وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا مُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا 56
A ko ran ọ nisẹ - ire ojise - ayaafi ki o le jẹ olufunni ni iro idunnu fun ẹniti o ba tẹle ti Allah pẹlu igbagbọ ati isẹẹre ati olukilọ fun ẹniti o ba sẹ Ẹ pẹlu sise keferi ati ẹsẹ.
قُلۡ مَآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍ إِلَّا مَن شَآءَ أَن يَتَّخِذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلٗا 57
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: wọn ko nii biyin leere ẹsan kankan lori mimu isẹ de ogongo ayaafi ẹniti o ba fẹ ninu yin lati mu oju ọna lọsi ibi iyọnu Allah pẹlu inawo ki o yaa se bẹẹ.
وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱلۡحَيِّ ٱلَّذِي لَا يَمُوتُ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِهِۦۚ وَكَفَىٰ بِهِۦ بِذُنُوبِ عِبَادِهِۦ خَبِيرًا 58
Ki o gbarale - irẹ ojisẹ - Allah Alaaye ẹniti yoo sẹku ti ko nii ku lailai nibi gbogbo alamọri rẹ, ki o si fọ Ọ mọ ni ẹniti o nyin In le lori mimọ Rẹ, o si to ni olufunni niro nipa awọn ẹsẹ ẹru Rẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu rẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ ٱلرَّحۡمَٰنُ فَسَۡٔلۡ بِهِۦ خَبِيرٗا 59
Ẹniti o da sanmọ, ti o si da ile ati ohun ti nbẹ ninu mejeeji ni ọjọ mẹfa, lẹyin naa O ga, O si gun wa lori alaarasi niti giga ti o tọsi gbigbọngbọn Rẹ, O ni Ajọkẹ aye, ki o beere - irẹ ojisẹ - lọwọ ẹniti o ti ni oye pẹlu Rẹ, Oun ni Allah eyiti O mọ gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un.
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱسۡجُدُواْۤ لِلرَّحۡمَٰنِ قَالُواْ وَمَا ٱلرَّحۡمَٰنُ أَنَسۡجُدُ لِمَا تَأۡمُرُنَا وَزَادَهُمۡ نُفُورٗا۩ 60
Nigbati wọn ba sọ fun awọn keferi: ẹ fori balẹ fun Ọba Ajọkẹ aye, wọn sọ wipe: a ko nii fi ori balẹ fun Ajọkẹ aye, taani Ajọkẹ aye naa? A ko mọ Ọ, a ko si ni fi rinlẹ bẹẹ, se a o fi ori balẹ fun Un, ti awa ko si mọ Ọ?! Pipasẹ Rẹ fun wọn lati fi ori kanlẹ fun Un lekun ijina si igbagbọ wọn si Allah.
تَبَارَكَ ٱلَّذِي جَعَلَ فِي ٱلسَّمَآءِ بُرُوجٗا وَجَعَلَ فِيهَا سِرَٰجٗا وَقَمَرٗا مُّنِيرٗا 61
Titobi ẹniti o fi aaye awọn awọn itanna oke ati awọn irawọ ti o nlọ si sanmọ, O si tun fi oorun ti o ntan imọlaẹ si sanmọ, bẹẹni O tun fi osunpa ti o tun ntan imọlẹ si ori ilẹ sibẹ pẹlu imọlẹ ti iyapa si ti oorun.
وَهُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ خِلۡفَةٗ لِّمَنۡ أَرَادَ أَن يَذَّكَّرَ أَوۡ أَرَادَ شُكُورٗا 62
Ọlọhun Allah ni ẹniti O sọ oru ati ọsan di ohun ti npaaọ ara wọn, ti ikan wa lẹyin, ti o si nrọpo ara wọn fun ẹniti o ba ngbero lati ronu nipa awọn amin Ọlọhun Ọba, ti o si mọna, abi o gberi lati dupẹ fun Allah lori idẹkun Rẹ.
