وَإِذۡ قُلۡنَا ٱدۡخُلُواْ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةَ فَكُلُواْ مِنۡهَا حَيۡثُ شِئۡتُمۡ رَغَدٗا وَٱدۡخُلُواْ ٱلۡبَابَ سُجَّدٗا وَقُولُواْ حِطَّةٞ نَّغۡفِرۡ لَكُمۡ خَطَٰيَٰكُمۡۚ وَسَنَزِيدُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 58
Ẹ ranti ninu awọn idẹkun Ọlọhun Allah lori yin nigbati A sọ fun yin: ẹ wọ “Baetul-Maq'dis” ki ẹ si jẹ nibẹ awọn nkan ti o ba mọ ni aaye ki aaye ti o wu yin, ni jijẹ ifọkanbalẹ ti o gbaaye, ki ẹ jẹ ẹni ti yoo tẹriba nigbati o ba wole, ti yoo si tẹriba fun Ọlọhun Allah, ki ẹ si maa beere ni ọdọ Ọlọhun Allah ni ẹni ti nsọ bayi wipe: Iwọ Ọlọhun Ọba wa pa awọn ẹsẹ wa rẹ; A o si da yin lohun. A o si se alekun fun awọn ti wọn ba se daada nibi isẹ wọn.
فَبَدَّلَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ قَوۡلًا غَيۡرَ ٱلَّذِي قِيلَ لَهُمۡ فَأَنزَلۡنَا عَلَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ رِجۡزٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ 59
Ko si nkan ti o jade ni ọdọ awọn ti wọn se abosi ju wipe wọn yi isẹ wọn pada, wọn si paarọ gbolohun wọn, wọn si yiju pada, wọn wa bẹrẹ sini sọ wipe: hóró irun kan, ni ẹni ti nse yẹyẹ pẹlu asẹ Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) , ẹsan ti Ọlọhun Allah san awọn alabosi ni sisọ iya kalẹ lati sanmọ le wọn lori pẹlu okunfa kikuro ni ẹnu aala ofin Ọlọhun Allah ati yiyapa asẹ Rẹ.
۞وَإِذِ ٱسۡتَسۡقَىٰ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ فَقُلۡنَا ٱضۡرِب بِّعَصَاكَ ٱلۡحَجَرَۖ فَٱنفَجَرَتۡ مِنۡهُ ٱثۡنَتَا عَشۡرَةَ عَيۡنٗاۖ قَدۡ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٖ مَّشۡرَبَهُمۡۖ كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ مِن رِّزۡقِ ٱللَّهِ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ 60
Ẹ ranti ninu idẹkun Ọlọhun Ọba leyin lori, nigbati ẹ wa ninu idaamu-daabo, ti ongbẹ ti o le koko si mu yin, ti Anọbi Musa (ki ọla Ọlọhun maa ba) si rawọ-rasẹ si Ọlọhun Allah rẹ pe ki O fun yin ni omi mu, A si pa lasẹ pe ki o fi ọpa rẹ na okuta, nigbati o fi naa, omi si sẹyọ ni ọna mejila, ni onka awọn idile yin, omi sun ninu rẹ, A si salaye fun idile kọọkan aaye imumi tirẹ lọtọ, ti ija ko fi nii sẹlẹ laarin wọn, ẹ maa jẹ, ki ẹ si maa mu ninu arisiki Ọlọhun Allah eyiti O dari rẹ wa bayin laise wahala kankan tabi isẹ, ẹ má rin irin-ibajẹ ni orilẹ.
وَإِذۡ قُلۡتُمۡ يَٰمُوسَىٰ لَن نَّصۡبِرَ عَلَىٰ طَعَامٖ وَٰحِدٖ فَٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُخۡرِجۡ لَنَا مِمَّا تُنۢبِتُ ٱلۡأَرۡضُ مِنۢ بَقۡلِهَا وَقِثَّآئِهَا وَفُومِهَا وَعَدَسِهَا وَبَصَلِهَاۖ قَالَ أَتَسۡتَبۡدِلُونَ ٱلَّذِي هُوَ أَدۡنَىٰ بِٱلَّذِي هُوَ خَيۡرٌۚ ٱهۡبِطُواْ مِصۡرٗا فَإِنَّ لَكُم مَّا سَأَلۡتُمۡۗ وَضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلذِّلَّةُ وَٱلۡمَسۡكَنَةُ وَبَآءُو بِغَضَبٖ مِّنَ ٱللَّهِۗ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانُواْ يَكۡفُرُونَ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَيَقۡتُلُونَ ٱلنَّبِيِّۧنَ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۗ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَواْ وَّكَانُواْ يَعۡتَدُونَ 61
Ẹ ranti nigbati ẹ se aimoore si idẹkun Ọlọhun Ọba yin, ti ẹ si ko susu nibi jijẹ ‘mọnnu’ ati ‘salwa’ ti Ọlọhun sọkalẹ fun yin, ẹ wa sọ wipe: A ko le se suuru lori ounjẹ kan soso ti ko yi pada, ẹ wa beere lọdọ Musa (ki ọla Ọlọhun maa ba) pe ki o bẹ Ọlọhun Ọba pe ki O mu jade fun yin irugbin inu ilẹ, bii; isu ilẹ, awọn ewebẹ ilẹ, elegede ilẹ - (o jọ eso ‘kiyaaru’ sugbọn o tobi ju lọ) , awọn sese ati alubọsa gẹgẹ bi ounjẹ, Musa (ki ọla Ọlọhun maa ba) wa sọpe- ni ẹni ti nkorira ibeere yin: se e feefi oun ti o kere, ti o si lọọlẹ ju si ‘mọnnu’ ati ‘salwa’ lo ni?, ti o si jẹ wipe oun ni o loore, ti o si ni apọnle, paapa julọ o nwa ba yin laisi inira ati idaamu, ẹ kuro ni ori ilẹ yii lo si eyikeyi abule, ẹ o ri ohun ti ẹ nbeere fun ninu oko ati ọja rẹ, latara titẹle ifẹ inu wọn ati igunri wọn eyiti o tẹle ara wọn nipa oun ti Ọlọhun Ọba sa lẹsa fun wọn, iyẹpẹrẹ, osi ati ilekoko ba wọn, wọn si sẹri pẹlu ibinu lati ọdọ Ọlọhun Allah nitori igunri wọn kuro nibi ẹsin Rẹ ati sise aimoore si awọn amin Rẹ, ati pipa awọn Anọbi ni ti abosi ati ọta sise; gbogbo e gbogbo e pelu okunfa pe won sẹ Ọlọhun Allah won si kọja ẹnu aala Rẹ.
Gbogbo ẹni ti o ba nfi awọn ọrọ ofin Ọlọhun Ọba se yẹyẹ, ti o si nyi pada, iru ẹni yii jọ awọn Yahudi, ẹni bẹẹ si jẹ ẹni iya Ọlọhun Allah.
Titobi ọla Ọlọhun ti nbẹ fun awọn ọmọ Isirẹli, ati wipe ni idakeji eleyi ni ilekoko iyan jija wọn, titako wọn, gigunri wọn kuro ni ọdọ Ọlọhun Allah ati ofin Rẹ.
Dajudaju ninu aburu ẹsẹ ati kikọja ẹnu aala Ọlọhun Allah (ti ọla Rẹ ga) ni iyẹpẹrẹ ati idagunlasi ti o sọkalẹ lori ọmọniyan pẹlu ibori ọta le wọn lori.