أَوۡ تَقُولَ لَوۡ أَنَّ ٱللَّهَ هَدَىٰنِي لَكُنتُ مِنَ ٱلۡمُتَّقِينَ 57
Tabi ẹ nfi kadara se ẹri ni, ni o wa nsọpe: ti Allah ba fi mi se kongẹ ni, emi ko ba wa ninu awọn olupaya Rẹ; emi ko ba se awọn asẹ Rẹ, nko ba si jinna si awọn nkan ti o kọ.
أَوۡ تَقُولَ حِينَ تَرَى ٱلۡعَذَابَ لَوۡ أَنَّ لِي كَرَّةٗ فَأَكُونَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 58
Tabi iwọ yoo sọ nigbati o ba fi oju ri iya ni ẹniti o nrankan, ti pipada si ile aye ba seese fun mi, nko ba sẹri si ọdọ Allah, bẹẹni nko ba wa ninu awọn oluse daadaa ninu awọn isẹ wọn.
بَلَىٰ قَدۡ جَآءَتۡكَ ءَايَٰتِي فَكَذَّبۡتَ بِهَا وَٱسۡتَكۡبَرۡتَ وَكُنتَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ 59
Ọrọ ko ri bi o se nlero nipa rirankan imọna, paapaa awọn amin ti wa ba ọ, o pe e nirọ, o si se igberaga, o wa ninu awọn keferi si Allah ati si awọn amin Rẹ ati awọn ojisẹ Rẹ.
وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ تَرَى ٱلَّذِينَ كَذَبُواْ عَلَى ٱللَّهِ وُجُوهُهُم مُّسۡوَدَّةٌۚ أَلَيۡسَ فِي جَهَنَّمَ مَثۡوٗى لِّلۡمُتَكَبِّرِينَ 60
Ti o ba di ọjọ igbende, iwọ yoo ri awọn ti o parọ mọ Allah nipa sise afiti akẹgbẹ ati ọmọ si ọdọ Rẹ, ti oju wọn yoo dudu; ni amin lori ori buruku wọn, se kii wa sepe aaye nbẹ fun awọn olusegberaga si igbagbọ ninu Allah ati ojisẹ Rẹ ninu ina jahannamọ ni?! Rara, dajudaju aaye nbẹ fun wọn nibẹ.
وَيُنَجِّي ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ بِمَفَازَتِهِمۡ لَا يَمَسُّهُمُ ٱلسُّوٓءُ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ 61
Allah yoo si la awọn ti wọn paya Ọlọhun Ọba wọn pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ kuro nibi iya naa pẹlu ki O ki wọn bọ aaye erenjẹ wọn ohun si ni ọgba idẹra, iya ko nii kan wọn nibẹ, wọn ko si ni banujẹ lori ohun ti o bọ mọ wọn lọwọ ninu awọn ipin aye.
ٱللَّهُ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٖۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٞ 62
Allah ni asẹda gbogbo nkan ko si asẹda miran yatọ si I, O si jẹ alaabo lori gbogbo nkan, O ma ndari alamọri Rẹ, O si ma nyi si bi o se wu U.
لَّهُۥ مَقَالِيدُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 63
Oun nikan ni O ni awọn kọkọrọ pẹpẹ ọrọ gbogbo oore ni gbogbo sanmọ ati ilẹ, O ma nfi ta ẹniti o ba wu U lọrẹ, O si ma nkọ fun ẹniti o ba wu U, awọn ti o si se keferi si awọn aayah Allah ni awọn ẹniti yoo sofo; nitori sise igbagbọ leewọ fun wọn ninu isẹmin aye wọn ati wiwọ ina wọn gbere ni ọrun.
قُلۡ أَفَغَيۡرَ ٱللَّهِ تَأۡمُرُوٓنِّيٓ أَعۡبُدُ أَيُّهَا ٱلۡجَٰهِلُونَ 64
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ ti wọn nse ọ loju kokoro wipe ki o sin awọn oosa wọn: se ẹ o maa pa mi lasẹ - ẹyin alimọkan si Ọlọhun yin - ki nsin ohun ti o yatọ si Allah ni?! ẹnikan ko tọ si ijọsin yatọ si Allah nikan soso, nko si nii sin ohun ti o yatọ si I.
وَلَقَدۡ أُوحِيَ إِلَيۡكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكَ لَئِنۡ أَشۡرَكۡتَ لَيَحۡبَطَنَّ عَمَلُكَ وَلَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ 65
Paapaa Allah ti ransẹ si ọ - irẹ ojisẹ - , O si ransẹ si awọn ojisẹ siwaju rẹ: ti o ba sin nkan miran mọ Allah, ẹsan isẹ rere rẹ paapaa yoo bajẹ, paapaa iwọ yoo wa si wa ninu awọn ẹni ofo ni ile aye pẹlu ki o sofo ẹsin rẹ ati iya ni ọrun.
بَلِ ٱللَّهَ فَٱعۡبُدۡ وَكُن مِّنَ ٱلشَّٰكِرِينَ 66
Bikosepe ki o sin Allah nikan soso, mase mu ẹnikẹni pẹlu Rẹ, ki o si wa ninu awọn oludupẹ fun Un lori awọn idẹkun Rẹ eyiti O se le ọ lori.
وَمَا قَدَرُواْ ٱللَّهَ حَقَّ قَدۡرِهِۦ وَٱلۡأَرۡضُ جَمِيعٗا قَبۡضَتُهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَٱلسَّمَٰوَٰتُ مَطۡوِيَّٰتُۢ بِيَمِينِهِۦۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ 67
Awọn ẹlẹbọ ko pataki Allah ni paapaa pipataki Rẹ nitoripe wọn mu ẹlomiran pẹlu Rẹ ninu awọn ẹda Rẹ ti o lẹ, ti o kagara, wọn si fọnu nipa agbara Allah eyiti o han ninu rẹ wipe ilẹ ati ohun ti o nbẹ nibẹ ninu awọn oke ati awọn igi ati awọn isẹlẹru ati awọn odo wa ni ọwọ Rẹ ni ọjọ igbende ati wipe dajudaju gbogbo sanmọ mejeeji patapata yoo ka jọ ni ọwọ ọtun Rẹ, O mọ, O si mọ kanga, bẹẹni O ga ju ohun ti awọn ẹlẹbọ nsọ, ti wọn si ndi adisọkan rẹ.
Igberaga jẹ iya iyẹpẹrẹ, eebu ti o ma nkọ fun ni lati ma de ibi ododo.
Didudu oju ni ọjọ igbende jẹ amin awọn olori buruku.
Ẹbọ ma nba gbogbo isẹ rere jẹ.
Ririnlẹ gbigbamu ati ọtun fun Allah ti mimọ nbẹ fun laisi apejuwe tabi afijọ.