tiwa lọ, ko si ẹsa fun yin lori wa, ẹ ngbero lati yiwa kuro nibi sinsin ohun ti awọn baba wa nsin, ki ẹ ya mu awijare ti o fi oju han wa fun wa, ti o si tọka si jijẹ ododo yin nibi ohun ti ẹ npe nipa wipe ojisẹ lati ọdọ Allah si wa ni yin.
Ninu ojupọnna ipepe ni mima ran ẹniti a npe leti idẹkun Allah ti o wa lori rẹ, pataki julọ nigbati o ba su pọ mọ kidẹkun ti o tobi, gẹgẹ bi aranse lori ọta tabi lila kuro nibẹ.
Ninu ọla Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga ni sise adehun Rẹ fun awọn ẹru lati fi alekun idẹkun se kongẹ ọpẹ wọn ni didu, ni idakeji adehun iya Rẹ ti o le koko si nbẹ fun ẹniti o ba se aimoore si I.
Sise keferi ẹru ko le ko inira kankan ba Allah gẹgẹ bi igbagbọ wọn naa ko le se alekun nkankan fun Un, O jẹ ọlọrọ gbọpẹgbọpẹ fun ara Rẹ.