وَٱلۡبَلَدُ ٱلطَّيِّبُ يَخۡرُجُ نَبَاتُهُۥ بِإِذۡنِ رَبِّهِۦۖ وَٱلَّذِي خَبُثَ لَا يَخۡرُجُ إِلَّا نَكِدٗاۚ كَذَٰلِكَ نُصَرِّفُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَشۡكُرُونَ 58
Ilẹ ti o ba dara, irugbin rẹ yoo jade daradara pẹlu iyọnda Ọlọhun Ọba Allah, gẹgẹ bẹẹ naa ni olugbagbọ ododo ti o ba gbọ isiti yoo se anfaani pẹlu rẹ, isẹ rere yoo si jade lati ibẹ, sugbọn ilẹ asalẹ ti o le, irugbin rẹ ko le jade ayaafi isoro ti ko si oore nibẹ, gẹgẹ bẹẹ naa ni keferi ko le se anfaani pẹlu awọn isiti, isẹ rere ko le jade nibẹ ti yoo se anfaani pẹlu rẹ, iru awọn oniranran agbekalẹ wọnyi, o nmu oniranran awijare ati ẹri wa lati le fi ododo rinlẹ fun awọn ijọ ti wọn yoo dupẹ idẹkun Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn ko ni se aimoore sii, ti wọn si ntẹle asẹ Ọlọhun Ọba wọn.
لَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوۡمِهِۦ فَقَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥٓ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ 59
Paapaa a ti gbe Nuha dide si awọn ijọ rẹ ki o le pe wọn si ijọkan soso Ọlọhun Ọba Allah, ki wọn si gbe sinsin ẹlomiran ju silẹ, o wa sọ fun wọn: ẹyin ijẹ mi, ẹ sin Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, ko si ẹniti ijọsin tọsi fun yin yatọ si I, mo npaya lori yin - ẹyin ijọ mi - iya ọjọ ti o tobi nigbati ẹ ba wo mọ sise keferi.
قَالَ ٱلۡمَلَأُ مِن قَوۡمِهِۦٓ إِنَّا لَنَرَىٰكَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ 60
Awọn asiwaju ati agbalagba ninu ijọ rẹ sọ fun un: a ri ọ - irẹ Nuha - ni ẹniti o jinna si kongẹ ti o fi oju han.
قَالَ يَٰقَوۡمِ لَيۡسَ بِي ضَلَٰلَةٞ وَلَٰكِنِّي رَسُولٞ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 61
Nuha sọ fun awọn agbalagba inu ijọ rẹ: emi kii se ẹni anu gẹgẹ bi ẹyin se nlero, mo wa ni oju ọna Ọlọhun Ọba mi, mo si jẹ ojisẹ fun yin lati ọdọ Ọlọhun, Ọlọhun Ọba Allah tii se Ọba mi ati Ọba yin ati Ọba gbogbo agbanla aye lapapọ.
أُبَلِّغُكُمۡ رِسَٰلَٰتِ رَبِّي وَأَنصَحُ لَكُمۡ وَأَعۡلَمُ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ 62
Mo nfi to yin leti ohun ti Ọlọhun Ọba mi fi ransẹ si yin ninu imisi ti wọn fi ran si mi, mo si nfẹ rere fun yin lati se ni oju kokoro si bi titẹle asẹ Ọlọhun Ọba Allah ati awọn ẹsan ti yoo ti ẹyin rẹ jade, mo si ndẹru bayin ki ẹ ma se ohun ti Ọlọhun Ọba Allah kọ ati iya ti yoo ti ẹyin rẹ yọ, mo si mọ nipa Ọlọhun Ọba nkan ti ẹyin ko mọ ninu imọ ti Ọlọhun Ọba fi ransẹ si mi ninu oju ọna imisi.
أَوَعَجِبۡتُمۡ أَن جَآءَكُمۡ ذِكۡرٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَلَىٰ رَجُلٖ مِّنكُمۡ لِيُنذِرَكُمۡ وَلِتَتَّقُواْ وَلَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ 63
Se eemọ yin lapa ati sise ajoji si yin lori wipe imisi ati isiti wa ba yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba yin lati ori ahọn ẹnikan ninu yin ti ẹ mọ? ! O dagba laarin yin, ko si jẹ opurọ tabi ẹni anu, ko si wa ninu iran miran, o wa lati dẹru bayin kuro nibi iya Ọlọhun Ọba Allah ti ẹ ba parọ tabi ẹ sẹ Ẹ, ki ẹ ya paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu wipe ki ẹ maa tẹle awọn asẹ Rẹ ati ki ẹ jinna si ohun ti O kọ, ki ẹ si maa rankan wipe Yoo kẹ yin ti ẹ ba ni igbagbọ si I.
