۞وَمَا مِن دَآبَّةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِ رِزۡقُهَا وَيَعۡلَمُ مُسۡتَقَرَّهَا وَمُسۡتَوۡدَعَهَاۚ كُلّٞ فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٖ 6
ko si ẹda kan ti o nrin lori ilẹ bi o ti wulẹ ki o ri ayaafi ki o jẹ wipe Allah ni o nse ijẹ imu rẹ ni sise ọla lati ọdọ Rẹ, Oun ti mimọ nbẹ fun ni o mọ aaye rẹ lori ilẹ, O si tun mọ aaye iku rẹ ti yoo ku si, gbogbo ohun ti o nrin lorilẹ ati arisiki rẹ ati awọn aaye ibudurosi rẹ ati awọn aaye iku rẹ wa ninu iwe ti o fi oju han, ohun naa ni ọpọn eyiti a ndaabobo.
وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ وَكَانَ عَرۡشُهُۥ عَلَى ٱلۡمَآءِ لِيَبۡلُوَكُمۡ أَيُّكُمۡ أَحۡسَنُ عَمَلٗاۗ وَلَئِن قُلۡتَ إِنَّكُم مَّبۡعُوثُونَ مِنۢ بَعۡدِ ٱلۡمَوۡتِ لَيَقُولَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٞ 7
Oun ti mimọ nbẹ fun ni ẹniti o da sanmọ ati ilẹ bi o se tobi to, O si da gbogbo ohun ti o nbẹ nibẹ ni ọjọ mẹfa, itẹ Rẹ ti wa siwaju ki o too da a si ori omin; ki o le ba fun yin niro - ẹyin eniyan -, taani yoo se isẹ ti yoo yọ Ọlọhun Ọba Allah ninu yin ati ẹniti yoo sisẹ aburu ti yoo bi ninu yin, yoo wa san ẹnikọọkan lẹsan ti o tọ si i, ti o ba si sọ wipe - ire ojise -: dajudaju ẹyin jẹ - ẹyin eniyan - ẹniti a o gbe dide lẹyin iku yin, awọn ti wọn se keferi si Ọlọhun Ọba Allah ti wọn si tako igbende yoo sọ wipe: Alukuraani ti ẹ nka yii ko jẹ nkankan ju idan ti o fi oju han lọ, ibajẹ ni o jẹ ti ibajẹ rẹ si han.
وَلَئِنۡ أَخَّرۡنَا عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابَ إِلَىٰٓ أُمَّةٖ مَّعۡدُودَةٖ لَّيَقُولُنَّ مَا يَحۡبِسُهُۥٓۗ أَلَا يَوۡمَ يَأۡتِيهِمۡ لَيۡسَ مَصۡرُوفًا عَنۡهُمۡ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ 8
Ti a ba lọ iya ti o tọ si awọn ẹlẹbọ lara ninu isẹmin aye fun asiko ọjọ ti o ni onka, wọn yoo maa sọ ni ẹniti o nkanju ti o si nse yẹyẹ wipe: kinni nkan ti ndi iya lọwọ fun wa gan? Tẹti o gbọ, dajudaju iya ti wọn lẹtọ si yii ti ni asiko lọdọ Ọlọhun Ọba, nigbati o ba de ba wọn, wọn ko nii ri ẹniti yoo yi kuro fun wọn, yoo sẹlẹ le wọn lori, gbogbo iya ti wọn nkanju rẹ niti yẹyẹ ati awada ni yoo bo wọn da ru.
وَلَئِنۡ أَذَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِنَّا رَحۡمَةٗ ثُمَّ نَزَعۡنَٰهَا مِنۡهُ إِنَّهُۥ لَئَُوسٞ كَفُورٞ 9
Ti a ba fun ọmọniyan ni idẹkun kan gẹgẹ bi idẹkun alaafia ati ọrọ lẹyin igba naa ti a tun gba idẹkun yii lọwọ rẹ, dajudaju yoo jẹ olujakan lọpọ igba kuro nibi ikẹ Allah, yoo si tobi ni sise keferi pẹlu idẹkun Rẹ, yoo gbagbe rẹ nigbati allah ba gba a lọwọ rẹ.
