وَمَا مَنَعَنَآ أَن نُّرۡسِلَ بِٱلۡأٓيَٰتِ إِلَّآ أَن كَذَّبَ بِهَا ٱلۡأَوَّلُونَۚ وَءَاتَيۡنَا ثَمُودَ ٱلنَّاقَةَ مُبۡصِرَةٗ فَظَلَمُواْ بِهَاۚ وَمَا نُرۡسِلُ بِٱلۡأٓيَٰتِ إِلَّا تَخۡوِيفٗا 59
A ko fi sisọ awọn amin ti o se fi oju ri kankan silẹ, ti o si ntọka si ododo ojisẹ naa eyiti awọn ẹlẹbọ nbeere fun gẹgẹ bi jiji awọn oku dide ati ohun ti o jọọ ayafi ki o ja si wipe toripe a sọ ọ kalẹ fun awọn ijọ akọkọ, wọn si pe e nirọ, paapaa a ti fun samudawa ni amin ti o tobi, ti o si fi oju han, ohun ni rakunmi, wọn si se keferi si i, awa kanju fi iya jẹ wọn, a kii gbe awọn amin dide lori ọwọ awọn ojisẹ ayafi ki o jẹ ipaya fun ijọ wọn; o seese ki wọn jupa jusẹ silẹ.
وَإِذۡ قُلۡنَا لَكَ إِنَّ رَبَّكَ أَحَاطَ بِٱلنَّاسِۚ وَمَا جَعَلۡنَا ٱلرُّءۡيَا ٱلَّتِيٓ أَرَيۡنَٰكَ إِلَّا فِتۡنَةٗ لِّلنَّاسِ وَٱلشَّجَرَةَ ٱلۡمَلۡعُونَةَ فِي ٱلۡقُرۡءَانِۚ وَنُخَوِّفُهُمۡ فَمَا يَزِيدُهُمۡ إِلَّا طُغۡيَٰنٗا كَبِيرٗا 60
Ranti - irẹ ojisẹ - nigbati a sọ fun ọ: dajudaju agbara Ọlọhun Ọba rẹ rọkirika awọn eniyan, wọn wa ni atẹlẹwọ Rẹ, Ọlọhun Allah yoo si maa la ọ ninu wọn, ki o si mu dopin ounti wọn pa ọ lasẹ imudopin rẹ, a ko se ounti a mu ọ ri loju koroju ni oru irin ajo oru ayafi ki o le jẹ idanwo fun awọn eniyan, boya wọn yoo gba a lododo tabi wọn yoo pe e nirọ? A ko si se igi "ṣakuumi" ti a darukọ ninu Alukuraani, ti o nwu lati isalẹ salẹ ina jahimi ni nkankan ju adanwo fun wọn lọ, ti wọn ko nigbagbọ si awọn mejeeji yii, wọn ko le nigbagbọ si ounti o yatọ si wọn, a ndẹru ba wọn pẹlu sisọ awọn aayah kalẹ sugbọn wọn ko lekun ni ipaya lati ibi sisọ ọ kalẹ ayafi ilekun nibi keferi ati itẹsiwaju aida nibi anu.
وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ قَالَ ءَأَسۡجُدُ لِمَنۡ خَلَقۡتَ طِينٗا 61
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nigbati a sọ fun awọn Malaika: ẹ fi ori balẹ fun Aadamọ ni iforibalẹ ti ikini ti kii se iforibalẹ ijọsin, wọn tẹle asẹ, gbogbo wọn patapata si fi ori kan lẹ sugbọn ibilisu taku nibi igberaga lati mase fi ori balẹ fun un ni ẹniti o sọ bayi wipe: se maa fi ori balẹ fun ẹniti O da lati inu abata, O si da emi lati inu ina?! Emi niyi ju u lọ.
قَالَ أَرَءَيۡتَكَ هَٰذَا ٱلَّذِي كَرَّمۡتَ عَلَيَّ لَئِنۡ أَخَّرۡتَنِ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَأَحۡتَنِكَنَّ ذُرِّيَّتَهُۥٓ إِلَّا قَلِيلٗا 62
Ibilisu sọ fun Ọlọhun rẹ: se O ri ẹda ti o se apọnle le mi lori lati ibi asẹ Rẹ wipe ki nfi ori balẹ fun un? Ti o ba mu mi jade ni alaaye si igbẹyin isẹmin ile aye, paapaa emi yoo gun awọn ọmọ rẹ lori, maa si si wọn lọna kuro ni oju ọna ti o duro tọ ayafi diẹ ninu awọn ti O ba sọ ninu wọn, awọn naa ni awọn ẹru Rẹ ti O fọ mọ.
