۞فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوۡمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُوٓاْ أَخۡرِجُوٓاْ ءَالَ لُوطٖ مِّن قَرۡيَتِكُمۡۖ إِنَّهُمۡ أُنَاسٞ يَتَطَهَّرُونَ 56
ko si esi kankan fun awọn ijọ rẹ ju gbolohun wọn lọ: ẹ mu awọn ara ile luth jade kuro ni abule yin, wọn jẹ eniyan kan ti o ma nmọra kuro nibi awọn eeri ati awọn ẹgbin, wọn nsọ eleyi niti mimu awọn ara ile luth sere, awọn ti ko kun wọn lọwọ nibi awọn ibajẹ ti wọn nse, bikosepe wọn ntako wọn lori si se e.
فَأَنجَيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ إِلَّا ٱمۡرَأَتَهُۥ قَدَّرۡنَٰهَا مِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ 57
A si la a, bẹẹni a la awọn ara ile rẹ ayaafi iyawo rẹ, a se idajọ ki o wa ninu awọn ti o sẹku si inu iya, ki o le wa ninu awọn ẹni iparun.
وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهِم مَّطَرٗاۖ فَسَآءَ مَطَرُ ٱلۡمُنذَرِينَ 58
A rọ ojo okuta le wọn lori lati sanmọ, o jẹ ojo buruku, ipanirun fun ẹniti wọn fi iya dẹruba ti ko si jẹpe.
قُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ وَسَلَٰمٌ عَلَىٰ عِبَادِهِ ٱلَّذِينَ ٱصۡطَفَىٰٓۗ ءَآللَّهُ خَيۡرٌ أَمَّا يُشۡرِكُونَ 59
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: Ọpẹ ni fun Allah lori awọn idẹkun Rẹ ati ifọkanbalẹ lati ọdọ Rẹ kuro nibi iya Rẹ eyiti o fi jẹ ijọ Luth ati Sọlihu fun awọn ọmọlẹyin anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, se Allah ni ẹni ijọsin fun tootọ, ẹniti ikapani gbogbo nkan rere nbẹ ni ọwọ rẹ tabi ohun ti awọn ẹlẹbọ nsin ninu ijọsin ti ko nikapa anfaani tabi inira?!
أَمَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَنۢبَتۡنَا بِهِۦ حَدَآئِقَ ذَاتَ بَهۡجَةٖ مَّا كَانَ لَكُمۡ أَن تُنۢبِتُواْ شَجَرَهَآۗ أَءِلَٰهٞ مَّعَ ٱللَّهِۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٞ يَعۡدِلُونَ 60
Tabi taani o da sanmọ ati ilẹ lori aisi apejuwe siwaju, ti O nsọ ọ kalẹ fun yin - ẹyin eniyan - omin ojo lati sanmọ, ti a si nmu jade lati ibẹ awọn ọgba ti o dara, ti o si rẹwa, ẹ ko le mu igi hu ninu awọn ọgba nitori ikagara yin si eleyi, Allah ni O nmu hu jade, se ẹniti ẹ njọsin fun ni o se eleyi pẹlu Allah ni?! Kii se bẹẹ, bikosepe wọn jẹ ijọ ti o yẹ kuro nibi ododo, ti wọn si nse dọgba laarin adẹda ati ẹniti a da niti abosi.
أَمَّن جَعَلَ ٱلۡأَرۡضَ قَرَارٗا وَجَعَلَ خِلَٰلَهَآ أَنۡهَٰرٗا وَجَعَلَ لَهَا رَوَٰسِيَ وَجَعَلَ بَيۡنَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ حَاجِزًاۗ أَءِلَٰهٞ مَّعَ ٱللَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 61
Tabi ẹniti o sọ ilẹ di ohun ti o rinlẹ, ti o si duro dọgba, ti ko min mọ awọn ti wọn nbẹ lori rẹ, ti O si se awọn odo ti nsan si inu rẹ, O si se awọn oke ti o rinlẹ si i, O si tun se laarin odo meji: eyiti o tẹ lẹnu ati eyiti o dun gaga eyiti ti o nkọ didapọ eyiti o tẹ pẹlu eyiti o dun ki o ma baa baa jẹ, ti ko fi ni wulo fun mimu, se ẹniti ẹ njọsin fun ni o se eleyi pẹlu Allah ni?! Rara, bikosepe ọpọ wọn ko nimọ, ti wọn ba mọ ni, wọn ki ba ti mu ẹnikankan mọ Allah ninu awọn ẹda Rẹ.
أَمَّن يُجِيبُ ٱلۡمُضۡطَرَّ إِذَا دَعَاهُ وَيَكۡشِفُ ٱلسُّوٓءَ وَيَجۡعَلُكُمۡ خُلَفَآءَ ٱلۡأَرۡضِۗ أَءِلَٰهٞ مَّعَ ٱللَّهِۚ قَلِيلٗا مَّا تَذَكَّرُونَ 62
Ẹniti o njẹ ipe ẹni alamọri rẹ fun mọ, ti o si le koko nigbati o ba pe E, ti o si ngbe aarẹ ti o sẹlẹ si ọmọniyan kuro ati osi ati ohun ti o yatọ si mejeeji, ti O si se yin ni arole ni oriilẹ, ti apakan yin nrole apakan ni igbe degbe, se ẹni a njọsin fun ni o se eleyi pẹlu Allah bi?! Rara, o kere ni igbati ẹ ngba isiti, ti ẹ si ngba iwoye.
أَمَّن يَهۡدِيكُمۡ فِي ظُلُمَٰتِ ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِ وَمَن يُرۡسِلُ ٱلرِّيَٰحَ بُشۡرَۢا بَيۡنَ يَدَيۡ رَحۡمَتِهِۦٓۗ أَءِلَٰهٞ مَّعَ ٱللَّهِۚ تَعَٰلَى ٱللَّهُ عَمَّا يُشۡرِكُونَ 63
Tabi ẹniti O ntọ yin sọna ninu okunkun oriilẹ ati okunkun omin ninu awọn imọ ti o tẹ fun yin ati awọn irawọ, tabi ẹniti O nfẹ atẹgun niti iro idunnu nigba isunmọ sisọkalẹ ojo eyiti Allah fi nkẹ awọn ẹru Rẹ, se ẹni a njọsin fun ni o se eleyi pẹlu Allah ni?! Allah mọ kanga, O si mọ nibi ẹbọ ti wọn nse pẹlu Rẹ ninu awọn ẹda Rẹ.
Lilugọ awọn ẹni ibajẹ sibi lile koko nigbati awọn awijare ododo ba fun lẹ mọ wọn.
Sisopọ lọkọlaya laisi igbagbọ ko le se anfaani lọrun.
Ririnlẹ adisọkan mimọ Ọlọhun Ọba lọkan lati ara riranti idẹkun Allah.
Gbogbo ẹniti o ni inira ninu olugbagbọ tabi keferi paapaa Allah ti se adehun jijẹ pe rẹ nigbati o ba pe E.