فَكَذَّبُوهُ فَأَنجَيۡنَٰهُ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥ فِي ٱلۡفُلۡكِ وَأَغۡرَقۡنَا ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَآۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمًا عَمِينَ 64
Awọn ijọ rẹ pe nirọ, wọn ko nigbagbọ sii, wọn si tẹsiwaju lori sise keferi wọn, o waa bẹ Ọlọhun Ọba Allah le wọn lori pe ki O pa wọn run, a la a, a si la awọn ti wọn wa pẹlu rẹ ninu awọn olugbagbọ ododo kuro nibi itẹri, a fi itẹri si omi ‘tuufaanu’ pa awọn ti wọn npe awọn amin wa nirọ ti wọn si tẹsiwaju lori irọ pipa run, ki o le jẹ iya fun wọn, dajudaju ọkan wọn fọju kuro nibi ododo.
۞وَإِلَىٰ عَادٍ أَخَاهُمۡ هُودٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥٓۚ أَفَلَا تَتَّقُونَ 65
A ran ojisẹ kan ninu wọn si idile Haadi, Oun naa ni Huud, o sọ wipe: ẹyin ijọ mi, ẹ maa sin Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, ko si fun yin olujọsin fun niti ododo yatọ si I, se ẹ ko ni bẹru Rẹ pẹlu mima tẹle asẹ Rẹ, ki ẹ si jinna si awọn nkan ti o kọ, ki ẹ le la kuro nibi iya Rẹ? !
قَالَ ٱلۡمَلَأُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن قَوۡمِهِۦٓ إِنَّا لَنَرَىٰكَ فِي سَفَاهَةٖ وَإِنَّا لَنَظُنُّكَ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ 66
Awọn agbalagba ati asiwaju ninu ijọ rẹ ti wọn jẹ alaimoore si Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si npe ojisẹ Rẹ nirọ sọpe: awa mọ wipe iwọ - irẹ Huud - jẹ ẹniti o fuyẹ ni laakaye, ti ko ni ọpọlọ nigbati onpe wa sibi sinsin Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, ati ki a gbe sinsin oosa ju silẹ, bẹẹ ni a di adisọkan wipe ninu awọn opurọ ni o jẹ nibi pipe ara rẹ ni ojisẹ.
قَالَ يَٰقَوۡمِ لَيۡسَ بِي سَفَاهَةٞ وَلَٰكِنِّي رَسُولٞ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 67
Huud fesi pada fun awọn ijọ rẹ wipe: ẹyin ijọ mi, laakaye mi ko fuyẹ, bẹẹ ni mo ni ọpọlọ, ohun ti o sẹlẹ ni wipe mo jẹ ojisẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, olutọju gbogbo agbanla aye.
Ilẹ ti o ba dara da gẹgẹ bi ọkan ti o dara nigbati imisi ba sọkalẹ sii, eyiti o jẹ komookun isẹmi aye, gẹgẹ bi ojo se jẹ komookun isẹmi aye, nigbati imisi ba de si inu ọkan ti o dara, yoo tẹwọ gbaa, yoo si kọ ọ, yoo wa hun irugbin jade nitori ipilẹ rẹ ti o dara, ati awọn akẹtun rẹ ti o dara, bẹẹ naa ni idakeji rẹ.
Awọn Anọbi ati awọn ojisẹ jẹ alaanu si ẹda koda ju aala awọn baba wọn ati awọn iya wọn lọ.
Ninu isesi Ọlọhun Ọba Allah ni wipe O ran ijọ kan pẹlu ahọn wọn; ko le jẹ rirọ ọkan awọn ti isẹda wọn ko tii bajẹ, o si tun jẹ idẹkun fun abara.
Ninu awọn omugọ ti o tobi ju ohun ni ẹniti o ba pade ododo pẹlu atako, ti o si se igberaga lati ma tẹriba fun awọn onimimọ ati awọn oluse isiti, ti ọkan rẹ waa tẹriba fun esu olusẹri ẹni.