قَالَ ٱذۡهَبۡ فَمَن تَبِعَكَ مِنۡهُمۡ فَإِنَّ جَهَنَّمَ جَزَآؤُكُمۡ جَزَآءٗ مَّوۡفُورٗا 63
Ọlọhun rẹ sọ fun: maa lọ iwọ ati ẹniti o tẹle ọ ninu wọn, dajudaju jahnamọ ni ẹsan rẹ ati ẹsan wọn ni ẹsan pipe ti yoo si kun lori isẹ yin.
وَٱسۡتَفۡزِزۡ مَنِ ٱسۡتَطَعۡتَ مِنۡهُم بِصَوۡتِكَ وَأَجۡلِبۡ عَلَيۡهِم بِخَيۡلِكَ وَرَجِلِكَ وَشَارِكۡهُمۡ فِي ٱلۡأَمۡوَٰلِ وَٱلۡأَوۡلَٰدِ وَعِدۡهُمۡۚ وَمَا يَعِدُهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ إِلَّا غُرُورًا 64
Mu ni fifuyẹ ẹniti o ba wu ọ lati mu ni fifuyẹ ninu wọn pẹlu ohun rẹ eyiti npepe lọ si ibi ẹsẹ, si mu ẹsin rẹ rin le wọn lori ati ẹran rẹ fun awọn ti wọn ba jẹpe itẹle ọ, ki o si bẹ pẹlu wọn nibi dukia wọn pẹlu ki o se gbogbo igbesẹ ti o ba ti yapa si ofin ni ọsọ, ki o kun wọn nibi awọn ọmọ wọn pẹlu pipe apemọra wọn niti irọ, ki o si mu ọwọ wọn to agbere, ki o si mu wọn jọsin fun ohun ti o yatọ si Allah nigbati wọn ba nsọrukọ, ki o si se e lọsọ fun wọn awọn adehun irọ ati awọn erongba ibajẹ, esu ko se adehun kankan fun wọn ju adehun irọ eyiti o ntan wọn jẹ lọ.
إِنَّ عِبَادِي لَيۡسَ لَكَ عَلَيۡهِمۡ سُلۡطَٰنٞۚ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ وَكِيلٗا 65
Dajudaju awọn ẹru Mi ti wọn jẹ olugbagbọ ododo, ti wọn si nsisẹ pẹlu titẹle teMi ko si ijẹgaba fun ọ le wọn lori; - irẹ ibilisu - nitoripe dajudaju Allah yoo kọ di aburu fun wọn, Ọlọhun Ọba Allah si to ni alatilẹyin fun ẹniti o ba gbara le E nibi awọn alamọri rẹ.
رَّبُّكُمُ ٱلَّذِي يُزۡجِي لَكُمُ ٱلۡفُلۡكَ فِي ٱلۡبَحۡرِ لِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ كَانَ بِكُمۡ رَحِيمٗا 66
Ọlọhun yin - ẹyin eniyan - ni ẹniti O nmu awọn ọkọ oju omin yin rin ni odo ni irankan ki ẹ le wa ijẹ imu rẹ lati ibi awọn ere owo sise ati ohun ti o yatọ si i, dajudaju O jẹ Onikẹ si yin nipa rirọ awọn ojupọnna yii fun yin.
Ninu ikẹ Allah si awọn eniyan ni aisọ awọn amin eyiti awọn opurọ nwa kalẹ ki O maa ba kanju fiya jẹ wọn nigbati wọn ba pe e nirọ.
Ọlọhun Allah fi esu dan awọn ẹru Rẹ wo eyiti o npe wọn lọsi bi sisẹ Allah pẹlu awọn gbolohun rẹ ati awọn isẹ rẹ.
Ninu aworan wiwa papọ esu pẹlu ọmọniyan nibi awọn dukia ati awọn ọmọ: nigbigbe idarukọ Allah ju silẹ nigba onjẹ, mimu ati isunmọ lọkọ laya ati aiko fun awọn ọmọ ni ẹkọ.