وَلَئِنۡ أَذَقۡنَٰهُ نَعۡمَآءَ بَعۡدَ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُ لَيَقُولَنَّ ذَهَبَ ٱلسَّئَِّاتُ عَنِّيٓۚ إِنَّهُۥ لَفَرِحٞ فَخُورٌ 10
Ti a ba fi pipọ arisiki tọ ọ lẹnu wo ati alaafia lẹyin osi ati aarẹ ti o kan an yoo sọ wipe: aburu ti kuro fun mi, bẹẹ ni inira ti yẹ ko si ni dupẹ lori eleyi, dajudaju o jẹ ọlọpọ ayọ niti ayọpọrọ, o si jẹ ẹniti o pọ ni mima tọju bọ awọn eniyan ati mima se iyanran pẹlu idẹkun ti Ọlọhun Ọba Allah se fun wọn.
إِلَّا ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَأَجۡرٞ كَبِيرٞ 11
Ayaafi awọn ti wọn se suuru lori awọn nkan ti ọkan kọ ati awọn itẹle asẹ ati kuro nibi awọn ẹsẹ, ti wọn si nse ọpọlọpọ isẹẹre, isesi miran wa fun wọn nibi ti ijakan ko ti nii sẹlẹ si wọn, ti wọn ko si nii se keferi si idẹkun Allah, ti wọn ko si ni maa tọ oju bọ awọn eniyan, awọn wọnyi ni a fi awọn iroyin naa royin, aforijin wa fun wọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba lori ẹsin wọn, bakanna ni ẹsan ti o tobi nbẹ ni ọrun.
فَلَعَلَّكَ تَارِكُۢ بَعۡضَ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ وَضَآئِقُۢ بِهِۦ صَدۡرُكَ أَن يَقُولُواْ لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡهِ كَنزٌ أَوۡ جَآءَ مَعَهُۥ مَلَكٌۚ إِنَّمَآ أَنتَ نَذِيرٞۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٌ 12
O seese iwọ ojisẹ naa - fun ohun ti o da oju kọ ninu keferi wọn ati isori kunkun wọn ati mimu imọran wa lori awọn aayah - ki o gbe mimudopin apakan ohun ti Ọlọhun Ọba Allah pa ọ lasẹ wipe ki o mudopin ju silẹ ninu ohun ti o soro fun wọn lati le se, ti o si pin iwọ naa lẹmi lati mu dopin rẹ, ki wọn maa baa maa sọ wipe: kinni o de ti wọn ko sọ pẹpẹ ọrọ ti yoo rọ lọrọ fun un kalẹ tabi ki Malaika kan wa ti yoo pe e lododo, mase gbe ju silẹ apakan imisi ti o wa ba ọ nitori eleyi, iwọ ko jẹ nkankan ju olukilọ lọ, ki o mun dopin nkan ti Ọlọhun Ọba rẹ pa ọ lasẹ imudopin rẹ, kii se dandan fun ọ ki o mu imọrn wọn ninu awọn aayah wa, Ọlọhun Ọba Allah jẹ oludaabobo lori gbogbo nkan.
Gbigbaaye imọ Allah ti o ga julọ ati lila arisiki awọn ẹda Rẹ bọrun gẹgẹ bi ẹnikan tabi ẹranko tabi ohun ti o yatọ si awọn mejeeji.
Sise alaye aleebu ẹda; ohun ni sise adanwo fun awọn ẹru Rẹ nibi titẹle awọn asẹ Allah ati jijinna si awọn nkan ti o kọ.
Ko tọ ki a gba itanjẹ pẹlu idẹlẹkẹ Ọlọhun Ọba fun awọn ẹlẹsẹ nitori wipe o le gba wọn mu lojiji, ti wọn ko nii mọ rara.
Sise alaye isesi ọmọ ẹda eniyan ni igba idẹkun ati ilekoko ati yiyin ipo olugbagbọ nigbati o ba nse suuru, ti o si ndupẹ.