Nigbatgi Allah sọ ninu suura yii awọn keferi ti o gunri nibi inigbagbọ si Allah ati itẹle asẹ Rẹ, o tun sọ iroyin awọn ẹru ti o jẹ ẹniire, ti wọn dojukọ titẹle tiRẹ, O si sọpe:
وَعِبَادُ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلَّذِينَ يَمۡشُونَ عَلَى ٱلۡأَرۡضِ هَوۡنٗا وَإِذَا خَاطَبَهُمُ ٱلۡجَٰهِلُونَ قَالُواْ سَلَٰمٗا 63
Awọn ẹrusin Ọba Ajọkẹ Aye ni awọn olugbagbọ ododo eyiti wọn nrin lori ilẹ pẹlu ọwọ ati ni itẹriba nigbati awọn alaimọkan ba ba wọn sọrọ, wọn ko nii fi iru rẹ pade wọn, bikosepe wọn yoo sọ daadaa fun wọn, ti wọn ko nii wu iwa aimọkan le wọn lori nibẹ.
وَٱلَّذِينَ يَبِيتُونَ لِرَبِّهِمۡ سُجَّدٗا وَقِيَٰمٗا 64
Awọn si tun sun lori iforikanlẹ, bakanna awọn ti o nfi gigisẹ wọn duro ni ẹniti o nkirun fun Allah.
وَٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا ٱصۡرِفۡ عَنَّا عَذَابَ جَهَنَّمَۖ إِنَّ عَذَابَهَا كَانَ غَرَامًا 65
Ati awọn ti o nsọ nibi adua wọn fun Ọlọhun wọn: Ọlọhun wa, mu iya jahanamọ jinna si wa, dajudaju iya jahanmọ jẹ ohun ti yoo maa bẹ gbere, ti yoo si lẹ mọ ẹniti o ba ku si keferi.
إِنَّهَا سَآءَتۡ مُسۡتَقَرّٗا وَمُقَامٗا 66
Dajudaju o jẹ aaye ibudesi aburu fun ẹniti o ba de si ibẹ, o si tun buru ni ibuduro si fun ẹniti o ba duro nibẹ.
وَٱلَّذِينَ إِذَآ أَنفَقُواْ لَمۡ يُسۡرِفُواْ وَلَمۡ يَقۡتُرُواْ وَكَانَ بَيۡنَ ذَٰلِكَ قَوَامٗا 67
Ati awọn ti o jasi wipe ti wọn ba nna dukia wọn, wọn kii mu de ogongo ina apa nibi inawo wọn, wọn kii si fun lẹ mọ ẹniti o ba jẹ ọranyan ki wọn nawo le lori nibi inawo wọn lati ọdọ wọn tabi ẹlomiran, inawo wọn si ma nwa laarin ina apa ati isọwọ kukuru niti deede ati wiwa laarin meji.
Olupepe si ọdọ Allah kii wa ẹsan lọdọ awọn eniyan.
Yiyẹ iroyin igunwa Ọlọhun Ọba ni ibamun bi o se tọ si gbigbọngbọn Rẹ.
Dajudaju Ajọkẹ Aye jẹ oruka ninu awọn orukọ Allah, ti ẹnikankan ko ba kẹgbẹ nibẹ rara, o si ntọka si iroyin kan ninu awọn iroyin Rẹ eyiti tii se ikẹ.
Riran ẹru lọwọ pẹlu pipaara oru ati ọsan lati le pa ba ohun ti o ti bọ mọ lọwọ nibi itẹle asẹ nibi ikenin keji rẹ.
Ninu awọn iroyin awọn ẹru Ọba Ajọkẹ Aye ni itẹriba ati amumọra ati itẹle asẹ Allah ni igba ti awọn eniyan ba fọnu ati ipaya ninu Allah ati wiwa ni aarin meji nibi inawo ati nkan miran ninu awọn alamọri.