فَجَعَلَهُمۡ جُذَٰذًا إِلَّا كَبِيرٗا لَّهُمۡ لَعَلَّهُمۡ إِلَيۡهِ يَرۡجِعُونَ 58
Ibrahim ge awọn oosa naa titi ti o fi di egige keekeeke, o si sẹ eyiti o dagba wọn ku ni ireti ki wọn le sẹri waa ba lati bi leere ẹniti o kan wọn.
قَالُواْ مَن فَعَلَ هَٰذَا بَِٔالِهَتِنَآ إِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ 59
Nigbati wọn sẹri, ti wọn si ri oosa ti wọn ti kan apakan wọn beere lọwọ apakan: taani ẹniti o kan awọn ohun ti a njọsin fun? Dajudaju ẹniti o kan an jẹ ninu alabosi nitoripe o yẹpẹrẹ ohun ti o lẹtọ si ipataki ati afọmọ.
قَالُواْ سَمِعۡنَا فَتٗى يَذۡكُرُهُمۡ يُقَالُ لَهُۥٓ إِبۡرَٰهِيمُ 60
Apakan wọn sọpe: a gbọ nipa ọkunrin kan ti wọn npe aburu mọ ọ, ti o si nbu wọn, wọn npe ni Ibrahim, o seese ki o jẹpe oun ni o kan wọn.
قَالُواْ فَأۡتُواْ بِهِۦ عَلَىٰٓ أَعۡيُنِ ٱلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَشۡهَدُونَ 61
Asiwaju wọn sọpe: ẹ mu Ibrahim naa wa si oju awọn eniyan ti wọn ti le ri; o seese ki wọn jẹri lori ifirinlẹ ohun ti o se, ki ifirinlẹ ẹri le maa bẹ fun yin lori rẹ.
قَالُوٓاْ ءَأَنتَ فَعَلۡتَ هَٰذَا بَِٔالِهَتِنَا يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُ 62
Wọn si mu Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun wa, wọn si bi leere: se iwọ ni o se isẹ aburu pẹlu awọn oosa wa irẹ Ibrahim?!
قَالَ بَلۡ فَعَلَهُۥ كَبِيرُهُمۡ هَٰذَا فَسَۡٔلُوهُمۡ إِن كَانُواْ يَنطِقُونَ 63
Ibrahim sọpe: - ti o nfẹ kọ wọn lọgbọ, ti o si nse afihan ikagara awọn oosa wọn ni oju awọn eniyan -: emi ko se eleyi bikosepe agba awọn oosa ni o se e, ẹ beere lọwọ awọn oosa yin ti wọn ba le sọrọ.
فَرَجَعُوٓاْ إِلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ فَقَالُوٓاْ إِنَّكُمۡ أَنتُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ 64
Wọn si sẹri pada si ara wọn niti ironu ati awoye, o wa han si wọn wipe dajudaju awọn oosa wọn ko le se anfaani bẹẹni ko le mu inira wa, wọn jẹ alabosi nipa sinsin in yatọ si Allah.
ثُمَّ نُكِسُواْ عَلَىٰ رُءُوسِهِمۡ لَقَدۡ عَلِمۡتَ مَا هَٰٓؤُلَآءِ يَنطِقُونَ 65
Lẹyin naa wọn sẹri si ibi orikunkun ati iya jija, wọn si sọpe: paapa iwọ naa mọ amọdaju - irẹ Ibrahim - wipe awọn oosa yii ko le sọrọ, kilode ti o fi wa npaya lasẹ ki a bi wọn leere? Wọn gbero ki eleyi jẹ awijare fun awọn sugbọn awijare ni o jẹ le wọn lori.
قَالَ أَفَتَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكُمۡ شَيۡٔٗا وَلَا يَضُرُّكُمۡ 66
Ibrahim sọpe: - ni ẹniti o ntako wọn -: se ẹyin yoo maa sin ẹbọ ti o yatọ si Allah ti ko le se yin ni anfaani bẹẹni ko le ko inira ba yin, o jẹ ẹniti o kagara lati mu inira kuro fun ara rẹ tabi mu anfaani wa fun.
أُفّٖ لَّكُمۡ وَلِمَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ 67
O se fun yin o, o si se fun ohun ti ẹ nsin yatọ si Allah, gẹgẹ bi awọn oosa ti ko le se anfaani, ti ko si le mu inira wa, se ẹyin ko se laakaye eleyi ni, ki ẹ si gbe ima jọsin fun un ju silẹ?!
قَالُواْ حَرِّقُوهُ وَٱنصُرُوٓاْ ءَالِهَتَكُمۡ إِن كُنتُمۡ فَٰعِلِينَ 68
Nigbati wọn kagara lati mu ẹri wa nibi dida oju kọ ọ, wọn sẹri si agbara, wọn si sọpe: ẹ fi ina jo Ibrahim; ki o le jẹ aranse fun awọn oosa yin eyiti o da wo, ti o si run un ti ẹ ba jẹ ẹniti o fẹ fi iya inira jẹ.
قُلۡنَا يَٰنَارُ كُونِي بَرۡدٗا وَسَلَٰمًا عَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ 69
Wọn ko ina, wọn si jo o sibẹ awa sọ wipe: irẹ ina jẹ tutu ati alaafia fun Ibrahim, o si di eleyi, sutan kankan ko si kan an.
وَأَرَادُواْ بِهِۦ كَيۡدٗا فَجَعَلۡنَٰهُمُ ٱلۡأَخۡسَرِينَ 70
Awọn ijọ Ibrahim ti ọla nbẹ fun gbero eto si lati jo o nina, a si sọ ete wọn di ibajẹ, bẹẹni a sọ wọn di ẹni iparun ẹniti a bori.
وَنَجَّيۡنَٰهُ وَلُوطًا إِلَى ٱلۡأَرۡضِ ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَا لِلۡعَٰلَمِينَ 71
A la a, a si la Luthu, a si mu awọn mejeeji jade lọsi ilẹ Shamu eyiti a fi ibukun si; nitori awọn Anọbi ti a gbe dide nibẹ, ati awọn oore ti o pọ ti a fan fun awọn ẹda nibẹ.
وَوَهَبۡنَا لَهُۥٓ إِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ نَافِلَةٗۖ وَكُلّٗا جَعَلۡنَا صَٰلِحِينَ 72
A si ta a lọrẹ Isiaka nigbati o pe Ọlọhun Ọba rẹ wipe ki o fun oun lọmọ, a si bun un lẹbun ya'quub ni alekun ati Ibrahim ati ọmọ rẹ Isiaka ati ya'quub ni a sọ wọn di ẹniire ti ntẹle ti Allah.
Titọ lilo ete lati fi se afihan ododo ati lati ba ibajẹ jẹ.
Sisopọ awọn ẹni ibajẹ mọ awọn awijare ti wọn lero wipe o wa fun awọn, ti o jẹpe o wa le wọn lori ni.
Fifun ọrọ le jẹ ọna kan ninu awọn ọna ti a fi nyi nkan ikorira pada nigbati inira ko ti o tobi ko ba tẹle e.
Sisẹri sibi lilo agbara jẹ awijare lori ikagara nigbati ko ba si ojupọnna ẹri.
Aranse Allah nbẹ fun awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo, bẹẹni lila wọn kurom nibi wahala ni awọn ibi ti wọn ko ti lero nbẹ fun wọn.